Covid-19 Vaccine: Joe Biden náà ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsara

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ orilẹede Amẹrika tunuti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Joe Biden naa ti gba abẹrẹ ajẹsara fun aarun Covid-19.

Biden fi si oju opo rẹ loru mojumọ ọjọ Aje pe oun ti lọ gba a.

Aarẹ ti wọn yan yii dupẹ gidi lọwọ awọn onimọ Sayẹnsi atawọn aṣewadii to ṣiṣẹ takuntakun lai kaarẹ.

"Gbogbo ẹyin onimọ Sayẹnsi ati ẹyin aṣewadii tẹ ṣe iṣẹ yii, a jẹ yin ni ọpẹ gidi gan o".

Joe Biden tun wa fi ọrọ ranṣẹ si awọn araa Amẹrika pe ki wọn ma foya tori ko si idi kankan lati bẹruu gbigba abẹrẹ ajẹsara naa.

"Ni kete ti abẹrẹ naa ba ti jade, mo rọ yin lati lọ gba a".

Loju opo Twitter rẹ, Biden gboriyin fun igbes tuntun yii to ṣapejuwe gẹgẹ bii "ipese irọrun".

Ẹwẹ, Joe Biden ni iṣẹ ṣi ku ni ṣiṣe fawọn lorii ṣiṣeranwọ lati bẹrẹ iṣẹ atilẹyin fun eto ti wọn la kalẹ lorii Covid-19.

"Ọrọ mi si gbogbo awọn to n tiraka lọwọlọwọ bayii ni pe: iranlọwọ ti wa lọna".