You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
US presidential election 2020: Kíni Kọ́lẹ̀jì ìdìbò, àwọn ìpińlẹ̀ tó le gbé olùdíje wọlé àti àwọn ǹkan ti o yé kí o mọ̀ nípa ìdìbò ilẹ̀ Amerika.
Ọjọ kẹ̀ta, oṣù kọkànlá, ọdún 2020 ni ìdìbò ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika yóò wáyé, sùgbọ́n , ó ṣee ṣe kí ẹni tí ó ni ìbò tó pọ̀jù lọ lásìkò ìdìbò gbogboogbo má wọle gẹ́gẹ́ bi ààrẹ.
Ẹ ní báwó ni yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀ àbí?
Ìdí ni pé, àwọn kọ́lẹ̀jì ìdìbò ni yóò sọ ẹni tó wọlé gẹ́gẹ́ bi ààrẹ, èyí kìí sì ṣe pé àwọn ni àwọn olùdìbò yàn.
Kí wá ni ìdí tí àwọn Amẹrika ṣe ń dìbò?
Bí àwọn Amẹrika bá dìbò ààrẹ, ǹkan tí ó maa n ṣẹlẹ̀ gàn an ni pé wọ́n ti yóò dìbò yhan àwọn ti yóò lọ sojú wọn ní kọ́lẹ̀jì ìdìbò.
Ìtùmọ kọ́lẹ̀jì níbí ni àwọn ènìyàn tó parapọ̀ fún ìdí kan náà, iṣẹ́ wọn ni láti yan ààrẹ àti ìgbákejì ààrẹ
Ọdún mẹ́rìn mẹ́rin ni àwọn kọ́lẹ̀jì ìdìbò yìí máa ń pàdé láti ṣe iṣẹ́ wọn lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ti ará ìlú bá ti dìbò tán.
Kíni iṣẹ́ àwọn kọ́lẹ̀jì oludìbò?
Ènìyàn ti yóò péjú nínú kọ́lẹ̀jì náà ní yóò jẹ́ aṣojú ìpińlẹ̀ tó ti wá.
Gbogbo ìpínlẹ̀ náà sì ni yóò ni iyé asójú bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iyé ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti wọ́n ni ilé Amẹrika (representaives àti Senator)
Califonia ló ni olùdìbò tó pọ̀ jù, tó jẹ́ -55- nígbà ti àwọn ìpínlẹ̀ tó kéré bi Wyoming, Alaska ati North Dakota (àti Washington DC) má a ń ni ènìyàn mẹ́ta-mẹ́tà.
Ní àkótán olùdìbò 538 ló wà ni ilẹ̀ Amẹrika
Olùdìbò kọ̀ọ̀kan ló dúró fún ìbò kan tí olùdíje ààrẹ kọ̀ọ̀kàn sì gbọdọ̀ ní ìbò 270 tàbi jù bẹ́ẹ̀ lọ láti di ààrẹ fún ọdún mẹ́rin.
Ní àpàpọ, kí àwọn ti yóò sójú fún kọlẹ̀jì ìdìbò yìí tó kúrò nílé ni àwọn àrá ìpińlẹ̀ wọ̀n yóò ti kọ́kọ dìbò láti mọ ẹni ti wọ́n fẹ́ dìbò fún.
Bí àpẹrẹ̀ ti olùdíje náà bá ní ìdìbò ìdá àádọ́tà àti ọ̀kan nínú ìdá ọgọ́rùn un ni Texas, wọ́n yóò fún ẹni náà ni gbogbo ìbò 38 tó tọ́ si lati ìpínlẹ̀ Texas
Nítori náà ó ṣeése ki ènìyàn di ààrẹ tó ba jáwe olúbori nínú ìdìbò to díjú ní àwọn ìpińlẹ̀ kan, kódà ti kò bá ni ìdìbò tó pọ̀ tó ti alátakò rẹ̀, ó sì le di ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹrika.
Ìpínlẹ̀ méjì péré (Maine àti Nebraska) ló máà n pín ìbò àwọn kọ́lẹ̀jì ìdìbò, nítori bi iye àwọn olùdìbò tí wọ́n ni.
Nítorí náà ni àwọn olùdíje ṣe máá n dójúkọ àwọn ìpińlẹ̀ tí ó le fi ìdì ẹni ti yóò wọlé múlẹ̀. Àwọn ìpińlẹ̀ yìí ló máa n sọ ẹni ti yóò wọlé ìdìbò
Gbogbo ìpínlẹ̀ tí wọ́n bá sì ti wọlé ni yóò sọ ọ̀nà ti wọ́n yóò gbà láti rí rí ìdìbò 270 tí àwọn kọ́lẹ̀jì ìdìbò nílò