You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí ìlú Omu Aran ṣe bẹ̀rẹ̀, tan pẹ̀lú Ìgbómìnà nínú ìtàn Yorùbá
Yoruba ni idalu ni iselu nitori itan to rọ mọ isẹdalẹ ilu kan se ọtọọtọ.
Ti a ba si n sọrọ bi ilu kan se sẹ wa, a ko le sai mẹnuba awọn eeyan to se koko, ti wọn para pọ lati da ilu naa silẹ.
Bẹẹ naa ni ti ilu Omu Aran ri nitori wọn ko le sọ ilu naa, lai ma mẹnuba awọn to tẹ ilu naa do.
Ninu Alaye to ṣe fun BBC News Yoruba, Oloye Adekunle Oyinloye to jẹ Eesa ti ilu Omu Aran ṣalaye pe ilu Ile Ifẹ, lati adugbo kan to n jẹ Iraye ni awọn to tẹ ilu Igbomina ti ṣẹ wa tẹdo siilu Igbomina.
Lati onka ẹgbẹrun ọdun lọna mẹtala (13th century), ti wọn ti da ilu Omu Aran silẹ si ni wọn ti n bọ iya agba Orugbo ni ọdọọdun titi di akoko yii.
Gẹgẹbi Oloye Oyinloye ṣe sọ,awọn to kọkọ de Omu gan ṣi ni agbegbe ni ilu Omu to ṣi n jẹ Iraye titi di oni oloni yii.
O ni Aperan lo kuro nilu ile Ifẹ wa tẹ ilu Omu do, oun ati iya to tọọ si ni wọn kuro.
"Pẹlu iya to tọọ̀ ti a mọ si Omutoto , ọkan lara awọn iyawo ọba laye Oduduwa ni wọn jọ kuro nilu ile Ifẹ.
O fi kun un pe gẹgẹbi jagunjagun, Aperan mu ọpa kan ti wọn n pe ni Ogbod ani kuro nilu Ile Ifẹ pẹlu, ti wọn si n b ọpa naa titi di oni yii.