Fashola EndSARS Protest: Fashola rí kámẹ́rà he ní ibùdó ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate, àwọn ọmọ Nàìjíríà bá figbe ta

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ni ọjọ Aiku ni awọn minisita atawọn gomina kan ṣabẹwo si ilu Eko lati wo bi ọrọ ṣe lọ lasiko iwọde to di gbodonroṣọ nibẹ.

Lasiko abẹwo wọn si agbegbe Lekki Tollgate nibi ti wahala ti ṣẹlẹ laṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ni minisita fun akanṣe iṣẹ, Babatunde Raji Fashola ṣadede ṣe awari ẹrọ ayaworan, kamẹra kan eleyi ti wọn ni o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn eeyan kan lo fi sibẹ ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Lọgan ti Fashọla to lewaju ikọ ti aarẹ Buhari ran si ipinlẹ Eko lori iṣẹlẹ naa ri kamẹra naa lo fi aṣọ ilewọ kan mu u ti o si fun gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fun ayẹwo iwadii.

Gẹgẹ bi ohun ti gomina Eko tẹlẹ ri naa sọ, o ṣeeṣe ki o jẹ pe awọn kọlọransi kan ṣaaju iṣẹlẹ to ṣẹ nibẹ lọjọ Iṣẹgun.

Ki ni awọn ọmọ Naijiria n sọ?

Iṣẹlẹ yii si ti n gbe ọpọlọpọ ariwo sita loju opo ayelujara bii Twitter.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n ja ara jẹ pe ọrs naa fẹ ṣebi eyi to mu ifunra dani.

Ẹ jẹ ka wo bi wọn ṣe sọ ọ lọkọọkan, ejeeji.

Awọn eeyan kan bii @yjpictures, @Wande_SHO, @lgc_pacman, @iam_ABC12 atawọn miran woye pe ṣe kamẹra naa ni ogun asọ ina di omi ni tabi ayẹta to fi jẹ wipe gbogbo bi wọn ṣe dana sun ibudo igbowo ode naa ina ko kan an rara.

Ẹwẹ, awọn miran n pariwo pe arumọjẹ lasan lawọn ijọba n fẹ fi ọrọ naa ṣe ati pe wọn ti fẹ maa mu araalu ni mugun niyẹn o.

Awọn eeyan bii@dami_lanre, @ifebanjo, @Babel411, @Abbey0057

Bakan naa lawọn miran bii @Henry_EI, @alrhemist naa n pariwo lori ayelujara pe ṣe gbogbo iroyin pe awọn oṣiṣẹ ajọ gbalẹ-gbadọti ni ipinlẹ Eko, LAWMA ti gba agbegbe Lekki Tollgate naa ṣaaju abẹwo awọn gomina ọhun ko kan ibi ti ẹrọ ayaworan naa wa ni.

Ọ̀kan lára olùwọ́de tó fara gbọgbẹ́ ní Lekki jáde láyé - Sanwo-Olu

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii lo ni ọkan ninu awọn ọdọ to fara gbọgbẹ ninu ipaniyan Lekki ti jade laye.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lo kede bẹẹ loju opo Twitter rẹ laarọ ọjọbọ.

O ni ori ti ọdọ naa fi sese lo sokunfa iku to paa

Gomina Sanwo-Olu wa kẹdun lori isẹlẹ naa, to si ni o ba oun lọkan jẹ.

Amọ ko sai fikun pe oun si n tẹsiwaju lori iwadi oun lori isẹlẹ naa.

Mò ǹ wá ọ̀dọ́ Lekki tó farapa láti fún wọn ní ìrànwọ́ - Anthony Joshua

Ilumọọka abẹsẹkubiojo ọmọ Naijiria nii, Anthony Joshua ti dara pọ mọ awọn gbajumọ ati eekanlu jakejado agbaye, to n bẹnu atẹ lu bi awọn ologun ṣe yinbon pa awọn oluwọde ENDSARS ni ilu Eko.

Lalẹ ọjọ Isẹgun ni ikọlu naa waye lẹyìn ti ijọba kede isede ni Eko, tawọn ologun si pa awọn oluwọde kan ni Lekki, bẹẹ ni ọpọ ọdọ bii ọgbọn fara gbọgbẹ.

Nigba to n gbara ta lori isẹlẹ naa loju opo Twitter rẹ, Anthony Joshua ni nnkan ti wa buru gan bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ipaniyan to n waye yii pakasọ, to si ṣe eemọ pe "gbogbo nnkan yii n waye nitori awon eeyan fẹ gbe ni alaafia?"

Joshua wa gba ladura pe, ki eledua jẹ ki alaafia jọba ni Naijiria tii ṣe orileede abinibi oun.

O ni oun n wa awọn ile iwosan ti oun le fi ounjẹ ati iranwọ ranṣẹ si, titi ti oun yoo fi le ṣe nkan miran.

Yatọ si Joshua, Odion Ighalo to jẹ agbabọọlu Naijiria naa da si ọrọ yii.

Ninu fọnran fidio kan to fi sita loju opo Twitter rẹ, Ighalo ni inu oun bajẹ nitori nnkan to n waye ni Naijiria.

O ni lootọ loun kii dá si ọrọ oṣelu ṣugbọn eyi to nsele yii, oun ko le dakẹ.

O wa kọju ọrọ rẹ si ijọba Naijiria pe, wọn ko lojuti pẹlu bi wọn ti ṣe doju ibọn kọ awọn oluwọde to n fehonu han.

Irufẹ ọrọ iporuru ọkan bayii tun waye lati ọdọ Trevor Noah, tii se adẹrinposonu ọmọ ilẹ South Africa ati Kamaru Usman ọmọ Naijiria abẹsẹkubiojo mii to wa nilẹ okere.

Loju opo Twitter wọn ati t'awọn mii bíi iyawo aarẹ Amẹrika tẹlẹ, Hillary Clinton niṣe ni wọn n kesi aarẹ Buhari lati dẹkun ipaniyan to n waye.

Àwọn ọlọ́dẹ darapọ̀ mọ́ ìwọ́de #EndSARS l'Osogbo, wọ́n ní kò sáyè fún jàǹdùkú mọ́

Awọn ọdẹ nipinlẹ Ọṣun ti darapọ mọ awọn oluwọde #EndSARS ni ilu Oṣogbo pẹlu ikilọ fawọn janduku pe ki wọn rin jinna si iwọde naa.

Alaga awọn ọlọdẹ naa labẹ aṣia Hunters Guild of Nigeria, Nurein Hameed koro oju si bi awọn janduku kan ṣe n fi iwọde naa boju lati hu iwa ibi.

Ẹgbẹ awọn ọlọdẹ naa wa jẹ ko di mimọ pe awọn ko ni la oju awọn silẹ ki awọn kọlọransi ẹda kan wa fi iwa buruku ọwọ wọn ba oju awọn oluwọde #EndSARS naa ati ohun ribiribi ti wọn n gbe ṣe jẹ.

Awọn ẹgbẹ ọlọdẹ naa ni awọn ṣetan lati maa pese abo fun awọn to n wọde naa .

Bakan naa ni wọn koro oju si bi awọn eeyan kan ṣe kọlu gomina ipinlẹ naa, Gboyega Oyetọla lopin ọsẹ to ksja, eleyi ti wọn ni o ku diẹ kaa to gidigidi.

Ìpínlẹ̀ Oyo àti Osun sàlàyé ìdí tí wọn kò fi tí ṣè ifilolẹ ìgbìmò igbẹjọ aṣemáṣe SARS

Lara ẹdun ọkan awọn oluwọde ENDSARS ni Naijiria ni pe ki ijọba ṣe agbekalẹ igbimọ ti yoo gbọ ẹjọ aṣemáṣe tàwọn oṣiṣẹ SARS ba ṣe si arailu.Imoran yi jẹ atẹwọgba lọdọ ìjọba apapọ koda awọn ipinlẹ kookan nilẹ kaarọ o jiire bi Eko ti gbe igbimọ yi kalẹ.

Ninu awọn ti ko ti i ṣe bẹẹ ni ipinlẹ̀ Oyo ati Osun wa ti BBC Yoruba si gbiyanju lati mọ ohun to n dawọn duro ati bi wọn ti ṣe fẹ gbe gba.

Osun:

Agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Osun, Ismail Omipidan salaye pe erongba lati se agbekalẹ igbimọ yi ko jinna si ọkan Gomina Gboyega Oyetola to n tukọ ipinlẹ̀ Osun.

O ni koda Gomina Oyetola mẹnu ba ọrọ yi lọjọ ti awọn janduku ṣe ikọlu si ni Osogbo ati lọjọ keji ọjọ naa lasiko to n ba ara ilu sọrọ lori ẹrọ amóunmáwòrán.

"Laarin ọsẹ yi ni Gomina lawọn yoo kede agbekalẹ igbimọ yi. Ko ni pẹ ẹ mọ" lalaye to ṣe fun akọroyin wa.

Oyo:

Laipe ni ijọba ipinlẹ Oyo yoo gbe ti wọn jade naa ni esi ti agbẹnusọ Gomina Seyi Makinde,Taiwo Adisa fọ nigba ti BBC kan si lori ago.

O ni awọn ipinlẹ to ti ṣe bẹ ṣaaju kan gbe igbimọ kalẹ ni lai so ni koko ohun ti yoo jẹ ilana ti wọn yoo tẹlẹ.

"Oyo kọkọ fẹ gbe ilana kalẹ lori iru isori awọn ti o lẹtọ lati wa sọrọ nipa aṣemase SARS."

O salaye pe awọn ko ni fẹ gbe igbimọ kalẹ ti ko wa ni ṣi awọn eeyan ti yoo gbẹjọ wa ba wọn.

"A kọkọ gbọdọ ri pe awọn eeyan fi ẹjọ sun ki a to gbe igbimọ ti yoo gbẹjọ yi le'lẹ"

O ni lọdọ t'awọn ni Oyo "igbesẹ ni ṣiṣẹ n tẹle lawọn n gbe kii ṣe pe k'awọn maa fo ipele to kan lati bọ si omiran"

O ni awọn ko le sọ pe ọjọ bayi pato lawọn yoo ṣe agbekalẹ igbimọ ṣugbọn kọ ni pẹ t'awọn yoo fi ṣe.

Wo àwọn ìpínlẹ̀ tó ti gbé ìgbìmọ̀ olùwádìí SARS kalẹ̀ fún àwọn ará ìlú:

EndSARS panel update: Wo àwọn ìpínlẹ̀ tó ti gbé ìgbìmọ̀ olùwádìí SARS kalẹ̀ fún àwọn ará ìlú

Lẹyin ti ijọba apapọ paṣẹ fun awọn ijọba ipinlẹ lati gbe igbimọ ti yoo bojuto ẹka SARS to tuka, pupọ ninu awọn gomina lo ti gbe igbimọ naa kalẹ lawọn ipinlẹ wọn.

Lara ojuṣẹ igbimọ naa ni lati ṣe iwadii iwa ifiyajẹni lọna aitọ ti awọn oṣiṣẹ SARS naa wu, ati bi awọn ti ọrọ kan yoo ṣe ri idajọ ododo gba.

Lara awọn ipinlẹ to ti gbe igbimọ naa kalẹ ree:

Eko

Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa, odun 2020 ni gomina ipinlẹ Eko gbe igbimọ tirẹ kalẹ.

Sanwo-Olu ni igbimọ naa wa lati gba ẹri lọwọ ẹnikẹni tabi ẹbi wọn to ba iriri ifiyajẹni lọwọ ọlọpaa SAR.

Bakan naa lo tun gbe obitibiti owo kalẹ fun igbimọ naa lati fun gbogbo awọn ti ẹri wọn ba dantọ lori ẹjọ ti wọn ba fi kan agbofinro to ba tasẹ agẹrẹ.

Sanow-Olu ni igbimọ ọhun ni aṣẹ lati ke pe ẹnikẹni ninu awọn ti ọrọ naa kan.

Ogun

Lara awọn iṣẹ ti igbimọ ti ijọba ipinlẹ Ogun gbe kalẹ ni ṣiṣẹ iwadii iwa titẹ ẹtọ ara ilu loju mọlẹ ati ṣiṣẹ agbeyẹwo ẹri awọn ti ọrọ naa kan.

Bakan naa ni igbimọ ọhun yoo dabaa iye owo itanran to yẹ ki ijọba ṣan fun ẹnikẹni ti ẹri rẹ ba dantọ.

Lara awọn to wa ninu igbimọ naa ni ajafẹtọ ọmọniyan, awọn to ti fẹyinti nidii iṣẹ ọlọpaa, aṣoju awọn akẹkọọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ondo

Ninu atẹjade ti ijọba ipinlẹ Ondo fi lede, igbimọ naa ni oṣu mẹfa pere lati ṣiṣẹ, ko si fi esi iwadii rẹ ṣowọ si ijọba.

Ekiti

Ni ti ipinlẹ Ekiti, iṣẹ igbimọ naa ni lati gbọ ẹdun ọkan awọn eeyan ilu lori iwa ipa awọn ọlọpaa si awọn ara ilu.

Bakan naa ni igbimọ naa gbọdọ fi esi iwadii wọn sọwọ si ijọba laarin oṣu mẹfa si asiko yii.