You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Babatunde Olatunji: E wo ọmọ Yorùbá tó kọ́kọ́ jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
Ilumọọka onilu nilẹ America ati nilẹ Afrika, Babatunde Olatunji ti tako ofin ẹlẹyamẹya ni ọdun mẹta saaju ki Rosa Park to tako ofin ẹlẹyamẹya ninu ọkọ igboro lorilẹ-ede America.
Akọroyin BBC, Aaron Akinyemi ni ọdun mẹta saaju Rosa Park ni Babatunde Olatunji ti bẹrẹ ijijagbara fun ẹtọ awọn ọmọ ilẹ Afrika gẹgẹ bi eniyan bi i alawọfunfun ni ilẹ America.
Ọdun 1950 si ọdun 1960 ni awọn alawọdudu dide lati ja fun ẹtọ wọn gẹgẹ bi i ọmọniyan.
Ọkan lara wọn ni Babatunde Olatunji, eleyii ti Ajafẹtọ ọmọniyan, Opal Tometi to jẹ adari ikọ ''Black Lives Matter'' sọ wi pe wọn jẹ iwuri fun oun ni aye ode oni lati tako ẹlẹyamẹya ati ifiyajẹni nitori awọ ara eniyan.
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
- Èèyàn 239 míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 ní Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan di èrò ọ̀run nítorí pé o fi ẹ̀sùn kan alájọgbélé rẹ̀ pé o n yan ìyàwó ẹnìkan lálè
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News
Babatunde Olatunji fi orin ati ilu ja fun ẹtọ alawọdudu
Ọlatunji wa nibẹ pẹlu awọn gbajugbaja ajafẹtọ to jẹ ilumọọka bii James Baldin, Harry Belafonte ni ọdun mẹtadinlọgọta sẹyin nigba ti Martin Luther King Jr sọ ọrọ akinkanju lasiko ifẹhọnuhan to waye nigba naa lati fopin si idẹyẹsini nitori ẹya lorilẹede America.
Ọdun 1927 ni wọn bi Olatunji to jẹ ọmọ Yoruba nipinlẹ Eko, ko to di wi pe Olatunji gba ami ẹyẹ lati lo kawe ọfẹ ni oke okun ni ''Morehouse College'' ni Atlanta, lorilẹede America ni ọdun 1950.
Olatunji da ilumọọka lẹyin to ṣe awo orin mẹtadinlogun pẹlu awo orin to kọkọ ṣe lọdun 1959, eyi to pe akọle rẹ ni "Drums of Passion".
Wọn gbe oriyin fun Olatunji pe orin rẹ ṣe igbalarugẹ asa ati orin ilẹ Afrika, eleyii to gbe awo orin naa wa si gbagede lagbaye.
Bawo lo ṣe bẹrẹ?
Ọdun 1952 ni Olatunji bẹrẹ ifẹhọnuhan tirẹ ni awọn ọkọ igboro ni Guusu ilẹ Amerika.
Lasiko ti Olatunji wa ni ileese Morehouse, ọpọlọpọ nkan to buru jai lo waye nigba naa ti awọn alawọfunfun ṣe si awọn alawodudu nitori ofin ẹlẹyamẹya.
Bakan naa ni Olatunji to ma n kọrin ilẹ Afrika ni Amerika ni awọn ile ijọsin ati fasiti ni awọn agbẹgbẹ ilu Atlanta, ni ilẹ Amẹrika.
Ni ọdun 1952 ni Olatunji bẹrẹ ifẹhọnuhan tirẹ ni awọn ọkọ igboro ni Guusu agbegbe naa.
Olatunji ati awọn ọrẹ rẹ tilẹ ma n wọ aṣọ alaranbara ilẹ Yoruba lati wọ awọn ọkọ igboro naa.
Bakan naa ni wọn ma n ṣe ifẹhọnuhan tako ofin ''Jim Crow'' ni Guusu ilẹ Amẹrika.
Awọn ẹbi Olatunji sapejuwe rẹ gẹgẹ bi akinkanju eniyan
Iyawo Olatunji, Iyafin Ammiebelle Olatunji to jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọrun ṣe apejuwe ọkọ rẹ gẹgẹ bi ẹni to gbe igbeaye rẹ lati ṣe igbelarugẹ fun ifimọsọkan awọn ọmọ ilẹ Afrika.
Ni ọdun 1964, Olatunji ṣiṣẹ pọ pẹlu aarẹ akọkọ lorilẹede Tanzania, Julius Nyerere ati Malcolm X lati fopin si ofin ẹlẹyamẹya lorilẹede Amerika.
Awọn ọmọ meji ninu awọn mẹrin ti Olatunji bi, Folasade ati Modupe Olatunji ṣe apejuwe baba rẹ gẹgẹ bi akinkanju eniyan to si kọ awọn ọmọ rẹ ni ṣiṣe iṣẹ takuntakun lọna ati jẹ ki wọn jẹ akinkanju eniyan nibi gbogbo ti wọn ba de.
- Àwọn ará ìlú Ikarẹ Akoko ń ṣọ̀fọ̀ Ọba Adegbite, Ọwá Ale Ikarẹ tó wàjà
- Gbajúgbajà òṣèré “Blue film'' wọ gàù ẹ̀sùn fífipá bá obìrin 13 lòpọ̀
- Ẹgbẹ́ wa ò dàrú o! Kódà gbọingbọin la wà lẹ́yìn Akintoye gẹ́gẹ́ bíi adarí YWC nílé, lẹ́yìn odi
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Àṣírí tú! Wo àwọn tó ń jí owó Covid-19 tí Ìjọba ní wọ́n yóò káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́
Ọdun 2003 ni Olatunji sun ti ko ji mọ ni ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin.
Iṣẹ takuntakun to ṣe ni ẹka orin kikọ ti jẹ ki Babatunde Olatunji jẹ awokọṣe fun Afrika ati awọn ọmọ ilẹ Afrika ti wọn bi tabi ti wọn n gbe ni Amerika.
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ padà sí iléèwé
- Iléeṣẹ́ ìròyìn Daily Trust gbọdọ̀ san N6 bilion nítorí ìbanilórúkọjẹ́- Femi Fani Kayode
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC