End SARS protest today: Ṣé òótọ́ ni pé Anonymous ti já gbogbo ojú òpó ìjọba Nàìjíríà gbà lórí Twitter?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Awọn agbọnaẹburuwọle si ori itakun agbaye, Anonymous, ti kede pe wọn ti ja gbogbo itakun ayelujara ijọba Naijiria gba ni atilẹyin fun iwọde End SARS to n lọ lọwọ.

Anonymous lo kede bẹẹ lẹyin to ja oju opo Twitter ti ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ igbohunsafẹfẹ, NBC, gba ni afẹmọju ọjọ Ẹti.

Lẹyin naa ni wọn kọ akọle kan pe "Awa Anonymous ti ja gbogbo itakun Twitter ijọba Naijiria gba lati ṣatilẹyin fun ifẹhonuhan End SARS."

Awọn ẹruku naa tun bere lọwọ awọn to wa loju opo NBC ọhun irufẹ oju opo ileeṣẹ ijọba apapọ ti wọn n fẹ ki awọn tun ja gba.

Ṣugbọn nigba ti ileeṣẹ iroyin BBC ṣe abẹwo si ọpọ ninu oju opo ti ijọba apapọ n ṣakoso rẹ, a rii pe digbi ni wọn ṣi wa.

O ti to nnkan bi ọjọ mẹwaa ti awọn ọdọ naijiria ti gunlẹ iwọde End SARS, ti wọn si bere fun atunto si ileeṣẹ ọlọpaa, ati opin si ẹka rẹ to n gbogun ti iwa idigunjale, SARS.