You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Ìpínlẹ̀ méjìlá tó wà ní ìṣọ̀rí àkọ́kọ́ ní yóò gba owó ìrànwọ́ lọ́sẹ̀ yìí
Lati ibẹrẹ ọsẹ yii lọ, ijọba apapọ yoo bẹrẹ si san owo iranwọ pẹ pẹ pẹ fawọn olokoowo ke ke ke ati alabọde.
Awọn eeyan yii ni wọn ti yege lati kopa ninu eto iranwọ arun Coronavirus ti apapọ owo rẹ to biliọnu marundinlọgọrin naira.
Ọjọ Kẹwaa osu Kẹsan ọdun 2020 si ni ijọba apapọ sefilọlẹ eto mejeeji naa, labẹ ileesẹ to wa fun ifẹsẹmulẹ ọrọ aje nilẹ Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti iléèwé pa nítorí ìwọ́de #EndSARS
- Ìrẹ̀wẹ̀sì ń bá wa torí ìdánwò NECO tẹ ń ṣún síwájú lọ́pọ̀ ìgbà - Akẹ́kọ̀ọ́, ọ̀gá iléèwé
- Agbára ìgbìmọ̀ ìdájọ tí mo gbé kàlẹ̀ yóò dé ọ̀dọ̀ àwón ólọ́pàá tó ti kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́lẹ̀- Sanwo Olu
- Wo àwọn orílẹ̀èdè míràn tó ń fojú winá ìwọ́de bíi ti ENDSARS
- Mo fura pé ẹ fẹ́ da Nàíjíríà rú, ń kò ṣe ìwọ́de mọ́ - Segalink, agbátẹrù ìwọ́de yọwọ́
- SERAP pe Buhari, igbákejì rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí àfikún owó iná àti epo bẹntiró
Awọn olokoowo ke ke ke ati alabọde to to miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin si ni yoo jẹ anfaani eto naa.
Amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori okoowo alabọde pẹlu ọọfisi igbakeji aarẹ ati alakoso eto naa, Tola Adekunle sọ fawọn akọroyin nilu Abuja pe eto sisan owo naa yoo bẹrẹ lọsẹ yii.
Adekunle ni isọri isọri lawọ n se eto pinpin owoya naa, ti ipinlẹ mejila si wa labẹ isọri kan, eyi ti yoo jẹ ko rọrun lati tọpinpin eto naa.
"Lọwọ lọwọ bayii, ipinlẹ mejila ti setan lati gba owoya naa, a si lero pe ki ọsẹ yii to pari, a san owo naa fun wọn.
Ori awọn onisẹ ọwọ lati ti kọkọ bẹrẹ, eeyan ẹgbẹrun mẹrin ati aabọ si ni yoo jẹ anfaani owo iranwọ naa nipinlẹ kọọkan.
Bakan naa ni awakọ ero ẹgbẹrun mẹrin ati aabọ yoo jẹ anfaani rẹ, eyi ti yoo mu ki apapọ akopa nipinlẹ kan jẹ ẹgbẹrun mẹsan.
Gbogbo apapọ awọn eeyan ti yoo jẹ anfaani eto naa ni isọri akọkọ, tii se ipinlẹ mejila si jẹ ẹgbẹrun lọna mẹrinlelaadọta."