US presidential election 2020: Ta a ni Joe Biden to di aàrẹ tuntun nilẹ̀ America

Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó kojú Trump nínú ìbò America.Ìgbà kẹta re e ti igbakeji Aarẹ ilẹ America nigba kan, Joe Biden, dije fun ipo aarẹ, labẹ ẹgbẹ oṣelu Democrat.

Bo tilẹ jẹ pe aarẹ America nigba kan, Barack Obama, sọ pe Biden, ni igbakeji aarẹ to dara ju ti America ti i ni, ẹnu n kun akọsilẹ nipa ogoji ọdun to fi jẹ oṣiṣẹ ijọba.

Biden gẹgẹ bi oloṣelu:

Ọgbẹni Biden du ipo aarẹ lọdun 2008, ninu ẹgbẹ oṣelu Democrat, ko to o di pe o dije pẹlu Obama, gẹgẹ bi igbakeji rẹ.

Ọdun mẹjọ to lo nile ijọba ilẹ America, White House, mu ko ṣe e ṣe fun Biden, lati ma a fi lara iṣẹ ti Obama ṣe polongo ibo.

O tun ṣe e ṣe ko jẹ pe ibasepọ rẹ pẹlu Obama, to ma n pe e ni "arakunrin" mi, jẹ ọkan lara awọn nkan to mu ko ṣe itẹwọgba lọdọ àwọn oludibo to jẹ ọmọ Africa, to tun jẹ ọmọ ilẹ America bakan naa.

Ẹnu kun un lọdun 2012, nigba to sọ ni gbangba pe oun faramọ igbeyawo ọkùnrin si ọkunrin, koda ki Aarẹ Obama to o sọrọ nipa atilẹyin rẹ fun iru igbeyawo naa.

Ọdun 1972, lo kọkọ di sẹnetọ, o si ti jẹ ni igba mẹfa.

Biden kọkọ dije fun ipo aarẹ lọdun 1988, àmọ́ o yi ero rẹ padà.

Bo tilẹ jẹ pe Biden ti pẹ ninu isejọba ilẹ America, àwọn nkankan wa to le ta ko o.

Nigba to kọkọ bẹrẹ isẹ, o ṣe atilẹyin fun awọn eeyan ẹkùn Gusu, to tako ki awọn aláwọ̀ dudu ati funfun, jọ ma a wọ ọkọ bọọsi kan naa, tabi jọ lọ sileewe ijọba kan naa.

Lọdun 1994, Ọgbẹni Biden, jẹ ọkan pataki lara awọn to polongo ofin iwa ọdaran.

Ọpọlọpọ sọ pe ofin naa n mu wọn o dajọ ẹ̀wọ̀n ọlọjọ pipẹ fun awọn eeyan, to si tun n mu ki awọn ti wọn n ju si ẹ̀wọ̀n o pọ.

Awọn akọsilẹ yii ko jẹ ki Biden o ba ẹgbẹ oṣelu Democrat ti ode oni mu.

Ibanujẹ ti Biden ni:

Lọdun 1972, laipẹ to kọkọ wọle gẹgẹ bi sẹnetọ, ni iyawo rẹ, Neila ati ọmọ rẹ ikoko l'obinrin, kú ninu ijamba ọkọ.

Ileewosan to ti n tọju àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin to ye ninu ijamba naa, ni wọn ti bura fun un.

Lọdun 2015, aisan jẹjẹrẹ ọpọlọ, pa ọmọ rẹ Beau, lẹni ọdun mẹrindinlaadọta.

Ọmọ naa n mura lati du ipo gomina ipinlẹ Delaware, lọdun 2016.

Iku ọmọ rẹ mu ko jẹ anfaani àwọn nkankan, nitori pe awọn eeyan gbagbọ pe baba daadaa ni.

Sugbọn, oore ẹ̀dẹ ni awọn anfaani yii, nitori pe lẹyin to bẹrẹ idije fun ipo aarẹ lọdun 2020, lo ti bẹrẹ si ni wi awijare.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn obinrin kan to jẹ oludibo ṣe n fi ẹsun kan an pe awọn ko nifẹ si bo ṣe maa n fi ọwọ kan wọn - àwọn kan ti ẹ tun fi àwọn fidio sita nípa rẹ.

Sugbọn esi to fun wọn ni pe eeyan ẹlẹ́ran ara ni oun.