NYSC Camp, After coronavirus: Ìjọba kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn àgùnbánirọ̀ sí ìpàgọ́ lẹ́yìn Covid 19- Minista ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

NYSC: Adupẹ! Ètò àgùnbánirọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ padà jakejado Nàìjíríà

Ijọba apapọ Naijiria ti kéde pe ki wọn ṣí gbogbo Ibudo akojọ eto agunbanirọ pada keto gbogbo si maa waye nibẹ.

Iroyin ayọ yi ni Minisita idagbasoke ọrọ ọdọ Naijiria Sunday Dare fi sita loju opo Twitter rẹ lỌjọbọ to si ni eto agunbanirọ yoo gberasọ lọjọ Kewaa, oṣu Kọkanla.

Ọgbẹni Dare fi kun ọrọ rẹ pe ijọba yoo ri wi pe gbogbo ilana idaabobo Covid-19 ni wọn tẹle lawọn ibudo yi.

Báyìí lo ṣe salaye ọrọ naa loju opo Twitter rẹ pe ijọba yoo pese ohun gbogbo ti wọn nilo lati tẹlẹ aṣẹ igbogunti itankalẹ ajakalẹ arun Covid 19.

O ni: "Wọn ti buwọlu aṣẹ pe ki wọn ṣí gbogbo ibudo akojọ agunbanirọ to jẹ ibi ipagọ fawọn ti yoo kopa ninu eto naa lasiko yii.

Eto naa yoo si bẹrẹ ni ọjọ kẹwaa, oṣu Kokanla. ọdun 2020.

A o si tẹle gbogbo ilana Covid-19"

Saaju ni ijọba apapọ ti sọ agadagodo si gbogbo aaye akojọ NYSC jakejado Naijiria nitori ajakalẹ Covid-19.