You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Adeyinka Godson fún ẹ̀yà Igbo ní gbèdéke láti fi ilẹ̀ Yorubá sílẹ̀
Ilu London, nil Gẹẹsi lo fi ṣe ibugbe.
Oun ni aarẹ ẹgbẹ Young Yoruba for Freedom, YYF, ẹgbẹ kan to ni afojusun oun ni lati tun ìtàn kọ, nipa fifa ẹya Yoruba jade kuro ni Naijiria, lati da orilẹ-ede tuntun Oduduwa Republic silẹ.
O ni oju opo kan sori ayelujara Facebook, nibi to ma n fi awọn fidio to fi n gbe afojusun rẹ lẹyin, si.
Ọdun 2012 lo da ẹgbẹ YYF silẹ, lati le "tun ero awọn ọdọ Yoruba ṣe, ati lati le ja fun iṣejọba ẹlẹkun-jẹkun".
Kii ṣe igba akọkọ ti yoo dunkooko mọ awọn ẹya ti kii ṣe Yoruba lorilẹ-ede Naijiria niyii.
O ti ṣe bẹ laimọye igba, koda awọn ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ti mu u ri ni ọdun 2019, fun pe o dunkooko mọ awọn eeyan ẹya Igbo, ati Fulani lori ayelujara.
Wọn ni iwa rẹ le da ija ẹlẹyamẹya silẹ, to si tun le ru igbesunmọmi soke.
Iroyin sọ pe wọn gbẹsẹ le iwe irinna rẹ, ati awọn nkan miran.
Afenifere, Soyinka korò ojú sí fídíò tó n dúnkokò mọ́ àwọn èèyàn ẹ̀yà Igbo tó wà nílẹ̀ Yoruba
Ẹgbẹ Afenifere ti sọ pe oun ko lọwọ si fidio kan to n lọ kaakiri ori ayelujara, ninu eyi ti ọkunrin kan ti fun awọn eeyan ẹya Igbo ni gbedeke wakati mejidinlaadọta lati kuro ni ilẹ Yoruba.
Ninu atẹjade ti Olori ẹgbẹ Afenifere, Alagba Reuben Fasoranti fi sita lọjọ Satide, ẹgbẹ naa sọ pe oun ko mọ nipa fidio naa rara.
Fasoranti sọ pe nkan itiju ni bi ọkunrin to sọrọ ninu fidio naa, ṣe fi orin ẹgbẹ Afenifere bẹrẹ ọrọ rẹ, eyi to mu ko da bi ẹni pe ẹgbẹ naa lo wa nidi ikilọ.
Ninu fidio naa, ni ọkunrin naa, Grandson Adeyinka ti sọ pe "awọn fun gbogbo awọn eeyan ẹya Igbo to n gbe nilẹ Yoruba ni gbedeke wakati mejidinlaadọta, to bẹrẹ ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun si ọjọ Aiku, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, lati pada si ilu abinibi wọn.
O ni "bẹrẹ lati ọjọ Aje, ao bẹrẹ si ni da gbogbo ọkọ duro laarin ilu, ao wọ ileeṣẹ, ọja ati awọn ibi gbogbo lati wo awọn ẹya to wa nibẹ.
Ẹnikẹni ti a ba ri to jẹ ẹya Igbo, la o fi iya jẹ lai si aanu."
Grandson to pe ara rẹ ni aarẹ ẹgbẹ awọn ọdọ Yoruba to n pe fun ominira, Young Yorubas for Freedom (YYF), ni awọn ọlọpaa nilẹ Gẹẹsi ti kọkọ mu ni oṣu Kẹjọ, ọdun 2019, nilu London , fun pe o n dunkooko mọ awọn ẹya Igbo ati Fulani lori ayelujara.
Wọn si tun fi ẹsun pipete ija ẹlẹyamẹya, ati igbesunmọmi kan-an. Amọ, ao le sọ boya ẹjọ ti pari lori awọn ẹsun naa.
Bakan naa ni Ọjọgbọn Wole Soyinka ti bu ẹnu atẹ lu fidio tuntun ti Grandson fi sita, to si rọ awọn eeyan ẹya Igbo to n gbe nilẹ Yoruba, lati ma fi eti si nkan to sọ.
O ṣe apejuwe iwa ọkunrin naa gẹgẹ bi ti ẹni ti ọpọlọ rẹ ko pe e.