You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lẹ́yìn tó jáde ní àhámọ́, Portable kéde orúkọ tuntun
Orukọ to ba wu ni la n jẹ lẹyin odi, bo si jẹ ninu ilu ẹni naa ni eeyan ti fẹ pa orukọ da, ko si ọlọpaa to n mu eeyan siyẹn.
Ohun ti Portable, Were olorin ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Habeeb Okikiola Badmus, ṣe bayii niyẹn.
Olorin taka-sufee naa lo kede pe kawọn eeyan maa pe oun lorukọ tuntun, lẹyin to ti ahamọ ijọba de lanaa ọjọ Aje.
'Innocenti', iyẹn alaiṣẹ, ni Portable ni kawọn eeyan maa pe oun bayii, gẹrẹ to ti kootu ti wọn tun ti gbọ ẹjọ rẹ lọjọ Aje de.
Ninu fidio kan loju ẹka Instagram, nibi ti awọn eeyan kan ti rọgba yi Portable ka ni wọn ti n sọ pe wọn parọ mọ ọ ni.
Awọn eeyan naa n pe e ni Innocenti, wọn si n ki I kaabọ.
'Ẹ pe mi lorukọ yẹn'
Bi won ṣe n ki Portable to maa n pe ara rẹ ni Were olorin kaabọ ninu fidio naa ni oun naa n sọ fun wọn pe ki wọn pe oun lorukọ yẹn.
"Ẹ pe mi lorukọ tuntun yẹn, a maa kọrin yẹn naa."
Bẹẹ ni Portable wi ti awọn ti wọn jọ wa nibẹ si n pariwo Innocenti.
Gẹgẹ bo ṣe wi, Portable ni oun yoo sọ orukọ naa di orin ti aye yoo gbọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọpọ igba ti Idaamu adugbo bo ṣe tun maa n pe ara rẹ, ba de lati atimọle tabi kootu lo maa n sọ ọ di orin.
Igba ti wọn gbe e lọ si ọgba ẹwọn Ilaro, to ku diẹ ki wọn ju u sẹwọn ṣugbọn to ri eto beeli rẹ ṣe lo sọ ọ di orin nigba to de.
Portable kọrin nigba naa pe :
"Dem carry me go prison, mi o gbaṣọ, ẹ jawọ lọrọ mi, I'm not a criminal.''
Ninu orin naa lo ti ni oun de ọgba ẹwọn loootọ bi aṣẹ kootu, amọ oun ko wọṣọ ẹwọn, oun ki i ṣe ọdaran.
Ana ode yii ti I ṣe ọjọ Aje ni kootu tun fi aaye beeli silẹ fun olorin naa, lẹyin ẹsun onikoko mẹsan-an to ni i ṣe pẹlu ifiyajẹni ati ole jija.
Yoo si tun foju ba kootu lọjọ keji, oṣu Keji, ọdun 2026 ti Adajọ O.A Sodunke sun igbẹjọ rẹ si.