You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
N kò pe Olokuku ní Baálẹ̀, mo máa fi kélé òfin gbé ẹnì tó purọ́ mọ́ mi lójú òpó Facebook - Oluwo ilẹ̀ Iwo
Oluwo ti ilu Iwo, Oba Adewale Akanbi, ti halẹ lati fi ọwọ ofin olumulo Facebook kan, lori ẹsun eke ati ibanilorukọ jẹ.
Oba naa, ninu atejade kan ti akowe iroyin re, Alli Ibrahim gbe sita, ṣalaye pe, ọkunrin kan, Simeon Abiodun, olupolowo oju opo Facebook kan, Ogbeni Funshy, ni wọn ti fi ẹjọ wọn awon osise eleto aabo fun itankale iro, eyi to ta tako ori ade naa.
Gege bii o ṣe wan ninu atẹjade naa, Funshy ni won ri ninu fidio Facebook kan to sọ wipe Oluwo n pe Oba Olokuku ni Baale.
"Fidio yii kii ṣe ṣinilọna nikan ṣugbọn o tun gbiyanju lati da alaafia ru laari nori ade mejeeji," alaye naa ṣe akiyesi.
Oluwo fi kun, "Mo ni ireti ti o lagbara ninu ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ati ẹka idajọ lati ṣewadii, ṣafihan otitọ ati ririi daju pe awọn igbese ti o yẹ.
"Ko si bi ti mo ti pe Olokuku ni Baale."
Lọdun to kọja ni Iyawo tẹlẹ fun Oluwo ti ilẹ Iwo, Olori Chanel Chin fun kan Oluwo bakan pe ko tọju ọmọ to wa laaarin wọn.
Ninu atẹjade ti Olori naa fi lede soju opo Instagram, Olori Chanel ṣapejuwe gbogbo ohun to jabọ lẹnu Oluwo gẹgẹ irọ lati si ọpọ lọna ati lati tabuku si ipo ladelade ni ilẹ Yoruba.
Eyi jade lẹyin awọ to waye laarin Ooni of Ife ati Oluwo.