You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Idanre Kingship tussle:Adelé Ọba Idanre ní Ọba Aroloye wà lórí ìtẹ́ nígbà tí àwọn jàndùkú lù ú
Adele Ọba Alade Idanre, Temilolu Akinboola ti ṣalaye fun BBC bi awọn janduku kan ṣe ya bo aafin rẹ ti wọn si lu u ni ilu bara.
Temilolu sọ pe inu ile igbọnsẹ ni oun farapamọ si lọjọ naa ki awọn janduku ọhun to fi tipatikuku wọ oun jade lọ si aafin Owa ilu Idanre, Ọba Frederick Aroloye.
O ni wahala bẹrẹ lẹyin ti wọn fi oun jẹ Adele Ọba tan, ti wọn si ti ọja ilu Alade.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "Mo gburo ọkada ti wọn pọ rẹrẹ, ti wọn n pariwo, ti wọn si n kọ orin bi ẹni to n lọ soju ogun, bẹẹ naa ni wọn n pariwo Adele da, Adele da!?
- Owatapa ti Itapa Ijesha, Wolii Olapade Agoro jáde láyé
- Sanwo Olu àti Okowa dẹwọ́ ìséde ní Eko àti Delta pẹ̀lú àlàyé tuntun
- Aàbò tó péye yóò wà fún àwọn tí yóò kópa nínú ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ Naijiria àti Sierra Leone ní Benin - Obaseki
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
O ni " Wọn gba mi loju, wọn lu mi, wọn si fi aṣọ mi wọ mi sita."
Temilolu sọ pe awọn janduku naa kọlu awọn oloye oun mẹta, bẹẹ ni wọn kan apa ọkan lara wọn.
Adele naa sọ pe Ọba Aroloye wa lori itẹ nigba ti awọn janduku naa n na oun ninu aafin rẹ.
O pari ọrọ rẹ pe eredi gbogbo rogbodiyan naa ko ṣẹyin bi wọn ṣe fi oun jẹ oye Adele, eyii ti Owa ilu Idanre sọ pe o lodi si aṣa ilu naa.
Gbogbo akitiyan lati kan si Ọba Frederick Aroloye lati sọ bi ọrọ naa ṣe jẹ lo ja si pabo.
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan to fi lede, o ni irọ pọnbele ni gbogbo ohun ti Adele sọ, nitori oun ko ran janduku kankan lati fi iya jẹ.
Ṣugbọn Aroloye sọ pe o lodi si iṣẹṣe ilu Idanre ki obinrin jẹ Adele Ọba.
Gbogbo igbiyanju BBC lati ri Owa ba sọrọ jasi pabo titi di asiko yii
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Adelé Ọba Alade Idanre fẹ̀sùn kan Owa ìlú Idanre pé ó bẹ àwọn jàǹdùkú lọ́wẹ̀ láti fi ìjà jẹ òun
Rogbodiyan bẹ silẹ ni ilu Alade Idanre, iyẹn ni ipinlẹ Ondo lori ẹni to yẹ ko gori itẹ Ọba Olusegun Akinbola to di oloogbe lọjọ kẹrindinlogun,oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
Lẹyin ọjọ meji ti Ọba naa waja ni wọn fi akọbi ọmọ rẹ obinrin, Temilolu Akinboola, sori oye gẹgẹ Adele, ṣugbọn o da bii pe igbesẹ yii ko dun mọ awọn kan ninu.
Iroyin ni lẹyin ọjọ karun un ti wọn fi Temilolu jẹ adele ni awọn janduku kọlu afin rẹ ti wọn si luu ni ilu bara toun ti iya rẹ.
Ninu iwe ẹbẹ kan to kọ si kọmisọnna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, adele Ọba ọhun ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn janduku to kọlu afin naa.
O ni awọn tọọgi ọhun "ti iye wọn to ogun ya bo afin oun lori ọkada pẹlu ibọn, ada, kondo atawọn ohun ija oloro miran" lati ṣakọlu si afin naa.
Temilolu fẹsun kan Owa ti ilu Idanre, Frederick Aroloye, pe oun lo ran awọn janduku naa lati ṣakọlu si oun.
- Wumi Toriọla ti sọ̀rọ̀ sóke láti fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun àti ọ̀rẹ́ òun níjà
- Ọlọ́pàááá! Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ kíá bí bẹ́ẹ̀ kọ́... Àmọ́ ẹ ríi pé ẹ dáàbò bo ẹ̀mí yín - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
- Ojúmọ́ kan, ìdàmú kan ni mo fi lo ogún ọdún àkọ́kọ́ lórí oyè - Alaafin
- Tí iye iná tí ẹ rí gbà bá kéré ju owó tí ẹ rà á lọ, ẹ ti jẹ gbèsè tẹ́lẹ̀ ni - Iléeṣẹ́ apínnáká
Bakan naa lo sọ pe awọn janduku ọhun ba gbogbo ọkọ to wa ninu afin naa jẹ, bẹẹ ni wọn tun ko awọn ohun ini oun bii ounjẹ, ọti ẹlẹrindodo, aṣọ olowo iyebiye, ohun ẹṣọ ara, ẹrọ kọmputa alagbeka ati owo lọ.
Adele naa fi kun un pe awọn janduku ọhun fi agidi gbe oun lọ si afin Aroloye nibi ti wọn ti fi ija jẹ oun niwaju rẹ.
Temilolu sọ pe awọn tọọgi naa fi iya jẹ oun atawọn eeyan miran to wa ni afin lọjọ naa ki wọn to gbe oun sori ọkada lọ afin Aroloye.
O ni Owa ti ilu Idanre joko sori itẹ rẹ to si n wo bi awọn janduku naa ṣe n na oun ni ilu bara.
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti Aroloye fi lede, o ni irọ pọnbele ni gbogbo ohun ti Adele ọhun sọ, nitori oun ko ran janduku kankan lati fi iya jẹ.
Ṣugbọn Aroloye sọ pe lodi si iṣẹṣe ilu Idanre ki obinrin jẹ Adele Ọba.