You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS Protest Update: Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá àti ọ̀gá àjọ ọlọ́pàá ń késí àwọn òṣìṣẹ́ wọn
Ọga agba awọn ọlọpaa, Muhammed Adamu ti ni ki awọn ọlọpaa maa daabo bo ara wọn lodi si ikọlu.
O ni awọn oṣiṣẹ wọn ati awọn ọlọpaa ni ẹtọ lati da abo bo ara wọn ni asiko ti wọn ba ri ikọlu lojukoroju.
Lọjọ Ẹti ti ọga agba ọlọpaa n ṣe ibẹwo si awọn ileeṣẹ ọlọpaa to wa kaakiri olu ilu orilẹede yii ni ilu Abuja lo sọ bẹẹ.
O si fi asiko kan naa gba awọn ọlọpaa to ti kuro lẹnu iṣẹ wọn loju popo fun bii ọjọ marun un latari pipa ọlọpaa to le ni ogun lasiko ifẹhonuhan to jade jakejado Naijiria.
Irufẹ ọrọ yii kan naa ni ọga ajọ to n moju to ọrọ ọlọpaa ni Naijiria, Ikechukwu Ani kesi wọn lati pada si ẹnu iṣẹ wọn kiakia tabi ki wọn gba iwe idaduro.
Bo tilẹ jẹ pe ohun to ṣẹlẹ si awọn akẹgbẹ wọn mejilelogun to tẹri si iku ni ọsẹ diẹ sẹyin lo mu wọn kuro loju popo ṣugbọn bayii wọn ti ni eyi kii ṣe awawi lati sa kuro, ki wọn pada bi bẹẹ kọ, iṣẹ a bọ lọwọ ẹni bẹẹ.
- Wo ojú àwọn òṣèré yìí láì lo "Make-up" orí ìtàgé bó ṣe rí gẹ́lẹ́
- Wumi Toriọla ti sọ̀rọ̀ sóke láti fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun àti ọ̀rẹ́ òun níjà
- Mo pinu láti dá Iphone tì mo mú padà kí ọlọ́pàá tó mú mi
- Ẹ gbọ́ Ohun tí Desmond Elliot àti Mojisola Alli-Macaulay sọ lórí ayélujára táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ìbínú
- Ìrànwọ́ ikú fàwọn tó bá wà lórí àkéte àìsan tó leè já sí ikú ti di òfin tuntun tí wọ́n fẹ́ fọwọ́ sí!
Ọga ọlọpaa, Adamu n fi ẹsun sita pe awọn afẹhonuhan EndSARS ti ni i lọkan lati ṣe ibi sawọn ọlọpaa to si fi kun un pe ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria yoo to ṣagbejade eto iranwọ fun idile awọn ọlọpaa to ku lasiko ifẹhonuhan naa.
O fi kun un pe irẹpọ orilẹede yii wa lọ́wọ́ iru atilẹyin ti awọn ọlọpa ba ri latọdọ araalu toripe bi eyi ba n bajẹ, o ma n faaye gba awọn janduku lati bẹrẹ iwa ipa wọn laarin ilu.
Ọga ọlọpaa ni awọn ni ijọba gbẹkẹle ki awọn janduku ma baa gba akoso igboro ilu nitorinaa "ko si bi eeyan ṣe fẹ́ bi wa ninu to tabi sọrọ abuku si wa ti a o ni ṣe iṣẹ wa bo ṣe yẹ.
"Niwọn igba ti a mọ pe ijọba ti wa lẹyin wa, a n gba yin niyanju lati maa ṣe iṣẹ yin lọna to tọ. A rọ yin lati jẹ akọṣẹmọṣẹ ṣugbọn bi ẹnikẹni ba wa fi ilọkulọ lọ yin, ẹ lee da abo bo ara yin".
Ọgbẹni Adamu ni "baa ba nsọ̀rọ̀ ẹtọ ọmọniyan, eniyan ẹlẹran ara ni ọlọpaa naa nitorinaa idaabobo fun ẹtọ awọn ọlọpaa naa yoo wa. tori eyi la ṣe n fi ọrọ yii sita loju gbogbogbo pe a ni lati da abo bo ara wa".
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá kọ àbájáde àjọ Amnesty International lórí ìṣẹ̀lẹ̀ EndSARS ní Lekki
Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Mohammed Adamu ti kọ àbájáde ọ̀rọ̀ tí ajọ Amnesty International sọ pe awọn ọlọpaa yinbọn pa awọn oluwọde EndSARS.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita lọjọ Ẹti, Ọga ọlọpaa, Adamu sọ pe abajade ajọ Amnesty International to hande lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwa dun 2020 to kọ pe awọn ọlọpaa yinbọn ba awọn to n ṣe iwọde wọọrọwọ n ṣi awọn eeyan lọkan ko si ki n ṣe ootọ wipe o lodi si gbogbo aridaju to wa nilẹ.
Ẹwẹ, ọga agba ọlọpaa fọhun pe awọn ọlọpaa ṣiṣẹ gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ ti awọn kan si fi ẹmi wọn lelẹ fun alafia lasiko ifẹhonuhan to waye kaakiri awọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria.
"Awọn esi to wa nita fihan pe ọlọpaa mejilelogun padanu ẹmi wọn ti awọn mii si farapa lasiko ifẹhonuhan naa". Ọga ọlọpaa ni ipo ti awọn to farapa gan wa nile iwosan bayii kọja afẹnusọ.
Lasiko ifẹhonuhan to ṣẹlẹ kaakiri orilẹede Naijiria yii, ọga agba ọlpaa ni agọ ọlọpa igba o le marun atawọn ibudo mii to fi mọ awọn nkan amayerọrun faraalu ni awọn kan lara awọn afhonuhan bajẹ.
Ọga ọlọpaa ni ileeṣẹ awọn ni ifarajin si igbesẹ atunṣe ti ijọba apapọ n ṣe lọwọlọwọ ni Naijiria.
Kí ni Amnesty International sọ?
"Ẹ má gbìyànjú àti bo àṣírí ǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Lekki, a ní ẹ̀rí tó dájú"
Ajọ ajafẹtọ ẹni kan l'agbaye, Amnesty International, ti kilọ fun ijọba orilẹ-ede Naijiria, lati ma bo aṣiri bi awọn kan ṣe yinbọn mọ awọn oluwọde ni Lekki, nipinlẹ Eko.
Oludari ajọ naa, Osai Ojigho sọ pe awọn fi ikilọ naa sita, nitori pe awọn iṣẹlẹ to n waye bayii fihan pe ijọba fẹ ẹ bo aṣiri iṣẹlẹ naa, gẹgẹ bi iṣe rẹ ni gbogbo igba ti ileeṣẹ ologun ba paayan lọna ti ko ba ofin mu ni Naijiria.
Ileeṣẹ ologun ti kọkọ sọ pe oun ko lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, ṣugbọn to tun yi ọrs pada lọjọ Iṣẹgun pe, gomina ipinlẹ Eko lo ranṣẹ pe awọn lati da alaafia pada si aarin ilu.
Amọ 'sa, gomina paapa ti kọkọ sọ pe oun ko fun wọn ni aṣẹ nitori pe oun ko ni agbara lati paṣẹ fun ileeṣẹ ologun.
Ajọ Amnesty sọ pe oun ni ẹri to pọ, lati fihan pe awọn ọmọ ogun lo yinbọn mọ awọn oluwọde naa, eyi to pa awọn kan, ti awọn mii si farapa.
Ati pe, awọn onimọ nipa rogbodiyan ninu ajọ naa ti ṣe iwadii, wọn si ri i daju pe ileeṣẹ ologun lọwọ ninu ipaniyan to waye ni Lekki.
Ilé iṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà tú àṣírí ẹni tó rán wọn níṣẹ́ lọ kojú àwọn olùwọ́de EndSARS ní Lekki Tollgate
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti gbómi-si-omi- ò tó tí wáye lórii pé tani o pàsẹ fún àwọn ọmọgún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti jáde sígborò tí àwọn olùwọ́de fí faragba ọ̀ta ìbọ̀n nibi iwọde EndSARS ti àwọn míràn sì gbà ibẹ̀ kú.
Onírúurú ìròyìn ló ti tàn kálẹ̀ tí gómìnà ìpińlẹ̀ Eko sì ti jáde pé àwọn àgbára kan tó jú òun lọ ló ṣe ìṣẹ́ ibí náà, àti pé, gbogbo ìwádìí tó bá yẹ ni ìjọba yóò ṣe láti ríi dájú pé, ìdájọ́ òdodo jẹyọ fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọ́n tàbí tí wọ́n fara gbọgbẹ́.
Ẹ̀wẹ̀, ilé iṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà nínú àtẹ̀jáde tó fi síta ló ti sàlàyé pé, ọmọogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò dédé jáde sítà, bíkòṣe pé, ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ló bẹ òun lọ́wẹ̀ láti ràn ìlú lọ́wọ́ lẹ́yìn tí àwọn ọ̀daran kan tí n jó àgọ́ ọlọ́pàá tí wọ́n sì ń ba ǹkan jẹ́ ní nìlú Eko.
Nínú àtẹ̀jáde náà tí Major Osoba Olaniyi tó jẹ́ adélé ìgbákeji àdári alukoro 81 Division fọwọ́sí ló ti sàlàyé pé, ilé iṣk ọmọogun ṣe àkíyèsí ìròyìn tó ń jà ràìn-ràìn lórí ayélujára pé, àwọn ọmọ ogún 81 Division ló yìnbọ pa àwọn olùwade ìfẹ̀hónúhan ni ìloro Lekki lógúnjọ, oṣù kẹ̀wàá, ọdún 2020.
Ilé iṣẹ́ ọmọogun ni irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà pé àwọn yìnbọ̀n tàbi pa ẹnikéni ní àsìkò sún, ẹ̀yí nìkàn kọ́, ó fi kun pé, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà nígboro pé àwọn ko pa ẹnikẹ́ni.
Osoba ní lẹ́yìn tí ìjọba pé àwọn, àwọn ọmọgun náà ríi dájú pé, ìlànà tó tọ́ àti èyí tó yẹn láti bá ará ìlú ṣe ni àwọn lò, ìbọ̀n yínyìn tàbí ìpànìyàn kankan kò sì wáye.
Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
Asiwaju ẹgbẹ oselu APC nilẹ wa, tii tun se gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, tun ti sọrọ lori isẹlẹ isekupani to waye ni Lekki fun igba keji.
Lọtẹ yii, ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ ni Tinubu ti bawọn ọdọ kan takurọsọ nipa isẹlẹ naa lọjọru.
Nigba to n salaye bi ifọrọwerọ Tinubu ati awọn ọdọ kan lori aago, amugbalẹgbẹ Tinubu feto iroyin, Tunde Rahman kede loju opo Twitter rẹ pe igbesẹ naa safihan pe oloselu to dantọ ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo díẹ̀ lára dúkìá tí jàǹdùkú sun níná l‘Eko torí ìwọ́de EndSARS
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
- Ooni Ogunwusi àti Wole Soyinka kòrò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate
O wa sapejuwe agba oselu naa bii "ẹni to rọrun lati ri, onirẹlẹ ẹda, to si n se atilẹyin fawọn ọdọ lasiko ti wọn n se iwọde alaafia EndSARS."
Rahman ni lai naani ọna arifin tawọn ọdọ naa gba ba Tinubu sọrọ, sibẹ o tiraka lati salaye awọn ọrọ naa fun wọn.
Tinubu ni ofege ati ẹbu ni iroyin to n ja kiri ori ayelujara nipa isẹlẹ ipaniyan to waye ni Lekki lọjọ Isẹgun.
Atẹjade naa ni Tinubu ko mọ awọn to n pe lori aago ri, sibẹ, o gbe ipe wọn, to si salaye fun wọn pe oun kọ ni oun ni ileesẹ LCC to n gba owo bode ni iloro Lekki.
Bakan naa lo ni Tinubu salaye pe oun ko mọwọ mẹsẹ lori bi awọn ologun se de bode Lekki lati doju ibọn kọ awọn ọdọ.
O ni lootọ ni Tinubu fidi rẹ mulẹ pe, bi gbogbo ọmọ Naijiria yoku se gbọ nipa rogbodiyan n waye lẹnu bode Lekki, naa ni oun naa gbọ.
Tinubu fikun pe oun ko ni imọ nipa isẹlẹ naa rara saaju akoko to waye, tabi ko awọn ologun ransẹ.
O wa tẹnumọ pe gomina Sanwo-Olu ti pasẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori isẹlẹ naa, to si rọ gbogbo araalu lati bomi suuru mu.
SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP ti kọwe mọ ijọba ati ileeṣẹ ologun Naijiria lọdọ ile ẹjọ agbaye to n gbọ ẹsun iwa ọdaran, ICC.
SERAP fẹsun kan ijọba apapọ pe o lo awọn janduku atawọn ologun lati mọọmọ pa awọn oluwọde l'Eko.
Ninu iwe to kọ si agbẹjọro agba ICC, Fatou Bensouda, o ni ki ile ẹjọ naa pe aṣoju ijọba Naijiria lati wa jẹjọ lori ẹsun ifẹmi awọn oluwọde ṣofo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
- Ooni Ogunwusi àti Wole Soyinka kòrò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate
- Ọ̀rọ̀ Nàíjíríà kúrò ní sinimá àwòrẹ́rìn-ìn, Buhari gbé ìgbésẹ̀ bíi òbí àti olórí - Obasanjo gbarata
- Ilẹ̀ Amẹ́ríkà wà lẹ́yìn àwọn olùwọ́de, Buhari dẹ́kun ìpànìyàn - Joe Biden
- Mọ̀ nípa DJ Switch, akíkanjú obìrin sàfihàn fídíò ìpànìyàn Lekki bó ṣe ń wáyé
O ni ki ICC "bẹrẹ iwadii ni kankan, lori iroyin to gbode nipa bi ijọba ṣe lo awọn tọọgi, ọmọ ogun atawọn oṣiṣẹ agbofinro, lati ṣẹru ba ati lati pa awọn oluwọde alaafia ni Abuja, Eko, Edo, Osun, Plateau ati ni Kano.
SERAP ni ki ile ẹjọ ọhun wadii awọn to wa nidi ikọlu naa, paapaa bi awọn oloṣelu, ọmọ ogun ati awọn oṣiṣẹ eto aabo to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Ninu iwe naa to kọ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ti igbakeji adari rẹ, Kolawole Oluwadare buwọlu, SERAP ni o ti pẹ ti ijọba Naijria ti maa n tẹ ẹtọ awọn ara ilu loju mọlẹ.
O ṣalaye pe "o ti lẹ ni ọpọlọpọ ọdun ti ijọba Naijiria kii le fi awọn to ba pa oluwọde jofin, eyii to ti wa di aṣa bayii."
Ajọ naa sọ siwaju si pe, ikọlu ti ijọba ṣe si awọn oluwọde ni Lekki, Alausa ati kaakiri Naijiria n ṣafihan pe, ijọba Buhari ko bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan, bakan naa ni ko naani ẹmi eeyan ati aye lati sọrọ bo ṣe wu wọn."
SERAP wa pe fun ki ile ẹjọ kan nipa fun ijọna Naijiria lati fi oju awọn aṣebi lede, ki wọn si fi wọn jofin.
Olusegun Obasanjo bọ́hùn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn
Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ke gbajare sita pe, asiko to fun aarẹ Muhammadu Buhari bayii lati sọrọ soke, ki ọrọ to kọja atunṣe bayii lorilẹede Naijiria.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si BBC News Yoruba, oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni nibi ti ọrọ de duro bayii, o ti kuro ni ere sinima, aarẹ si gbọdọ gbe igbesẹ akin, gẹgẹ bii obi ati olori.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ilẹ̀ Amẹ́ríkà wà lẹ́yìn àwọn olùwọ́de, Buhari dẹ́kun ìpànìyàn - Joe Biden
- Mọ̀ nípa DJ Switch, akíkanjú obìrin sàfihàn fídíò ìpànìyàn Lekki bó ṣe ń wáyé
- Buhari, máṣe gbá ìpànìyàn Lekki sórí ààtàn, kò yẹ́ kí ológun yin ọ̀dọ́ níbọn - Bode George
- Ọ̀kan lára olùwọ́de tó fara gbọgbẹ́ ní Lekki jáde láyé - Sanwo-Olu
- Kò sí olùwọ́de tó kú ní Lekki - Sanwo-Olu
- N kò lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn, kò dáa bí wọn ṣe lo ọta ìbọn ní Lekki - Tinubu
- Ọjọ́ Ìsẹ́gun di ọjọ́ ìbànújẹ́ fún ọ̀pọ̀ ìdílé ní Nàíjíríà torí òkú tó ṣùn
- Ọ̀dọ́ 30 ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn torí ọ̀gbẹ́ ìbọn ní Lekki - Sanwo-Olu ṣàlàyé
O ni aarẹ Buhari gbọdọ fi iwa irẹlẹ, ẹni to lẹran eeyan lara ati ijolootọ lati dahun si awọn ibeere awọn eeyan yii, ki o si rii daju pe idajọ ododo waye nibi to yẹ.
Bakan naa lo tun rọ awọn ọdọ to n wọde naa pe, ki awọn pẹlu gba alaafia laaye bi wọn ṣe n gbe ẹhonu wọn sita.
O ni kikọlu awọn dukia ati araalu yoo tubọ mu ki ipinya wa laarin wọn ni, eleyii to si lee da omi iṣọkan aarin wọn ru.
"Inu mi bajẹ gidigidi nipa rogbodiyan to n waye lọwọ bayii lorilẹede Naijiria; mo si n fi eyi rọ ijọba atawọn eeyan orilẹede Naijiria lati yago fun wahala ki wọn si gba alaafia laaye.