Lekki Shooting: UN, Biden, Clinton àtàwọn gbajúmọ̀ lágbááyé tó korò ojú sí ípànìyàn Lekki

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Akọwe Gbogboogbo fun ajọ agbaye, United Nations, Antonio Guterres, ti bu ẹnu ẹtẹ lu ipaniyan to waye nipinlẹ Eko ni ogúnjọ, oṣu Kẹwaa.

Ninu atẹjade kan ti agbenusọ rẹ, Stephane Dujarric, fi sita, o ba awọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn ninu iṣẹlẹ naa, to si tun gbadura fun ilera awọn to farapa.

Bakan naa lo kesi ijọba Naijiria lati ṣe iwadii àwọn to wa nidi ipaniyan ọhun, ko si fi oju wọn wina ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "ajọ agbaye ti ṣe tan lati ṣe iranlọwọ fun lori igbesẹ wiwa atunse."

Bakan naa ni Akọwe ijọba ilẹ America nigba kan, Hilary Clinton ti kesi Aarẹ Muhammadu Buhari, ati ileesẹ ologun Naijiria lati fi opin si pipa awọn ọdọ to ṣe iwọde #ENDSARS.

Joe Biden ni ki ologun ati Buhari fopin si ipaniyan

Oludije fun ipo aarẹ lorilẹede Amerika latinu ẹgbẹ oselu Democrat, Joe Biden, ti koro oju si iwa ipaniyan sawọn oluwọde naa.

Biden to kede bẹ́ẹ́ ninu atẹjade kan to fisita lori rogbodiyan Naijiria wa sọ̀ fun Buhari atawọn ologun lati dawọ ipaniyan naa duro.

Bakan naa ni Biden ni gba gba gba ni orilẹede Amẹrika wa lẹyin awọn oluwọde to n fi ẹhonu han wọọrọwọ.

Alufa ijọ Canterbury naa koro oju si isẹlẹ ipaniyan Lekki

Lara awọn ilumọọka l'agbaye to tun ti koro oju si ipaniyan ati idaru-dapọ to n waye ni Naijiria ni Olori Alufa ijọ Church of England ni Canterbury, Justin Welby.

Ninu ọrọ to kọ sori ayelujara Twitter rẹ ni owurọ Ọjọru, o ni oun koro oju si awọn iroyin ipaniyan to n waye nipinlẹ Eko, ati awọn ibomiran ni Naijiria.

O ni "mo ti rọ Aarẹ Buhari ni taara lati pèsè aabo fún ẹmi. Mo si tun n sọ ni gbangba bayii."

O ni oun ba Naijiria kẹdun, to si gbadura ki "Ọlọrun gba Naijiria là".

Kò sí olùwọ́de tó kú ní Lekki - Sanwo-Olu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti bawọn eeyan ipinlẹ Eko sọrọ lori ipaniyan to waye ladugbo Lekki nilu Eko.

Sanwo-Olu , ninu ikede rẹ to waye ni owurọ ọjọ Isẹgun salaye pe oun sepade peẹlu awọn asaaju ẹsin ati ẹgbẹ ajafẹtọẹni, tawọn si fẹnuko pe kawọn oluwọde naa maa pejọ si Alausa ati ẹnu iloro bode Lekki.

O ni ko si gomina ipinlẹ kankan to lasẹ lori ileesẹ ologun ilẹ wa ati bi wọn se n sisẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa fọwọ gbaya pe kó si eeyan kankan to ku ninu ikọlu ologun Naijiria s'awọn oluwọde ENDSARS ni Lekki lọjọ Isẹgun.

O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn parọwa sawọn oluwọde lati tuka ki aago mẹrin irọlẹ to lu, amọ arọwa awọn ko se aseyọri ni Lekki.

Sanwo-Olu ni meji ninu awọn eeyan to fara gba ọgbẹ ni Lekki ni wọn sisẹ abẹ fun loru mọju, ti ara wọn si ti n balẹ.

"Mo si ti pasẹ pe ki wọn so gbogbo isẹ ijọba rọ na fun ọjọ mẹta, ayafi awọn osisẹ alaabo nikan.

Bakan naa ni mo pasẹ pe ka fa asia Naijiria wa silẹ fun ọjọ mẹta lati sedaro awọn eeyan to ba iwọde EndSARS lọ."

O wa fi da awọn eeyan ilu Eko loju pe, oun yoo sa ipa oun lati se awari awọn ohun to sẹlẹ ni Lekki lalẹ ọjọ Isẹgun.

O ni oun ati àwọn amugba legbe oun ati Komisana ilera sabewo s'awọn ile ìwòsan to wa ni Eko mojumọ, la ti ki awọn to f'arapa.

Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwo Olu tun kesi awọn ọdọ ati oluwọde ipinlẹ Eko lati faaye gba alaafia laaye.