You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
FG Covid Palliatives: Àjọ SERAP ń wá ìdájọ́ tó tọ́ lórí rògbòdìyàn jíjí ǹkan ìrànwọ́ Covid-19
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan kan ní Naijiria, SERAP ti ke si ajọ to n ri si ọrọ iwa ibajẹ ICPC lati tu iṣu de isalẹ koko gbogbo rogbodiyan to rọ mọ ẹsun pe ijọba kọ lati pin nkan iranwọ Covid-19 fawọn araalu.
Iroyin yii hande nigba ti fọnran kan bẹrẹ si ni tan kalẹ lori ayelujara bi awọn janduku kan ṣe n yabo awọn ile ti wọn n ko ẹru si jakejado orilẹede Naijiria.
Eyi lo mu ki ajọ SERAP lọjọ Aiku kọ iwe ipẹjọ si ajọ ICPC lati rii daju pe wọn tọpinpin awọn iṣẹlẹ yii ki wọn si fi ẹnikẹni ti igba rẹ ba ṣi mọ lori jofin ti wọn ba fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn kan n ko gbogbo nkan iranwọ to yẹ ki wọn pin lasiko Covid-19.
"O da bii wipe awọn alaṣẹ ni ki awọn eeyan kan jokoo sile ṣugbn wọn kọ lati pin nkan iranwọ lati mu asiko naa dẹrun fun awọn ti ko rọwọ họri lawujọ", SERAP kọ eyi sinu ipẹjọ wọn.
Lafikun, SERAP ni "Ẹsun pe wọn ko nkan iranwọ pamọ kaakiri ipinlẹ to fi mọ ikuna idọgba ninu pinpin awn nkan naa fawọn to ku diẹ kaato fun atawọn tiya n jẹ nilu ti di eyi ti wọn n fi ẹtọ wọn dun wọn to yẹ ki wọn ran wọn lọwọ".
Ó tó gẹ́ẹ́! Ẹ̀yin ọlọ́pàá, ẹ di ìhàmọ́ra kẹ́ẹ já àlàfíà ìlú gbà padà - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
Ọga agba awọn ọlọpaa ni Naijiria, Muhammed Adamu ti fohun silẹ pe ẹni to ba tasẹ agẹrẹ yoo lori aṣẹ tuntun to ṣẹṣẹ jade fun araalu yoo foju wina ofin.
Ọgbẹni Adamu lo paṣẹ fawọn ọlọpaa lati ko gbogbo irinṣẹ ti wọn nilo ati ikọ alaabo jọ lati lee dẹkun gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ jakejado orilẹede Naijiria.
Eyi n waye lẹyin bi jiji ẹru ẹlẹru ko ṣe n waye laipẹ yii ni lemo lemo ni Naijiria lara rẹ ni awọn nkan to yẹ ko jẹ awọn nkan irọrun fun pinpin lasiko Covid 19, awọn ọja nile itaja nla nla ati awọn nkan ini awọn eeyan jankan jankan lawujọ.
- Awọn jàndúkù yabo ilé Sẹ́nétọ̀ Teslim Folarin, wọ́n kó ẹ̀rọ ata, ọ̀kadà, fírìíjì àti àwọn nkan tí owó rẹ̀ tó N200m
- "Apena fẹ́gbẹ́ Oṣugbo, Opa, Akala àtẹ̀yin awo, ẹ wa ọ̀pá àṣẹ Ọ́ba Akiolu jáde"
- Èmi ṣì ni Jagaban, aṣíwájú Eko gangan, èmi ò lè sá kúrò l'Eko- Ahmed Tinubu
- Àwọn ọ̀nà láti dẹ́kun ìwọ́de ọ̀dọ́ lọ́jọ́ iwájú nìyí
- Èèyàn 229 ló ti wà ní gbaga òfin fún wàhálà tó wáyé l'Eko
Fun idi eyi, ọgbẹni Adamu paṣẹ pe ki awọn ọga ọlọpaa ko awọn ikọ́ wọn sita ki wọn ja alafia ilu gba pada lọwọ awọn ọdaran to n fi aṣọ oluwọde bora ti wọn si n da omi alafia ilu ru.
Ninu ọrọ ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, DCP Frank Mba fi sita, Ọga agba Adamu pa aṣẹ fun gbogbo awọn igbakeji rẹ, awọn kọmisọna ọlọpaa, awọn adari igun ọlọpaa kọọkan awọn ọgagun to moju to awọn bareke ni ipele ijọba ipinlẹ titi de ijọba apapọ, awọn ọlọ́paa MOPOL atawọn ikọ alaabo to ku lati tu sita fun iṣẹ yii.
O fi kun un wipe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ alaabo yii pata gba gbogbo igboro kan ki wọn si ri i daju pe alafia jọba lawọn ibi ti iṣẹlẹ idigunjale yii ti ṣọṣẹ.
Iléeṣẹ́ Ọmọogun ní òun yóò bẹ́ 'speaker' lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki ṣùgbọ́n...
Ileeṣẹ ọmọogun ti ṣalaye pe awọn ko tii ni ọrọ kankan lati sọ bayii, lori iṣẹlẹ to waye lagbegbe Lekki TollGate nilu Eko ni alẹ ọjọ Iṣẹgun.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lọjọbọ, alakoso eto iroyin lolu ileeṣẹ ọmọogun Naijiria, Ọgagun John Enenche ṣalaye pe, niwọn igba ti gomina ipinlẹ Eko ti gbe igbimọ oluwadi kalẹ, ọrọ yowu ti awọn ba sọ bayii, lee pagidina iṣẹ igbimọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìró ìbọn dún lákọ ní Iwo road n‘Ibadan, Seyi Makinde yọjú síbẹ̀
- "7000 Jàǹdùkú ló fọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Okitipupa, jó mọ́tò, tí wọn si se òṣìṣẹ́ léṣe"
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Wo díẹ̀ lára dúkìá tí jàǹdùkú sun níná l‘Eko torí ìwọ́de EndSARS
O ni ẹsun lasan ṣi ni awọn ọrọ to n kaakiri pe awọn ṣọja yinbọn pa awọn oluwọde kan, ati pe awọn akọṣẹmọṣẹ kan ti sọ pe, iroyin eke ni pe awọn ologun lo pa awọn to ku naa, kii ṣe ootọ.
O wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati fiye denu, ki wọn si ṣe suuru fun abajade iwadi lori iṣẹlẹ buruku naa.
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
Sanwo Olu búra fún ìgbìmọ̀ tí yóò má a ṣe ìdájọ́ àwọn ọlọ́pàá tó bá hùwà kò tọ́ sáwọn ará ìlú ní Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo Olu ti ṣagbekalẹ igbimọ ti yoo maa ri si idajọ awọn ti awọn agbofinro ba fiya jẹ ni ipinlẹ Eko.
Igbimọ yii ni Sanwo Olu gbekalẹ lẹyin ti ijọba Naijiria tu ikọ awọn olọpaa kogberegbe ka kaakiri Naijiria.
Ni ile ijọba ni Marina ni wọn ti ṣe ibura fun awọn ọmọ igbimọ naa.
Awọn naa ni: Adajọ Doris Okuwobi to je alaga ti wọn bura fun lẹyin eyi ti awọn ọmọ igbimọ naa kọja lọ si ile LASWA to wa ni Falomo ni Ikoyi.
Sanwo Olu ni ijọba oun setan lati yanju ọrọ ifiyajẹni to n fa iwọde kaakiri Naijiria lasiko yii.
O mẹnuba awọn iṣẹlẹ to ti ṣẹlẹ lati ọsẹ meji sẹyin pe nitootọ ni awọn ara ilu laṣẹ lati fi ẹhonu han si nkan ti ko ba tẹ wọn lọrun.
Gomina ni: Awọn ọdọ yii ti fi ohun marun un ti wọn fẹ ranṣẹ si ijọba, funra mi ni mo fi jiṣẹ fun aarẹ Buhari ni Abuja, Mo ti tu gbogbo awọn ti wọn mu satimọle nitori iwọde silẹ, mo ti ri owo igba milionu naira fun awọn opo ati ẹbi awọn ti wọn pa.
Bawo ni wọn yoo ṣe ṣiṣẹ:
Sanwo Olu ni oṣu mẹfa ni awọn igbimọ naa ni lati fi ṣiṣẹ.
Iṣẹ wọn ni lati ṣagbeyẹwo awọn ẹri ti awọn eeyan fi ranṣẹ ki wọn si ṣe ohun to yẹ lori ipaniyan lọna aitọ gbogob to ti waye sẹyin ni ipinlẹ Eko.
Wọn tun ni agbara lati fi ọrọ wa awọn oṣiṣẹ SARS ti ijọba apapọ ti tuka lẹnuwo lori awọn ẹsun naa ki wọn si yọ okodoro.
O ni abala ofin karun un ti Tribunal of Inquiry law lo fun wọn lagbara lati gbe abajade iwadii wọn sita pẹlu irufẹ idajọ iya to tọ si ẹni ti ade iwa ibajẹ ba ṣimọ lori.
Sanwo Olu ni ọrọ yii ko yọ awọn olọpaa ti wọn ti gba iṣẹ lọwọ wọn silẹ.
O gba wọn nimọran lati ṣiṣẹ laini ibẹru ẹnikẹni ati lai ṣegbe fun ẹnikẹni.
O tun ṣeleri atilẹyin ijọba fun awọn ọmọ igbimọ naa.
Adajọ Okuwobi to jẹ alaga igbimọ naa sọrọ lorukọ ijọba pe didun lọsan yoo sọ fun idajọ ododo lori awọn ti ọpọ n ṣe iwode nitori wọn.
Wo nọ́mbà tí o le è pè láti gba owó gbà-má-bínú tí ọlọ́pàá bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ l'Eko
Báyìí ni o ṣe leè fi ẹjọ́ ọlọ́pàá tó bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ sun ìjọba ìpínlẹ̀ Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti gbe igbimọ ẹlẹni meje kan kalẹ ti yoo maa ṣagbeyẹwo ẹsun fifi iya jẹ ara ilu lọna aitọ ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa n hu.
Bakan naa ni igbimọ ọhun yoo maa bojuto bi ijọba yoo ṣe maa san owo gba-ma-binu fun ẹnikẹni ti ọlọpaa ba fiya jẹ lọna aitọ ni ipinlẹ naa.
Sanwo-Olu lo kede igbeṣe yii lẹyin iwọde End SARS ti awọn eeyan gunlẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria, paapaa ni ipinlẹ Eko.
- "A ti já gbogbo ojú òpó ìjọba Nàìjíríà gbà lórí Twitter láti ṣàtìlẹyìn ìwọ́de End SARS" - Anonymous
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de End Sars
- Toyin Abraham tú àṣírí ohun tí ọlọ́pàá Náìjíríà sọ mọ́lẹ́bí rẹ̀ kan dà
Sanwo Olu ni awọn ara ilu le bẹrẹ si ni pe awọn nọmba wọnyi 0901 051 3203; 0901 0513204 ati 0901 051320 lati fi ọrọ awọn ọlọpaa to ba tasẹ agẹrẹ to ijọba leti.
Bo tilẹ jẹ pe nọmba naa ko wọle nigba ti a pe e, ṣugbọn Gomina Sanwo-Olu ti ni awọn eeyan le bẹrẹ si n pe awọn nọmba naa lati ọsẹ to n bọ.
Wo nọ́mbà tí o le è pè láti gba owó gbà-má-bínú tí ọlọ́pàá bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ l'Eko
Wo diẹ lara awọn eeyan to wa ninu igbimọ tuntun naa:
Doris Okuwobi
Wọn bi adajọ-fẹyinti Doris Okuwobi ni ipinlẹ Eko ni ọjọ Kẹwaa, oṣu kinni, ọdun 1955.
O kawe gboye gẹgẹ bi amofin ni ile ẹko awọn agbẹjọro to wa ni ipinlẹ Eko lọdun 1997.
Okuwobi ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun ko to fẹyinti ni ileeṣẹ to n ri si eto idajọ ti ipinlẹ Eko loṣu kinni, ọdun 2020, lẹyin to ti ṣiṣẹ fun ọdun mejilelogoji.
Doris Okuwobi ni alaga igbimọ naa.
Ebun Adegboruwa, SAN
Agbẹjọrọ agba ni Ebun Adegboruwa, ṣugbọn ko to de ipo naa, o ṣiṣẹ miran bii iṣẹ agegẹdu ni inu igbo ipinlẹ Ondo, Edo ati Delta.
O kẹkọọ jade nile iwe Obafemi Awolowo to wa ni ilu Ile Ife, nibi to ti darapọ mọ ẹgbẹ awọn to n ja fun ẹtọ awọn akẹkọọ.
Ko pẹ si akoko to wọm ile iwe naa ti wọn le oun atawọn eeyan mọkanlelọgọta miran kuro nile iwe naa lẹyin ti wọn dari ifẹhonuhan kan lọdun na lọhun, ki oloye Gani Fawehinmi to gba ẹjọ wọn ro.
Bakan naa ni wọn fi panpẹ ofin gbe laye ọgagun Sani Abacha to si lo oṣu mẹsan an latimọle ki wọn tu silẹ lẹyin iku ọgagun naa.
DIG Taiwo Lakanu
Wọn bi Taiwo Lakanu ni ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 1959 ni Lagos Island, ni ipinlẹ Eko.
O si kawe jade ni Fasiti ijọba apapọ to wa ni ilu Eko, UNILAG, ko to tẹsiwaju ni Leeds Metropolitan nilẹ Gẹẹsi.
Bakan naa lo tun kawe ni ile iwe eto abo to wa ni Jos, Abuja ati Accra, ni Ghana.
Lakanu ṣiṣẹ ọlọpa fun ọpọ ọdun ko to fẹyinti lọdun 2019.
Patience Udoh
Patience Udoh jẹ ọkan gboogi lara awọn obinrin akinkanju to n ja fun ẹtọ awọn eeyan ni ipinlẹ Eko.
Oun si ni ẹni ti yoo maa ṣoju awọn ara ilu ninu igbimọ ẹlẹni meje ọhun
Segun Awosanya
Ọkan gboogi lara awọn to n ṣagbatẹru iwọde End SARS ni Segun Awosanya jẹ.
Wọn bii ni ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun 1978 ni ipinlẹ Eko.
Awosanya wa lara awọn ti ijọba apapọ bẹ lọwẹ lati ṣatungbeyẹwo ikọ SARS ko to parada di FSARS.
- Gbọ́ ìtàn bí ikọ̀ SARS ṣe dà bó ṣe dà láti ẹnu Ọ̀gá ọlọ́pàá tó dá SARS sílẹ̀
- Ìjọba kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn àgùnbánirọ̀ sí ìpàgọ́ lẹ́yìn Covid 19- Sunday Dare
- #EndSARS: Àwọn olùwọ́de kọ etí ikún sí àṣẹ ijọba, wọ́n tẹ̀sìwájú ìwọ́de l'Abuja
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?
Olutoyin Odusanya
Agbẹjọro to dantọ ni iya afin Olutoyin Odusanya, o si tun jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA.
Lara awọn ibi ti Odusanya ti kawe ni Ilẹ Gẹẹsi, ilu Abeokuta ati ipinlẹ Eko.
Odusanya gboye gẹgẹ bi agbẹjọro ni Naijiria lọdun 1990 ko to kawe siwaju sii.
Lọwọ yii, oun ni oludari ileeṣẹ Citizens Mediation Centre to maa n pẹtu si aawọ laarin awọn ara ilu, o tun jẹ ọkna lara awọn ọmọ ẹgbẹ Human Rights Commision, to maa n ja fun ẹtọ ara ilu.
- Mo kọ̀ láti kópa nínú ìpàdé orí ayélujára Nàìjíríà yìí- Falz
- Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram
- Ẹ ṣọ́ra ní òpópónà AIT, ọkọ̀ agbépo kan ti yí dánù lọ́nà agbègbè Alagbado
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Ìjọba Nàìjíríà ti gbà láti san N30b owó àjẹmọ́nú fún ASUU
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn