You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Electricity new tariff: ''Àjọ NERC ti fún Disco láṣẹ láti padà sí owó tàríìfù tuntun iná mọ̀nàmọ́ná''
Otitọ ni wi pe ileeṣẹ ina mọnamọna Disco ti pada si owo ina tuntun ti wọn ni ki awọn araalu maa san.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Disco Ikeja ti ko fẹ ki BBC darukọ rẹ lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.
O ṣalaye pe ọjọ kinni oṣu kọkanla ọdun 2020 yii ni ajọ to n ṣakoso awọn ileeṣẹ mọnamọna, NERC ti fawọn laṣẹ lati pada si owo in a tuntun.
- Ajọ WAEC gbé èsì ìdánwò ọdun 2020 jáde
- Kàyééfì tuntun rèé lórí #EndSARS, ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwádìí BBC
- Akinwumi Isola dárà nínú ìwé "Nítorí Owó" lórí Akomolede Yoruba
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ní Oyigbo lẹ́yìn tí ọlọ́páà mẹ́ta àti sọ́jà kú nínú rògbòdìyàn EndSARS
- Ènìyàn méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abúlé Ẹ̀gbá, ní ìpínlẹ̀ Eko
Ṣugbọn ohun to jẹ iyalẹnu ni pe ọpọ awọn onibara lo ti n kọminu pe lati inu oṣu kẹwaa ni ileeṣẹ Disco ti bẹrẹ si fawọn onibara wọn ni ni biili tuntun.
Nigba ti a beere bo ya ijọba apapọ mọ si bi wọn ṣe bẹrẹ si gba tariifu tuntun, oṣiṣẹ Disco naa sọ pe ajọ NERC nikan lo le dahun ibeere yii.
O ni ọpọ araalu ni wọn n dibọn pe awọn ko mọ nitori wọn ko faramọ igbesẹ Disco lori ọrọ tariifu ina tuntun.
''Gbogbo awọn onibara wa lo n sọ kaakiri pe ọfẹ ni ijọba n gbe mita ina mọnmọna fawọn eeyan, ṣugbọn niṣe ni wọn dakẹ lori ọrọ tariifu tuntun,'' oṣiṣẹ Disco lo sọ bẹẹ.
Ẹwẹ, ajọ ajafeto-ọmọniyan kan ni Naijiria, SERAP ati awọn eeyan mejilelọọdunrun mii, ti pe aarẹ Buhari ati ile aṣofin lẹjọ tẹlẹ lori afikun owo epo bentiroo ati owó ina ọba.
SERAP ati awọn ti wọn dijọ pe ẹjọ yii ni awọn fẹ ki ile ẹjọ "f'ọwọ rọ afikun owo epo ati ina ọba sẹyin.
Alaye wọn ni pe awọn eeyan to dipo nla mu ninu ijọba ko le maa gbadun, ki wọn wà ni k'ara ilu maa ṣe ifarada."
Ninu awọn ti wọn pe lẹjọ yii la ti ri igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo, aarẹ ile aṣofin agba Ahmad Lawan, Olori ile aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila ati awọn mii.
- Ta ni Wolii Olapade Agoro tó re ibi àgbà ń rè tí ayé ń pariwo rẹ̀ yìí?
- Ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Adelé Ọba Alade Idanre ló rí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti Ọba Aroloye
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Aàbò tó péye yóò wà fún àwọn tí yóò kópa nínú ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ Naijiria àti Sierra Leone ní Benin - Obaseki
- Wo iye owó tí ìjọba Amẹrika ń na sí ìdìbò Ààrẹ àti ibi tí owó náà ti ń wá