Ìjọba tún ti wọ́gilé ètò yíyan Awujale ilẹ̀ Ijebu tuntun, ìdí rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Ijebu Ode ní ìpínlẹ̀ Ogun, Dare Alebiosu ti darí àwọn afọbajẹ Awujale ilẹ̀ Ijebu àti ìdílé Fusengbuwa láti ṣe ìdádúró ètò yíyan Awujalẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́.

Alága náà ní ìdarí yìí ló ń wáyé nítorí onírúurú ẹ̀sùn tí àwọn ti wọ́n ti kọ ránṣẹ́ sáwọn, tó fi mọ́ ẹ̀sùn pé àwọn aṣemáṣe kan ń wáyé lórí ètò yíyan Awujale náà.

Ó sọ pé àwọn èèyàn ń fẹ̀sùn kàn pé níṣe ni àwọn kan ń gbìyànjú láti fi ọ̀nà èbùrú wá oyè náà, tí ìgbésẹ̀ yíyan ọba náà sì ti ń ní ọwọ́ kan ìkà nínú.

Nínú lẹ́tà kan tí alága náà kọ ránṣẹ́ sáwọn afọbajẹ Awujale ilẹ̀ Ijebu ní Ogúnjọ́, oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni wọ́n ti kéde ìdarí náà.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú lẹ́tà náà ṣe sọ, ìjọba gbé ìgbésẹ̀ náà lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wò òfin tó de ọ̀rọ̀ oyè jíjẹ ní ìpínlẹ̀ Ogun tọdún 2021 ìyẹn Obas and Chiefs Law of Ogun State, 2021.

Wọ́n ní òfin fi ààyè gba ìjọba láti ṣe ìdádúró ètò yíyan ọba tàbí ọmọ oyè kan tí wọ́n bá ri pé ìgbésẹ̀ náà le da omi àlááfíà ìlú rú.

Ó fi kun pé àwọn ìròyìn tó tẹ àwọn lọ́wọ́ ló jẹ́ káwọn tètè gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe ìdádúró ètò yíyan Awujale náà nítorí àti dènà àwọn ìwà èyí tó le dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìlú, tí àwọn sì nílò láti dá ààbò bo oyè ilẹ̀ Ijebu.

Alága náà wá rọ àwọn afọbajẹ láti ṣe ìdádúró ètò yíyan Awujale náà títí tí wọ́n fi máa gbọ́ látọ̀dọ̀ ìjọba kí wọ́n tó tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò náà.

Ṣùgbọ́n lẹ́tà náà kò sọ pàtó ohun tó wà nínú ìwé ẹ̀sùn àtàwọn tó kọ̀wé ẹ̀sùn náà tó jẹ́ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ náà.

Ṣáájú ni onírúurú awuyewuye ti ń wáyé lórí ètò yíyan Awujalẹ̀ náà kó tó di pé wọ́n kọ́kọ́ wọ́gilé ìgbésẹ̀ náà.

Lẹ́yìn náà ni ìjọba ìbílẹ̀ Ijebu Ode kéde nínú lẹ́tà kan tí wọ́n kọ ránṣẹ́ sí ìdílé Fusengbuwa lọ́jọ́ Kẹfà, oṣù Kìíní, ọdún 2026 pé àwọn afọbajẹ tún le bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ náà padà.

Lẹ́tà ọ̀hún sọ pé àwọn ìdílé náà ní ọjọ́ mẹ́rìnlá lẹ́yìn tí wọ́n gba lẹ́tà náà láti fi gbé ìgbésẹ̀, kí wọ́n sì fi ọjọ́, àkókò àti gbàgede tí ètò fífa ọmọ oyè kalẹ̀ náà yóò ti wáyé tó ìjọba ìbílẹ̀ náà létí.

Lẹ́yìn náà ni ìdílé Fusengbuwa nínú àtẹ̀jáde kan tó tẹ BBC News Yorùbá lọ́wọ́ ní àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yan ọmọ oyè ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kìíní, ọdún 2026.

Wọ́n ní ibi ìpàdé náà ni àwọn ti máa yan ọmọ oyè tí àwọn sì máa forúkọ rẹ̀ ránṣẹ́ sáwọn afọbajẹ.