Kogi Commissioner: Àlàyé rèé bí Kọmíṣọ́nnà ìlera Kogi ṣe bù sẹkùn lórí amóhùnmáwòrán

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ọmọ Naijiria ti gba oju opo ayelujara lati tun da si ọrọ kan to n ja wititi lọkan awọn eeyan.

Iṣẹlẹ yi ni ṣe pẹlu Kọmisana eto ilera ipinlẹ Kogi to ṣaadede bu sẹkun lasiko to n ṣe ayẹwo bi awọn janduku ṣe ba ẹrọ ayẹwo olowo iyebiye jẹ nile iwosan Kogi.

Fọnran fidio yi to gbode kan loju opo ayelujara ti ileeṣẹ iroyin Channels TV gbe sita ṣafihan Dokita Saka Haruna to bu sẹkun nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ.

Ohun ati awọn akẹgbẹ rẹ kan ni wọn kọwọrin ṣayẹwo si ile ikẹru irinṣẹ ilera pamọ si ni Lokoja.

Ninu fọnran ọhun, a ri i bi awọn janduku ṣe ba nkan jẹ lorisirisi.

Ninu ọrọ to sọ lẹyin ti wọn kaakiri wo nkan to bajẹ, arakunrin Saka ni yoo nira fun ipinlẹ Kogi lati pada bọ sipo latari ijamba ti awọn janduku yi ṣe. Lo ba kan sẹkun.

Awọn oloṣelu Naijiria ati Awada Kẹrikẹri

Kete ti fọnran fidio Kọmisana yi lu oju ayelujara lawọn eeyan ti bẹrẹ si ni bu ẹnu atẹ lu u pe ẹkun eke lo n sun.

Iṣẹlẹ ẹkun sisun tabi wiwu iwa ti yoo mu ki ara ilu kaanu wọn paapa lati ọwọ awọn oloṣelu tabi awọn to dipo mu kii ṣe tuntun ni Naijiria.

Ẹkun sisun Kọmisana yi si ti wa mu kawọn eeyan maa darukọ awọn to jẹ gbajumọ ẹlẹkun ori amohunmaworan mii laipẹ yi bi:

  • Gomina Ben Ayade ipinlẹ Cross River
  • Sẹnatọ Dino Melaye Kogi
  • Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ekiti Ayodele Fayose ati
  • Iyawo aarẹ tẹlẹ Dame Patience Jonathan.

Bo tilẹ jẹ wipe a ko le sọ boya lootọ lọrọ dun wọn ti wọn fi bu sẹkun, awọn araalu ko foju rere wo iwa yi.

Lọdọ ọpọ eeyan, oju awada ni wọn fi n wo awọn to ba hu iru iwa yi niwaju kamẹra tabi lasiko ipolongo.