You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
US election 2020: Àlàyé rèé lórí bí èèyàn 538 ṣe ń yan ààrẹ lé èèyàn mílíọ̀nù 331 ní Amẹ́ríkà
Awọn igbimọ agbaọjẹ oludibo alaṣẹ ni ilu Amẹrika, Electoral College ti buwọlu ibo to gbe Joe Biden ti ẹgbẹ oṣelu Democratic wọle gẹgẹ bi aarẹ.
Ibuwọlu naa waye lọjọ Aje lẹyin ti idibo aarẹ lorilẹ-ede naa ti waye ni ọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun 2020.
Ninu idibo naa ni ti Biden gbegba oroke pẹlu ibo awọn igbimọ agbaọjẹ oludibo alaṣẹ ni ilu Amẹrika, Electoral college nibi to ti ni ibo 306 ti Trump si ni 232.
O ti tun bori ninu ididbo apapọ araalu to ti ni ibo to le ni ọgọrin miliọnu si ibo adọrin miliọnu o le diẹ ti Trump ni.
- E wo ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
- Wo ìdí márùn-ún tí Biden fi bórí nínú ìdìbò ààrẹ America
- Àwọn àkọ́lé ìròyìn mẹ́ta tó leè tẹ̀lẹ́ ìdìbò Ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika
- Agbára wa kò ká àrùn Covid-19 mọ́ - Ìjọba ilẹ̀ Amẹrika
- Báwo ni Donald Trump ṣè ń rí ọwọ́ mú sí nínú àkójọ èrò àwọn olùdìbò?
Ki lo ṣẹlẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 2020?
Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 2020 lawọn ọmọ igbimọ oludibo alaṣẹ, Electoral College parapọ lati fi ontẹ lu ibo to gbe Joe Biden gẹgẹ bi aarẹ tuntun fun orilẹ-ede Amẹrika.
Igbesẹ yii, bi o tilẹ jẹ wi pe amọ ni, ṣugbọn fifi aake kọri ti aarẹ Donald Trump faake kọri lori gbigbe ijọba silẹ ṣe pataki.
Trump ni pe oun ko lee gba pe Joe Biden lo bori idibo aarẹ orilẹ-ede Amẹrika to waye lọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun 2020.
Gbogbo aadọta ipinlẹ to wa lorilẹ-ede Amẹrika lo ti buwọlu abajade ibo naa.
Wọn gba pe ẹgbẹ oṣelu Democrats to ni ibo miliọnu mọkanlelọgọrin o le ẹgbẹrun lọna ọọdunrun, (81.3m) to duro fun ida mọkanlalaadọta o le diẹ (51.3%) lo wọle.
Ẹgbẹ oṣelu Republican si ni ibo miliọnu mẹrinlelaadọrin ati ẹgbẹrun lọna igba, (74.2m) to din diẹ ni ida mẹtadinlaadọta (46.8%)
Amọṣa lorilẹede Amẹrika, ilana ti wọn fi n yan aarẹ wọn yatọ si bi wọn ṣe n ṣe lọpọ orilẹede jakejado agbaye.
Ki ni aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Joe Biden ati Donald Trump sọ lẹyin rẹ?
Lẹyin ibo naa lọjọ Aje aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Joe Biden abajade ibo awọn igbimọ agbaọjẹ oludibo alaṣẹ ni ilu Amẹrika, Electoral college fihan pe ifẹ araalu lo papa ṣẹ.
O ni eto iṣejọba awarawa lorilẹede Amẹrika la ipenija nla kọja, sibẹ o duro ṣinṣin.
Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu aarẹ Trump pe asiko to ko gba fun Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wi pe Trump ko tii sọ ohunkohun lori rẹ.
Awọn wo ni igbimọ agba ọjẹ oludibo alaṣẹ ti wọn n pe ni Electoral College?
Awọn igbimọ agba ọjẹ oludibo alaṣẹ ti wọn n pe ni Electoral College gan an lo lagbara ati yan aarẹ o.
Koda bi oludije kan ba ni ibo to pọ julọ nipasẹ araalu, bi awọn igbimọ agba ọjẹ oludibo alaṣẹ yii ba dibo fun alatako rẹ, alatako yẹn ni yoo di aarẹ
Ẹ maa jẹ ko ru u yin loju, alaye re e.
- Bi awọn eeyan orilẹ-ede Amẹrika ba lọ dibo, kii ṣe oludije ipo aarẹ ni wọn n dibo fun bi ko ṣe akojọpọ awọn eeyan kan ti a n pe ni igbimọ agba ọjẹ oludibo alaṣẹ ti wọn n pe ni Electoral college.
- Awọn wọnyii ni wọn ni ojuṣe lati dibo yan ẹni ti yoo di ipo aarẹ mu.
- Nnkan bii igba ọdun sẹyin ni aṣa yii ti bẹrẹ nigba tawọn babanla orilẹ-ede naa fẹ da eto iṣejọba tiwantiwa silẹ.
- Sugbọn ti ọkan wọn ko balẹ nitori pe wọn n wo o pe bi wọn ba fi ọrọ naa silẹ fun tikere tikere ilu, wọn lee yan ẹni ti ko kun oju oṣuwọn fun ipo naa;
- Eyi lo mu wọn gbe igbimọ agbaọjẹ oludibo yii kalẹ.
- Wọn pin awọn oludibo yii si ipinlẹ kọọkan gẹgẹ bi awọn eeyan ipinlẹ kọọkan ṣe pọ si.
- Lọwọ yii, ojilelẹẹdẹgbẹta o din meji lapapọ awọn igbimọ agbaọjẹ oludibo alaṣẹ yii,
- Ẹnikẹni to ba si fẹ de ipo aarẹ gbọdọ gba ibo to pọ julọ lati ọdọ wọn.
- Eyi to tumọ si pe, ki eeyan to lee di aarẹ lorilẹ-ede Amẹrika, o kere pin, igba o le aadọrin lara awọn ọmọ igbimọ yii lo gbọdọ dibo fun un.
- Ni ọpọlọpọ awọn ipinlẹ, oludije to ba ti ni ibo araalu to pọ julọ ni ọpọ awọn ipinlẹ ni yoo ko gbogbo ibo awọn ọmọ igbimọ agbaọjẹ oludibo alaṣẹ nibẹ.
- Fun apẹẹrẹ, boya oludije kan ko ida mọkandinlọgọrun un tabi mọkalelaadọta ibo ni ipinlẹ Carlifornia;
- Oludije naa ni yoo ko gbogbo ibo awọn ọmọ igbimọ agbaọjẹ oludibo maraarundinlọgọta to wa nibẹ.
- Eyi lo faa to fi jẹ pe oludije kan lee padanu ibo apapọ araalu jakejado orilẹ-ede naa ṣugbọn ko si di aarẹ bi o ba jẹ pe ida to pọ julọ laarin awọn igbimọ naa ni wọn dibo fun un.
- Eyi lohun to ṣẹlẹ lọdun 2016 to fi jẹ pe pẹlu bi Hillary Clinton ṣe ni ibo araalu to pọ julọ, ọwọ rẹ ko tẹ ipo aarẹ Amẹrika.
- Nitoripe alatako rẹ nigba naa, Donald Trump tawọn to pọ julọ ni igbimọ agba ọjẹ oludibo alaṣẹ, Electoral College dibo fun lo gbegba oroke.
- Awọn ipinlẹ kan wa lorilẹ-ede Amẹrika ti awọn oludije ka si ipinlẹ to n dari ibi ti ibo yoo lọ tọrọ ba ti di tibo aarẹ lorilẹede Amẹrika.
- Awọn ipinlẹ naa ni Pennsylvania, Arizona, Texas, Florida, Georgia ati Winsconsin.
- Awọn ipinlẹ wọnyi si lawọn oludije maa n doju kọ lati lee ri ibo to giriki gba nibẹ.
- Fun awọn ọdun diẹ sẹyin, igbesẹ loriṣiriṣi ti n waye lati mu ayipada ba eto igbimọ agbaọjẹ oludibo alaṣẹ (Electoral System) ṣugbọn awọn to gbe lẹyin ilana naa ni oun gan lo n mu ki eto idibo aarẹ lorilẹede Amẹrika o rinlẹ kaakiri orilẹede naa, ati wi pe awọn to n dibo tabi dije ti mọ eyi ṣaaju.