You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS Protest Update: DJ Switch ṣàlàyé ohun tójú rẹ̀ rí níbi ìfẹ̀míṣòfò àwọn olùwọde EndSARS ní Lekki
Gbajugbaja aseto orin to wa nibi iṣẹlẹ iṣekupani tawọn oluwọde to waye ni Lekki Toll Gate ni ilu Eko, DJ Switch, ti ṣalaye ohun toju rẹ ri lọjọ naa.
DJ Switch ni awọn ọmọ ogun to dihamọra atawọn ọlọpaa, lo ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde EndSARS lalẹ ọjọ Iṣẹgun.
DJ Switch lo sọ ọrọ naa ninu fidio to fi lede loju opo Instagram rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Apena fẹ́gbẹ́ Oṣugbo, Opa, Akala àtẹ̀yin awo, ẹ wa ọ̀pá àṣẹ Ọ́ba Akiolu jáde"
- Àwọn jàńkùkú tún padà lọ fọ́ ShopRite Ilorin lónìí lásìkò ìṣéde
- Ikú Aráàlú 51, ọlọ́pàá 11, Sọ́jà 7 tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS dùn mí - Buhari
- Ẹ wo ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ saájú nípa làásìgbò EndSARS
- Májèlé olóró lẹ jí l‘Ekiti dípò èròjà oúnjẹ Covid-19 - Ariwo sọ lórí ayélujára
- Ẹ sọ́ra fún ìwà olè àti jàgídíjàgan nílẹ̀ Yorùbá-Sunday Igboho
- ₦147m la rí kójọ fún ìwọ́de, a kò fẹ́ owó mọ́, ìwọ́de ti parí - Feminist Coalition
- Sanwo-Olu kéde ìlànà ìséde tuntun l'Eko
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn kan se lọ pín "CaCovid 19 Palliative" ní Ilorin pé...
O ni ko din ni eeyan marundinlogun to di oloogbe nibi iṣẹlẹ naa, ti oun atawọn olufẹhonuhan miran si gbe awọn to ṣeṣe lọ ba awọn ọmọ ogun, ti awọn ọmọ ogun naa si gbe oku wọn lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ohun kan ti oun kabamọ ni bi wọn ṣe gbe oku awọn eeyan lọ ba awọn sọja ọhun.
DJ Switch ni "Mo kabamọ pe a ṣe bẹẹ nitori ṣe ni awọn ọmọ ogun naa ko oku awọn eeyan naa sinu ọkọ, ti wọn gbe wa."
Bakan naa lo tun ṣafihan awọn ọta ibọn to ri ṣa lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.
O sọ pe awọn ọlọpaa wa si ibi ti iṣẹlẹ naa to waye lẹyin ti awọn ọmọ ogun kọlu wọn tan, ti wọn si fi gaasi tajutaju tu wọn ka.
Dj Switch tun tan imọlẹ si awọn ọrọ kan to ti n tan ka lori ayelujara nipa awọn ohun to ti sọ ṣaaju.
O ni "ẹ jọwọ mi o ṣọ pe eeyan 78 lo ku o, nigba ti mo n ṣe fidio lọwọ, awọn meje ti ku silẹ, ṣugbọn lẹyin ti ẹrọ ibanisọrọ mi ku, awọn 15 miran tun dagbere faye."
Bo tilẹ jẹ pe o sọ pe oun ko le fidi rẹ mulẹ boya wọn ju bẹẹ lọ, ṣugbọn o fi kun pe ọpọ eeyan lo fara gbọta ibọn.
Akinkanju obinrin naa pari ọrọ rẹ pe, oun ko faramọ bi awọn eeyan ṣe n jo awọn ọkọ akero, ṣugbọn oun yoo ṣi tun kopa ninu iwọde kannaa lọjọ iwaju.
Orukọ abisọ DJ Switch ni Obianuju Catherine Udeh, o jẹ olorin to gbegba oroke ninu idije X Factor akọkọ iru rẹ, ti ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ Glo ṣagbatẹru rẹ lọdun 2013.
Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa akíkanjú obìrin tó kópa nínú ìwọ́de End SARS?
Ni kete ti iroyin gbode pe awọn ọmọ ileeṣẹ ologun ti kalẹ si Lekki Toll Gate ni ilu Eko, ti iro ibọn si n dun lọtun losi ni DJ Switch bẹrẹ si n ṣe fidio lati lati agbegbe naa loju opo Instagram rẹ lori bo ṣe n lọ.
Fidio ọhun ṣafihan bi awọn eeyan ṣe fara gba ọta ibọn, ti awọn oluwọde to wa nibẹ si n gbiyanju lati yọ ọta ibọn naa, ati lati doola ẹmi awọn eeyan miran to farapa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari, máṣe gbá ìpànìyàn Lekki sórí ààtàn, kò yẹ́ kí ológun yin ọ̀dọ́ níbọn - Bode George
- Ọ̀kan lára olùwọ́de tó fara gbọgbẹ́ ní Lekki jáde láyé - Sanwo-Olu
- Kò sí olùwọ́de tó kú ní Lekki - Sanwo-Olu
- N kò lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn, kò dáa bí wọn ṣe lo ọta ìbọn ní Lekki - Tinubu
- Ọjọ́ Ìsẹ́gun di ọjọ́ ìbànújẹ́ fún ọ̀pọ̀ ìdílé ní Nàíjíríà torí òkú tó ṣùn
- Ọ̀dọ́ 30 ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn torí ọ̀gbẹ́ ìbọn ní Lekki - Sanwo-Olu ṣàlàyé
- Àwọn ṣọ́jà ṣíná ìbọn bolẹ̀ ni Lekki Tollgate
- Àwọn ọlọ́dẹ darapọ̀ mọ́ ìwọ́de #EndSARS l'Osogbo, wọ́n ní kò sáyè fún jàǹdùkú mọ́
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ologun ti sẹ pe oun ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ibeere ti awọn eeyan n bere bayii ni pe, ta ni akinkanju obinrin DJ Switch yii gan?
Ta ni DJ Switch?
Orukọ abisọ DJ Switch ni Obianuju Catherine Udeh, o jẹ olorin to gbegba oroke ninu idije X Factor akọkọ iru rẹ, ti ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ Glo ṣagbatẹru rẹ lọdun 2013.
O jẹ ọmọ ilu Udi, ni ipinlẹ Enugu, oun si ni abikẹyin iya rẹ.
O kẹkọọ jade ninu imọ Geology ni Fasiti ijọba apapọ to wa ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers.
Okiki rẹ bẹrẹ si n kan lẹyin ti oun ati ẹgbẹ rẹ Da Pulse jawe olubori ninu idije orin Star Quest lọdun 2009.
Lẹyin naa lo gbe awo orin kan jade eyii to pe akori rẹ ni "So tey," ti olorin takasufẹ ilẹ Amẹrika, Busta Rhynes kopa ninu rẹ.
Ko pẹ si asiko naa to darapọ ileeṣẹ to n gbe orin jade, Sony Music.
DJ Switch jẹ ọkan gboogi lara awọn to n lọgun iwọde End SARS lori ayelujara.