EndSARS Protest: Àwọn olùwọ́de Endsars ló já sọ́ọ̀bù kìí ṣe torí ebi - Femi Adesina

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Agbẹnusọ ààrẹ Muhammadu Buhari lórí ìròyìn àti ìpolongo, Femi Adesina ni kìí ṣe ebi tàbi òsì ló mú ki àwọn ènìyàn maa já ilé, já sọ́ọ̀bù tàbi bá ǹkan jẹ́ bí kò ṣe ìfẹ̀hónúhàn #EndSars.

Adesina sọ ọrọ náà lásìkò tó ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ni orí móhùmáwòràn kan pé, kí a maa lọ ẹbi àti ìyà mọ bí wọ́n ṣe ń já sọ́ọ̀bù, dàbí ẹni pé ènìkàn sọ pé ìwà adigunjalè dára ni.

Gẹ́gẹ́ bi o ṣe sọ ọ́ " Ìwà ọ̀daràn ni ọ̀daràn ń jẹ́, ṣe a lé sọ pé ǹkan tó dára ni adigunjale ṣe, nítori pé ó tòsì tàbi kò lówó?

"Tí a ko ba ti lé foriji ẹnii to gbé ìbọ̀n lọ jalè nítorí kò lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni a ò le fọwọ́ ra awọn to já sọ́ọ̀bù lóri.

Agbẹnusọ ààrẹ náà sàlàyé pé, nítori pé ìwọ́de náà ti pẹ́ ju bi o ṣe yẹ lọ ló mú kí ààyè gba àwọn tó ṣe aburu náà.

Ó ní tí wọn ò bá jó àgọ́ ọlapàá ni, ètò ààbò kò ni dojúbolẹ̀, àwọn ọ̀daran kò sì ni rí iṣẹ́ ṣe.

Adesina ni, bí wọ́n ṣe n sọ pé, orílẹ̀-pedpe Nàìjíríà ni olú-ilú àwọn òtòsì lágbàyé, kìí ṣe orí ìjọba yii ni òṣì náà ti bẹ̀rẹ̀, bí kìí ṣe bi àwọn adarí ti ṣe ṣe owó ìlú mákumaku láti ààdọ́ta ọdún sẹ́yìn, kìí ṣì ṣe ǹkan ti ìjọba tọ n bẹ lóde le ṣe láàrin ọdun méjì

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ni àwọn ìgbẹ́sẹ̀ ààrẹ Buhari yóò mú ènìyàn ọgọ́rùn mílíọ̀nù kúrò nínú òṣì ni ọdún mẹ́wàá síbí.

NUJ ní báwọn ọlọ́pàá ṣe ń ti akọ̀ròyìn mọ́lé láìtọ́ sàfihàn ìwà taniómúni wọn

Ẹgbẹ awọn akọroyin nilẹ wa, NUJ, ti kesi aarẹ Muhammadu Buhari lati ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ nipa iwọde EndSARS to n lọ lọwọ.

Atẹjade kan ti olu ile ẹgbẹ akọroyin nilu Abuja fisita, ti akọwe apapọ ẹgbẹ, Shuaib Usma Leman fọwọsi, ni ọrọ yii ti jẹyọ.

Ẹgbẹ NUJ ni ẹnu n ya oun nipa bi aarẹ Buhari se dakẹ lai fọhun lori iwọde EndSARS to n lọ lọwọ, eyi to ti da omi alaafia orilẹede yii ru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni NUJ tun kesi ọga agba ọlọpaa pata loriẹede yii lati fopin sawọn iwa ifiyajẹni ti wọn n se sawọn akọroyin.

O wa beere pe ki wọn tu akọroyin kan, Tom Oga Uhia, tii se oludasilẹ iwe iroyin Power Steering Magazine to wa lahamọ silẹ.

Atẹjade naa ni o ti to ọsẹ kan nayii ti wọn ti fi Tom sahamọ pẹlu asẹ minisita keji feto ohun amusagbara, Godwin Jeddy Agba, lori ẹsun pe o ba oun lorukọ jẹ.

NUJ ni niwọn igba ti awọn ọlọpaa ko ti lee gbe Tom lọ sile ẹjọ lati igba naa, bi wọn se fi si ahamọ tubọ tu asiri iwa tani yoo mu mi tawọn ọlọpaa n hu.

Atẹjade yii ni oun gba pe wọn ko tii gbe awọn igbesẹ ti yoo wa ojutu sawọn ohun to n fa ẹhonu awọn oluwọde.

Bakan naa lo kesi aarẹ Muhammadu Buhari lati jade wa bawọn ọmọ Naijiria sọrọ, ko si sọ awọn ọna ti yoo gba wa ojutu sawọn ẹhonu oluwọde.

Atẹjade NUJ wa n beere pe se aarẹ Buhari ti padanu ohun rẹ ni, tori awọn ọmọ Naijiria n reti ọrọ rẹ nibayi ti Naijiria joko le agba ẹtu, to lee bu nigbakugbaa.

Ọ̀pọ̀ aráàlú ló ti pàdánù ọwọ́ àti ẹsẹ wọn sọ́wọ́ jàǹdùkú - Sanwo-Olu

Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ti kede isede konile o gbele nipinlẹ́ Eko.

Atẹjade kan ti gomina Sanwo-Olu fisita salaye pe alase yipo ni isede naa, ti yoo gba gbogbo ọjọ.

Ijọba gbe igbesẹ naa nitori rogbodiyan to bẹ silẹ laarin ifẹhọnuhan EndSars.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ lori iwọde EndSARS to n lọ lọwọ naa, gomina ipinlẹ Eko ni pẹlu iyalẹnu ni oun fi n tọpinpin bi iwọde naa, to bẹrẹ ni alaafia se wa di eyi to n dunkoko mọ awọn araalu ati igbayegbadun awujọ.

Ọpọ eeyan lo ti padanu ọwọ ati ẹsẹ wọn sọwọ awọn janduku naa, ti wọn sapamọ sabẹ awọn oluwọde yii, ti wọn si n da omi alaafia ipinlẹ naa ru.

O ni gẹgẹ bii ijọba to mọ ohun to n se, to si mu iwọde EndSARS lọkunkundun, a ko ni fọwọ lẹran, ki ilu dojuru mọ wa lọwọ.

"Nitori idi eyi, mo ti wa kede isede oni wakati mẹrinlelogun yika gbogbo ipinlẹ Eko, bẹrẹ lati aago mẹrin irọlẹ oni.

Ko gbọdọ si lilọ bibọ ọkọ ati ero kankan ni gbogbo awọn agbegbe to wa nipinlẹ Eko yatọ si awọn onisẹ kose maase nikan."

Àlàyé rèé lórí ìdí táwọn jàǹdùkú fi dáná ṣun àgọ́ ọlọ́pàá ní Iganmu

Iwọde EndSARS to n lọ lọwọ yika Naijiria tun ti gba ọna miran yọ ni agbegbe Apapa Iganmu nipinlẹ Eko.

Idi ni pe awọn janduku to ti ja iwọde naa gba, ti dana sun agọ ọlọpaa to wa lagbegbe yii ni deede aago mẹwa ku isẹju mẹẹdogun laarọ yii.

Koda, iroyin kan ti ko tii fidi mulẹ ni awọn ọlọpaa lo yinbọn mọ awọn janduku naa, eyi to mu ki wọn dana sun agọ ọlọpaa ibẹ.

Lọwọ lọwọ bayii, iwọde naa si n tẹ siwaju nilu Eko, tawọn oluwọde si ti di awọn opopona nlanla to wa nilu naa.

Nigba ta kan sileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lori isẹlẹ yii, alukoro fun ileesẹ ọlọpaa naa, Muyiwa Adejobi salaye pe, ileesẹ ọlọpa yoo fi ikede sita laipẹ.

O ni ikede yii ni yoo sọrọ lẹkunrẹrẹ nipa bi isẹlẹ naa se waye.

Ìwọ́de EndSARS ti yíwọ́ pátápátá ní Ondo - Ọlọ́pàá

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ni igboro ilu Akure ti daru nitori iwọde EndSARS to gbode.

A gbọ pe awọn oluwọde naa n jo sọọbu, taya, ti wọn si di gbogbo ọna gboogi nilu Akure pa.

Koda, se ni awọ̀n eeyan to jade laarọ oni n sa kijokijo kiri lati sa asala fun ẹmi wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ti fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba salaye pe, ilu Akure n gbona giri laarọ oni nitori awọn oluwọpde End SARS tó dí gbogbo oju ọna.

Ikoro lọ sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.

O ni "O ni ootọ ni pe igboro ti daru ni ilu Akure lẹyin ti awọn janduku to darapọ mọ awọn oluwọde End SARS, di gbogbo oju ọna to yẹ ki awọn eeyan gba pa."

Ikoro fi kun pe gbogbo awọn ọna to ṣe pataki ni ilu naa ni awọn oluwọde naa di ti, wọn ko si jẹ ki awọn to nibi re ri ọna kọja.

O ṣalaye pe iwọde ọhun n lọ ni ẹrọ pẹlẹ ṣaaju akoko yii ni ipinlẹ Ondo, ṣugbọn o dabi pe nnkan ti n yiwọ bayii.

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko le fi idi rẹ mulẹ pe awọn oluwọde naa n jo ṣoọbu lagbegbe Arakalẹ ni Akure, ṣugbọn ori alupupou ni oun wa, ti oun si n kaakiri ilu naa lati woye bi ohun gbogbo ṣe n lọ.

Ikoro pari ọrọ rẹ pe, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ ipade pẹlu awọn ẹlẹkajẹka lọna ati wa ojutu si rogbodiyan naa to n rugbo bọ.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn olugbe ilu Akure, Oluwatosin Oladapo sọ fun BBC Yoruba pe "Gbogbo ibi ni awọn oluwọde naa ti di bayii, koda wọn n jo taya lagbegbe Old Garage, awọn eeyan ko si ri ọna kọja."

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.