You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ajínigbé tú ọmọ ọba tí wọ́n jí gbé ní Kwara sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦20m
Àwọn ajínigbé ti yọ̀nda Ọláolú ọmọ kabiyesi tí wọ́n jí gbé ni Kwara.
Awọn ajinigbe ti yọnda ọmọkunrin kabiyesi Ọba Simeon Ọlanipẹkun Aniwọ ti ilu Ààfin Ilérè ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara, ti wọn ji gbe.
Ọkan lara awọn mọlẹbi Ọba Ọlanipẹkun lo fidi iroyin naa fun BBC Yoruba amọ ko fẹ ki a darukọ oun.
Lasiko to n fìdi ìṣẹlẹ yii mulẹ, oníwàásù ijọ ti kabiyesi n lọ, Samueli Ajayi ni lootọ ni wọn ti yọnda Ọlaolu ọmọ kabiyesi.
O fikun pe ogun millionu naira ni awọn ajinigbe naa gba ki wọn to yọnda Ọlaolu.
O ṣalaye pe, aadọta millionu naira ni wọn bere fun ṣugbọn ogun million naira lawọn ri ko jọ.
Ajayi sọ pe awọn ajinigbe naa ni kawọn gbe owo ọhun wa si agbegbe Oreke ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara.
O ni nigba t'awọn gbe owo de bẹẹ ni wọn ba yii ọrọ pada pe, ọmọ kabiyesi nikan lawọn yoo yọnda awọn oni yọnda Ọba Ọlanipẹkun.
Pẹlu alaye pe wọn ni kawọn lọ wa millionu mẹrindinlogun naira wa kawọn to le yọnda kabiyesi.
Pasitọ naa ṣalaye pe ọrọ naa ti wa toju su awọn bayii nitori ko rọrun kawọn to ko ogun millionu naira ti wọn gbe lọ jọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, alaafia ni kabiesi wa nigba ti wọn sọrọ lori aago.
Lẹyin naa lo rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati dide iranlọwọ lori bi kabiyesi yoo se pada wale lalaafia.
Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn ajinigbe ji ọba ilu Ààfin Ilérè to wa lagbegbe Babanla, ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin Ọlaolu, to jẹ agunbanirọ gbe lọjọ kejì ọdun keresimesi.
Ọgọrun miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ bere fun itusilẹ kabiesi ati ọmọ rẹ ki wọn to dinkun si aadọta miliọnu naira pẹlu alupupu mẹta.