How to apply for Nigeria Youth Investment Fund: Wo ibi láti mọ̀ síi nípa àwọn ọ̀dọ́ tó máa ri owó náà gbà

Banki apapọ Naijiria ti a mọ si Central Bank ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori irufẹ awọn to maa ri gba ninu owo iranwọ ti o jade yii.

Wọn ni owo naa wa fun awọn ọdọ to nilo iranlọwọ ṣugbọn ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mejidinlogun si ọdun marundinlogoji lọ.

Awọn to lẹtọ si owo iranwọ N75 biliọna naa lasiko yii ni awọn ti iṣẹ wọn nii ṣe pẹlu:

- Awọn agbẹ olohun ọsin ati oko ounjẹ

- Awọn ti iṣẹ wọn nii sẹ pẹlu imọ ẹrọ ati tikinọlọji

Wọn ni awọn ti iṣẹ wọn ni i ṣe pẹlu irin ajo afẹ, ile kikọ, ati eto ilera laiyọ karakata silẹ.

Wọn ni ki awọn eeyan to ku lọ ni suuru nitori pe eto naa maa kari gbogbo awọn to ba nifẹ sii laipẹ.

Erongba ijọba ni lati yanju iṣẹ to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta laarin ọdun 2020 si ọdun 2023.

Bakan naa ni wọn salaye pe awọn ẹgbẹ alajẹṣẹku ti wọn forukọ silẹ pẹlu ijọba to jẹ ti awọn ọdọ naa yoo jẹ ninu anfani yii.

Awọn ẹnikọókan to forukọ silẹ naa yoo jẹ ninu anfani ọhun.

Wo bí o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ láti gbà nínú N75b tí ìjọba fẹ́ ẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ láti dá iṣẹ́ sílẹ̀

Ìjọba ti ṣí ojú òpó fún àwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ ẹ dá iṣẹ́ sílẹ̀

Ijọba Naijiria ti ṣi oju opo ayelujara silẹ fun awọn ọdọ orilẹ-ede naa lati fi orukọ silẹ fun owo iranwọ.

Owo naa ni wọn pe ni Nigeria Youth Investment Fund (NYIF).

Owo naa to jẹ biliọnu marundinlọgọrin lowa fun awọn ọdọ to ba fẹ ẹ da iṣẹ ti ara wọn silẹ.

Ileeṣẹ ijọba fun awọn ọdọ ati idagbasoke ere idaraya,lo ṣe agbatẹru eto yii, pẹlu ajọṣepọ banki apapọ, to gbe owo silẹ.

Awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn si wa laarin ọdun mejidinlogun si marundinlogoji, to ni erongba okoowo ti wọn fẹ ẹ ṣe ni eto naa wa fun.

Ẹnikọọkan wọn sile kọwe beere fun owo to to ẹgbẹrun lọna ọtalerugba din mẹwaa (250,000) si miliọnu marun-un Naira.

Lati fi orukọ silẹ, ẹ lọ si oju opo ayelujara nyif.nmfb.com.ng fun ẹkunrẹrẹ.

Wo bi wa a ṣe fi orukọ silẹ

Lọ si oju opo ayelujara nyif.nmfb.com.ng

  • Tẹ bọtinni ti wọn kọ 'apply here' si, ni oju ewe to ba kọkọ ṣi
  • Fi orukọ rẹ silẹ, pẹlu nọmba BVN rẹ, si aaye to yẹ
  • Lẹyin naa ni ki o kọ akọsilẹ nipa ọjọ ori rẹ, nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ, adirẹsi rẹ, ipinlẹ ti o ti wa, ati imeeli rẹ, pẹlu awọn nkan miran.
  • Yoo gbe ọ lọ si oju ewe to kan lati sọ nipa iwe ẹri ileewe ti o wa lọwọ rẹ.
  • Abala to kẹhin ni wa a ti yan ibudo ti o ti fẹ ẹ gba idanilẹkọ rẹ.

Fi si ọkan pe ọfẹ ni iforukọ silẹ ati idanilẹkọ

Ori ayelujara ni idanilẹkọ naa yoo ti waye fun ọjọ marun-un gbako.