You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lekki Toll gate: Àwọn ọlọtẹ̀ ló ń gbìyànjú láti dá ọ̀tá sílẹ̀ láàrin èmi àti ẹ̀yin ènìyàn mi - Jagaban
Agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ni gbogbo asiko iwọde EndSARS atohun to tẹyin rẹ wa to fi mọ iṣẹlẹ pipa awọn oluwọde kan ni Lekki Tollgate l'Eko kan tun n ba ọrọ jẹ fun oun ni.
Tinubu figbe ọrọ yii bọ ẹnu nigba to ri i pe ẹjọ nihin lọhun fẹ pọ lori oun. o ni lakọkọ, wọn fẹsun kan oun pe oun lo ṣagbatẹru ifẹhonuhan ọhun, nigba to ya wọn tun ni oun lo ran awọn lati yinbọn lu awọn oluwọde ni ibode Lekki lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja lati tu wọn ka.
Tinubu ni iṣẹ awọn ọta leleyii tori wọn n sọ pe oun n pa owo latara Lekki Tollgate ọhun tẹlẹ toun si ti n padanu rẹ lọpọlọpọ nitori iwọde.
Ẹwẹ, Asiwaju ṣapejuwe pe irọ patapata gbaa ni wipe awọn to n ditẹ mọ oun ninu oṣelu lo kan n lo wọn lati kẹyin oun ati ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ sira.
Ṣaaju ninu ọrọ kan to sọ lọj Aiku nigba ti wọn fi ọrọ wa Tinubu lẹnu wo lo ti s pe oun kọ ni alakoso Lekki Tollgate, oun ko si ni owo nibẹ.
Ṣugbọn o gba o si sọ pe "emi ni alagbatẹru ati oludari agba ileeṣẹ iroyin the Nation ati ileeṣ amohunmaworan TVC" eyi ti awọn janduku tun kọlu ti wọn si jo nina rau-rau.
Tinubu ni sibẹsibẹ, oun ko ran sọja tabi ọlọpaa lati dena oun ti wọn ṣe si awọn ileeṣẹ oun tori oun ko fẹ ki ẹnikẹni ku bo tilẹ jẹ pe idokoowo oun ni wọn bajẹ.
O ni iṣẹlẹ to n waye yii ko ṣe oun lanfani kankan nipa ti oṣelu tabi na miiran bikoṣe pe o tun ba ọrọ jẹ fun oun ni toripe ọpọ eeyan lo n tabuku ba oun lọna aitọ si ohun ti oun ko mọwọ mẹsẹ.
"Amọ sibẹ sibẹ, mo duro lẹyin awọn ọmọ Naijiria digbi lati ṣe iwọde alafia".
Ọ̀nà láti sọ ọ̀rọ̀ ajé ilẹ̀ Yorùbá di akúrẹtẹ̀ ni àwọn ìkọlù tó wáyé ní Eko - Àwọn gómìnà
Awọn gomina kan ni ẹkun Iwọ-oorun Gusu Naijiria ti ṣe abẹwo ibanikẹdun si gomina ipinlẹ Eko, Bababjide Sanwo-Olu.
Abẹwo yii ko yọ awọn minisita kan to jẹ ọmọ ilẹ Yoruba silẹ.
Ni ile ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Marina ni Sanwo-Olu ti gba wọn ni alejo.
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, Kayode Fayemi ti Ekiti, Gomina Rotimi Akeredolu lati ipinlẹ Ondo, to fi mọ minisita fun ina mọnamọna, Babatunde Fashola, minisita fun ọrọ awọn ọdọ ati idagbasoke ere idaraya, Sunday Dare.
Lara awọn to tun wa nibi abẹwo naa ni minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Aregbesola, ati minisita keji fun eto ilera, Olorunninbe Mamora, to fi mọ minisita fun okoowo ati ọrọ awọn ileeṣẹ, Niyi Adebayo.
Minisita fun iwakusa, Olamilekan Adegbite naa wa nibẹ.
Lasiko abẹwo naa ni Gomina Sanwo-Olu mu wọn lọ si diẹ lara awọn dukia ijọba ati aladani ti awọn janduku dana sun.
Gẹgẹ bi Akọwe iroyin ati ikede fun Gomina Sanwo-Olu, Gboyega Akosile ṣe sọ, Gomina ipinlẹ Ondo, to tun jẹ olori awọn gomina nilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu ṣapejuwe iṣẹlẹ to waye nipinlẹ Eko, gẹgẹ bi ibudo ogun.
O ni eyi ko ṣẹyin iye nkan ti awọn janduku to ja iwọde ENDSARS gba, bajẹ.
"Awọn nkan to ṣẹlẹ yii, mu ki a gbagbọ pe ọrọ naa kii ṣe oju lasan.
"Awọn nkan to ṣẹlẹ yii tu aṣiri pe ẹkun yii wa ninu ewu lọwọ awọn to fẹ sọ ọrọ aje rẹ di akurẹtẹ."
Àwọn ìbéèrè tí Tinubu bi gómìnà Sanwo-Olu àtàwọn olùwọ́de tó faragbọta ní Lekki Tollgate rèé
Agba ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ni oun ti beere lọwọ gomina ipinlẹ Eko boya oun lo fun awọn ṣọja to yinbọn ni agbegbe Lekki lalẹ ọjọ Iṣẹgun lasẹ lati yin si awọn oluwọde nibẹ.
Bọla Tinubu sọ eyi di mimọ lasiko to ṣabẹwo si gomina Sanwo-Olu ni ile ijọba ipinlẹ Eko to wa lagbegbe Marina.
Tinubu to ni idi abẹwo oun gan ni lati mọ hulẹhulẹ iṣẹlẹ naa ni lara awọn ibeere ti oun wa bi gomina Sanwo-Olu nipa iṣẹlẹ naa ni pe 'ṣe oun lo paṣẹ ki awọn ṣọja yinbọn sawọn oluwọde naa?"
Bi kii ba ṣe oun, ta lo paṣẹ naa?" "ṣe o mọ pe wọn kọlu awọn eeyan nibi iṣẹlẹ naa?
Bakan naa ni Oloye Tinubu tun jẹ ko di mimọ peawọn oluwọde to wa ni agbegbe Lekki Tollgate lasiko ti iṣẹlẹ naa waye pẹlu ni ibeere lati dahun leyi to ni yoo ran ijọba lọwọ lati lee ṣi aṣọ loju ohun gbogbo to ṣokunkun sraye nipa ikọlu naa.
Awọn ibeere to ni awọn oluwọde naa gbọdọ fesi si niyi.
1.Bawo ni wọn ṣe de ibẹ?
2.Iye asiko wo ni wọn fi wa nibẹ
3.Iru awọn eeyan wo ni awọn oluwọde to wa nibẹ.
Èmi ṣì ni Jagaban, aṣíwájú Eko gangan, èmi ò lè sá kúrò l'Eko- Ahmed Tinubu
Agba ọjẹ oloṣelu ninu ẹgbẹ All Progressives' Congress, APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ṣe abẹwo si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lati ba a kẹdun lori awọn iṣẹlẹ to waye nipinlẹ Eko l'ọsẹ yii.
Lasiko abẹwo naa to waye nile ijọba ipinlẹ ọhun to wa ni Marina nilu Eko, ni Tinubu ti ba awọn oniroyin sọrọ, to si sọ pe irọ ni iroyin to sọ pe oun sa kuro ni Naijiria lasiko rogbodiyan to waye.
Bakan naa lo sọ pe awọn to fi ara gbọta nibi iṣẹlẹ ipaniyan to waye ni Lekki "naa ni ẹjọ lati jẹ́".
O sọ pe wọn ni lati sọ iru eeyan wo ni wọn jẹ, bawo ni wọn ṣe de ibẹ, ati pe bawo ni wọn ṣe pẹ to nibẹ.
"Lootọ la fẹ ẹ ranwọn lọwọ, ṣugbọn a ṣi gbọdọ gba ọrọ ti yoo ran ijọba lọwọ lati le mura silẹ fun ọjọ iwaju, ati lati mọ igbesẹ to yẹ."
Asiwaju Tinubu sọ pe oun ko kuro ni ilu Eko. O ni "mi o lọ si ibi kankan, ọmọ Eko ni mi, eminaa si ni Asiwaju ilu Eko.
"Emi ṣi ni Jagaban."
Awọn iroyin kan sọ pe ni kete ti wahala #ENDSARS gba ọna miran yọ, ni Ahmed Tinubu ti salọ si ilu Paris, l'orilẹ-ede France. Awọn kan tiẹ tun sọ pe ilu London lo salọ.
Bakan naa lo sọ pe oun kẹdun pẹlu ẹbi awọn to ku, ati awọn to farapa nibi iṣẹlẹ to waye."
O sọ pe "mo wa lati ba gomina kẹdun, ati lati tọrọ aaye lọwọ rẹ lati ṣe abẹwo si diẹ lara awọn to farapa, to ṣi wa nile iwosan, ati lati mọ bi ao ṣe pese iranlọwọ lori igbesẹ ti ijọba fẹ ẹ gbe."
O ni ayederu iroyin ni awọn iroyin to sọ pe oun salọ, tabi pe awọn kan ji ọmọ rẹ ọkunrin, Seyi Tinubu gbe nitori iṣẹlẹ naa.
N kò lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn, kò dáa bí wọn ṣe lo ọta ìbọn ní Lekki - Tinubu
Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe, oun ko lee ba ẹnikẹni lọwọ ninu iṣekupani ọpọ eniyan.
Tinubu lo sọ ọrọ naa, nigba to n da si bi awọn ọmọ ileeṣẹ ologun ṣe ṣina ibọn bolẹ fun awọn olufẹhonuhan End SARS ni Lekki Toll Gate, to wa ni ilu Eko lọjọ Iṣẹgun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọjọ́ Ìsẹ́gun di ọjọ́ ìbànújẹ́ fún ọ̀pọ̀ ìdílé ní Nàíjíríà torí òkú tó ṣùn
- Ọ̀dọ́ 30 ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn torí ọ̀gbẹ́ ìbọn ní Lekki - Sanwo-Olu ṣàlàyé
- Àwọn ṣọ́jà ṣíná ìbọn bolẹ̀ ni Lekki Tollgate
- Àwọn ọlọ́dẹ darapọ̀ mọ́ ìwọ́de #EndSARS l'Osogbo, wọ́n ní kò sáyè fún jàǹdùkú mọ́
- Kíní ìtumọ̀ ''Sọ̀rọ̀ Sókè'' tí àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ń lò káàkiri
- Ìpínlẹ̀ Ogun náà ti ilé ìwé títí dí ọjọ́ Ajé tó m bọ̀, kò ní sí lílọ bíbọ̀ ọ̀kádà fún wákàtí 24
O sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Channels pe, ko bojumu to bi awọn ọmọ ogun naa ṣe lo ọta ibọn to lee gbẹmi eeyan lati tu awọn oluwọde ka.
Tinubu bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti awọn ọmọ ogun naa gbe.
O ni "Emi ko le darapọ mọ ẹnikẹni lati gba ẹmi ọpọ ero, lai lai.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa sọ pe kii ṣe oun lo ni ileeṣẹ Lekki Concession Company, to n mojuto bi Toll Gate naa ṣe n pa owo wọle fun ijọba Eko.
O ni "Mi o lọwọ ninu Toll Gate, bẹẹ ni kọbọ mi ko si nibẹ."
Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC naa tẹsiwaju pe oun ko mọwọ mẹsẹ ninu bi Toll gate ṣe n pa owo wọle, bẹẹ si ni oun ko lọwọ ninu iku awọn oluwọde.
Wahala bẹ silẹ ni Toll Gate naa lẹyin wakati diẹ ti ijọba ipinlẹ Eko kede ofin konile-o-gbele, ṣugbọn ti awọn oluwọde ọhun kọ lati fi agbegbe naasilẹ.
O kere tan, ọgbọn eeyan lo fara gbọgbẹ ọta ibọn lẹyin ti awọn ologun sina bolẹ nibẹ.
Ṣugbọn ileeṣẹ ologun ti sẹ pe oun ko mọwọ mẹsẹ ninu bi wọn ṣe dana ibọn bo awọn oluwọde.
Tẹ́ bá fẹ́ lo ìwọ́de láti gba àkóso ìjọba, wọn yóò dá yín lẹ́kun - Tinubu
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko ati asiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, ti sọrọ nipa iwọde ENDSARS to gbode jake jado Naijiria.
Tinubu, ninu ikede to fi sita loju opo Twitter rẹ lọjọ Aje ni lootọ lawọn oluwode lẹtọ lati fehonu han ṣugbọn nibi ti wọn ba ọrọ de yii,asiko to lati sinmi iwọde.
O ti pe ọjọ mejila ti iwọde ENDSARS naa ti bẹrẹ yika Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Owó ìrànwọ́ Covid-19 dé, ìjọba fẹ́ san ₦75bn fún 54,000 olókoòwò
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti iléèwé pa nítorí ìwọ́de #EndSARS
- Ìrẹ̀wẹ̀sì ń bá wa torí ìdánwò NECO tẹ ń ṣún síwájú lọ́pọ̀ ìgbà - Akẹ́kọ̀ọ́, ọ̀gá iléèwé
- Agbára ìgbìmọ̀ ìdájọ tí mo gbé kàlẹ̀ yóò dé ọ̀dọ̀ àwón ólọ́pàá tó ti kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́lẹ̀- Sanwo Olu
- Wo àwọn orílẹ̀èdè míràn tó ń fojú winá ìwọ́de bíi ti ENDSARS
- Mo fura pé ẹ fẹ́ da Nàíjíríà rú, ń kò ṣe ìwọ́de mọ́ - Segalink, agbátẹrù ìwọ́de yọwọ́
- SERAP pe Buhari, igbákejì rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí àfikún owó iná àti epo bẹntiró
Bakan naa lo tun kan sara si ipinnu awọn oluwọde naa, to si bẹnu atẹ lu awọn janduku to n da omi alaafia Naijiria ru.
"Ẹ́yin ọdọ ti ri ere nipa awọn tẹ n beere fun lati ipasẹ iwọde tẹ n se, amọ, ẹ gbọdọ sọra se, kẹ ma ba padanu awọn ere naa nitori bi iwọde ọhun se n di ọlọjọ gbọọrọ.
Tinubu ni awọn oluwọde ni lati fun ijọba Buhari laaye, ko le ṣe amuṣẹ awọn ileri to fẹ ṣe nipa ọrọ to wa nilẹ yii, paapa atunto ileeṣẹ ọlọpaa.
Diẹ ree ninu ọrọ rẹ, gẹgẹ bí o ti ṣe kaa silẹ loju opo Twitter:
- Tinubu tun sọ pe ohun to pọn awọn ọdọ le ni ki awọn oluwọde fún ìjọba nigba diẹ ki wọn le fi ṣe ayipada ti wọn n beere fun, amọ o ni eyi ko le waye ni kiakia
- Asiwaju ni bi ijọba ṣe yara da awọn oluwọde lohun lọtẹ yíi ṣafihan pe, ijọba ti yipada ni daada
- O ni awọn oluwọde ti ṣe aṣeyọri to gbọngbọn lẹnu igba ti iwode bẹrẹ amọ ki wọn sọra lati mase padanu aṣeyọri naa nipa aifi ẹlẹ ṣe ati aironujinlẹ
- Tinubu ko salai mẹnuba ọrọ bi awọn janduku se sa sabẹ iwọde lati maa dun koko mọ ara ilu, ti wọn n ba karibujẹ ti wọn kaakiri
- O ni erongba awọn agbatẹru iwọde naa ni ki ijọba mu iyipada ba iṣẹ ọlọpaa, eyi ti wọn sì ti n ṣe
- O ni wọn ko le wa yipada lati gba akoso mọ ijọba lọwọ amọ bi wọn ba wa ni ero ọkan yii lati gba ijọba, ijọba yoo gbe igbesẹ lati dẹkun wọn lọna ati fi idi ijọba awaarawa rinlẹ
- Bẹẹ naa ni Tinubu sọ pe iṣọwọ ṣe iwọde yii fi han pe ijọba tiwantiwa n gbooro si ni Naijiria
- Ṣugbọn o ni k'awọn oluwọde ṣe jẹjẹ ki wọn ma ba fi ọwọ ara wọn pa igi ominira ti wọn n lọ silẹ yii.
Igba akọkọ ree ti Tinubu yoo da sí iwọde to gba ile, gba oko ni Naijiria.
Kaakiri Naijiria si ni iwọde yii ti ṣe idiwọ fun lilọ bíbọ ọkọ ati ero, to si tun mu ki ọrọ aje dẹnu kọlẹ pẹlu.
Wo àwọn orílẹ̀èdè míràn tó ń fojú winá ìwọ́de bíi ti ENDSARS
Bi awọn ọdọ lorilẹede Naijiria ṣe n wọde lati tako iwa kotọ awọn ọlọpaa ati iṣejọba ti ko fararọ lati nnkan bii ọsẹ kan sẹyin,iwọde n lọ lawọn agbegbe miran lagbaye, ojo iwọde Naijiria to n rọ ni ko jẹ kaye mọ pe awọn eeyan iwọde ,miran lagbaye n tọ sara.
Ni ilẹ Afirika nikan, orilẹede Ivory Coast ati Namibia naa n foju wina tiwọn titi kan awọn orilẹede bii Hong Kong, Thailand, Chile ati Belarus lawọn eeyan ti n fi ẹhonu wọn han lori ọkọ o jọkan idi to kan koowa wọn.
Nigeria
Ni ibẹrẹ oṣu kẹwaa ọdun 2020 ni iwọde fopin si iwa kotọ ọlọpaa ti ọmọ si #ENDSARS bẹrẹ ni Naijiria.
Ninu iwóde yii ni ogunlọgọ awọn ọdọ ti ya bo igboro lati pe fun wiwagbo dẹkun si iwa aitọ awọn ọlọpaa.
Koko ẹhonu marun un lawọn oluwọde naa gbe kalẹ pe awọn fẹ ki ijọba mojuto ki wọn si tete gbe igbesẹ to tọna lori rẹ.
Nitori eyi ileeṣẹ ọlọpaa pa ikọ SARS rẹ; bẹẹni ijọba apapọ ti ṣalaye fawọn ipinlẹ gbogbo lorilẹede Naijiria lati tete gbe igbimọ oluwadi kalẹ lati boju wo gbogbo ẹsun ati ẹhonu tawọn araalu n gbe sita.
Igbimó naa yoo mojuto ọrọ naa ki wọn si gbe lọ siwaju ileeṣẹ eto idajọ fun eto to tọ labẹ ofin.
Namibia
Ni ọjó kẹjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, awọn eeyan orilẹede Namibia ya wọ oju popo gbogbo lolu ilu orilẹede naa, Windhoek.
Wón se eyi lati fi ẹhonu han tako iwa ipa si awọn obinrin lẹyin ti awọn ọlọpaa ri oku arabinrin kan, Shannon Wasserfall lẹyin oṣu mẹfa ti wọn ti n wa a.
Afẹfẹ tajutaju tea gas, ọta ibọn onirọba ni awọn ọlọpaa fi tu awọn oluwọde naa ka.
Orilẹede Namibia wa lara awọn orilẹede ti iwa ifipabanilopọ pọ ju si ni Africa
Chile
Ni oṣu kẹwaa, ọdun to kọja lawọn ara Chile ni tiwọn ti n wọde nitori owo ọkọ to gbowo leri.
Amọṣa iwọde naa ba tun yipada si eyi ti a fi n fẹhonu han lori ọwọngogo , aisi iṣuna to jọju fun ẹka eto ẹkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ
Ni ọjọ kejidinlogun ni awọn oluwọde naa rin kaakiri fun ayajọ ọdun ti kan iwọde wọn a
Awọn ọlọpaa só pe awón ọlọpaa mejidinlogun ni o fara pa nibi iwọde naa.
Thailand
Ọpọ ọdọ lorilẹede Thailand lo n wọde nibi ti wọn ti n ke si olotu ijọba orilẹede naa, Pratyuth Cha-ocha o kọwe fi ipo silẹ
Awọn ọdọ naa n beere fun atunṣe iwe ofin orilẹede naa, ki wọn si ṣeto idibo tuntun, ki wọn si tun fi opin si idunmọhuru sawọn ajafẹtọ araalu nibẹ.
Hong Kong
Iwọde tako ijọba ni Hong Kong ti n walẹ diẹdiẹ.
Abadofin kan lori lile eeyan kuro ni orilẹede naa lo tan ina wa ibinu araalu nibẹ.
Abadofin naa yoo fun awọn afurasi iwa ọdaran lanfani ati gbe ni orilẹede China bẹrẹ lati ọjọ kini, oṣu kẹrin nitori ninu ero wọn, abadofin naa yoo fi idajọ ododo dun awọn ọmọ HongKong.
Ehonu marun un ni wọn gbe ka iwaju ijọba.
Belarus
Idibo ni Belarus nibi ti olori ilẹ naa, Alexander Lukashenko to ti wa nipo fun ọpọlọpọ ọdun tun bori lo fa wahala iwọde ni Belarus pẹlu bi ọpọlọpọ awọn eeyan ṣe n ni makaruru wa ninu idibo naa lati gbe Lukashenko
O le lẹgbẹrun lọna ọgọrun un awọn eeyan to peju si Central Minsk, to jẹ olu ilu orilẹede naa fun ọjọ Aiku mẹrin ọtọtọ ni ṣiṣẹ n tẹle, bẹẹni o le ni ẹgbẹta eeyan tawọn agbofinro ti de mọ kulu ahamọ .