You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí nìdí tí oríṣiríṣi oúnjẹ máa ń wu aláboyún jẹ: ojúkòkòrò ni tàbí àtẹnujẹ? Àlàyé rèé
Lasiko iloyun, ọpọ ayipada lo maa n de ba ara obinrin. lara rẹ si ni ki oniruuru ounjẹ ati oun ti ko ṣee jẹ maa wu obinrin to loyun bẹẹ lati jẹ.
Kii ṣe gbogbo obinrin lo maa n ni iriri yii lasiko iloyun, amọ awọn miran a maa ni i. Koda awọn obinrin miran wa to jẹ wi pe lasiko iloyun, ounjẹ ti wọn kii fẹ lati jẹ nigba ti wọn ko loyun, ni yoo wa maa wu wọ̀n lati jẹ lọpọlọpọ igba.
Dokita Samuel Faturoti to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe nnkan aramanda lawọn obinrin miran tilẹ maa n fẹ́ jẹ lasiko ti wọn b awa ninu oyun.
Dokita Faturoti ṣalaye pe awọn obinrin miran maa n fẹ jẹ awọn nnkan bii eedu, ṣọọki ati bẹẹbẹẹlọ lasiko ti wọn b awa ninu oyun.