You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS: Olórí ilé aṣofín-ṣòfin ní ìṣúnà 2020 gbọdọ̀ pèsè owó fún ASUU bí bẹ́ẹ́kọ̀...
Olori ile asoju-sofin nilẹ wa, Femi Gbajabiamila ti sọrọ nipa awọn isẹlẹ to se koko to n waye nilẹ wa, paapaa iwọde EndSARS.
Gbajabiamila, ẹni to sọrọ yii ninu akanse ọrọ to bawọn araalu atawọn asoju-sofin sọ nibi ijoko ile asoju-sofin to waye lọjọ Isegun, wa kede awọn igbesẹ to fẹ gbe loti yanju awọn isẹlẹ naa.
Gbajabiamila ni lakọkọ, oun ko ni buwọ lu eto isuna ọdun 2020 lai jẹ pe o pese owo iranwọ fawọn mọlẹbi awọn eeyan to jalaisi lasiko iwọde naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ẹ ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ ní Oko àti Benin padà"
- Ìwọ́de EndSARS ló ń sọ pé inú ń bí àwọn ọ̀dọ́, ìjọba, ẹ náání wọn - Obasanjo
- Ẹni iyì àti akíkanjú tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé làwọn èèyàn Akure, ilú ìyá mi - Seyi Makinde
- Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ti rí èrè ìwọ̀de yín lórí EndSARS àmọ́ ẹ ṣọ́ra, kẹ má baà sọ èrè náá nù - Tinubu
- Owó ìrànwọ́ Covid-19 dé, ìjọba fẹ́ san ₦75bn fún 54,000 olókoòwò
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti iléèwé pa nítorí ìwọ́de #EndSARS
- Ìrẹ̀wẹ̀sì ń bá wa torí ìdánwò NECO tẹ ń ṣún síwájú lọ́pọ̀ ìgbà - Akẹ́kọ̀ọ́, ọ̀gá iléèwé
- Agbára ìgbìmọ̀ ìdájọ tí mo gbé kàlẹ̀ yóò dé ọ̀dọ̀ àwón ólọ́pàá tó ti kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́lẹ̀- Sanwo Olu
- Wo àwọn orílẹ̀èdè míràn tó ń fojú winá ìwọ́de bíi ti ENDSARS
Bakan naa lo ni oun ko ni buwọlu eto isuna ọhun, ti ko ba pese owona fun ẹgbẹ ASUU lati wa idahun si ohun ti wọn n beere fun.
Olori ile asoju-sofin ni ile asofin naa yoo tun ri daju pe ijọba gbe igbesẹ lati se atunse ati atunto awọn ileeẹkọ giga gbogbo nilẹ wa, ti yoo fi ba ode oni mu.
O ni oun ko ni buwọlu eto isuna naa, ti ko ba ya owo nla sọtọ lati se atunse awọn ileẹkọ giga wa.
Ko tan sibẹ, Gbajabiamila tun ni oun yoo ri daju pe oun kan sawọn mọlẹbi awọn eeyan to padanu ẹbi wsn lasiko iwọde EndSARS yii, lati tu wọn ninu.
O fikun pe, Ile asofin yoo tun saayan lati ri daju pe aba ofin to n se atunto si eto idibo nilẹ wa dohun, lọna ti pese idibo to mọyan lori ni Naijiria.
Olori ile asoju-sofin tun fọwọ gbaya pe atunse ofin ilẹ wa yoo waye, eyi ti yoo mu ko dangajia lati fidi ẹtọ ọmọniyan mulẹ.
Bakan naa lo ni ile asofin yoo sisẹ lori ọna tawọn ẹkun kọọkan yoo fi maa se akoso awọn ohun alumọọni to wa ni ẹkun wọn, gẹgẹ bawọn ọmọ ilẹ yii ti n fẹ.
Gbajabiamila wa koro oju si iwa ta ni yoo mu mi tawọn ọlọpaa n hu, to si ni wọn ko ga ju ofin lọ lọna kọna, eyi to ba si tapa si ofin, lo yẹ ki ọbẹ ofin ba.