Yoruba Staff of Office: Àwọn ọbá aláye ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún rèé pẹ̀lú ọ̀pá àṣẹ wọn

Ni ilẹ kaarọ ojiire, ọpa aṣẹ jẹ ohun kan pataki to ni itumọ tir ninu aṣa iran Yoruba to bẹẹ ti pataki rẹ ṣe dede pẹlu ade ori ọba gan funrarẹ tori o wa lara aṣẹ ti ọba ni.

Ọkan lara awọn ọrọ to fọnka ori ayelujara lẹnu ọjọ mẹta yii ni iroyin bi awọn ọdọ janduku kan ṣe ya wọ aafin Oba rilwan Akiolu ti ilu eko ti wọn si ji ọpa aṣẹ gbe lọ.

Kete ti ọba ba ti gori oye nilẹ Yoruba, ati ọ́pọ́ aṣẹ, ade ọba, irukẹrẹ lo ti di awọn nkan ami aṣẹ fun ọba alade naa eyi ti awọn eeyam si fi maa n pe wọn ni "alaṣẹ ikeji oriṣa".

Diẹ lara awọn ba ilẹ Yoruba tawọn ti ọpa aṣẹ wọn lọjọ iwuye ree.

Alaafin Oyo

Oba Lamidi Adeyemi keji lo gba ọpa aṣẹ lọwọ Alaafin Gbadegesin Ladigbolu II lọdun 1970 lẹyin ogun abẹle igba naa. Lasiko naa, gomina Ọgagun Robert Adeyinka Adebayo lo wa nipo, nigba naa lo gori oye ti wọn si gbe ọpa aṣẹ le e lọwọ. Ko ko ko ni Ọba Adeyemi, Alaafin Iku Baba Yeye ṣi le lori alefa pẹlu bi baba ṣi ṣe n bi sii to si n rẹ sii.

Ọọni Ile Ife

Kẹti kẹti ni ilu Ile Ife lasiko ti Ooni tuntun, Oba Adeyeye Ojaja II ṣe iwuye gẹgẹ bii Ọọni ikọkanlelaadọta ti Ile Ife.

Lẹyin ọdun mẹtalelọgbọn ati ọjọ kan ti Ooni ti tẹlẹ naa ṣe iwuye ni ti Ooni naa waye eyi ti gomina Old Oyo nigba naa lọhun, Oloogbe Bola Ige ti gbe ọpa aṣẹ le e lọwọ.

Torinaa, Ogunwusi gori oye ni ọjọ kẹrindinlọgbọn lẹyin ọpọlọpọ fa ki n fa a ija oye to gbona janjan laarin gbogbo awọn Arẹmọ oye to wa lasiko naa.

Olubadan ti Ibadan

Lọjọ karun oṣu kẹta dun 2016 ni Olubadan to wa lori oye bayii, Oba Saliu Akanmu Olasupo Adetunji, Aje Oguguniso I gba ọpa aṣẹ.

gomina ana ni ipinlẹ Oyo to ti di oloogbe bayii, Abiola Ajimobi lo gbe ọpa aṣẹ le ọba Saliu lọwọ to si sọ ọrọ iyanju lọjọ naa pe ki awn oloye alabaṣiṣẹpọ rẹ takete si gbogbo ọrọ oṣelu.

Oluwo ti Ilu Iwo

Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi gba pa aṣẹ gẹgẹ bi Alayeluwa ti ilu Iwo ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kini ọdun 2016.

Gomina ipinlẹ Osun lọdun naa, Ọgbẹni Rauf Aregbesola lo gbe ọpa aṣẹ le Oluwo lọwọ.

Ọluwo jẹ ọkan lara awọn ọba to jẹ ọdọ to si tun maa n sọrọ daadaa lori ayelujara.

Osemawe ti Ondo

Osemawe ti ilu Ondo jẹ ọkan lara awọn ọba alaye ni Ilu Ondo, ipinlẹ Ondo.

Osemawe Ondo, Oba (Dr.) Victor Adesimbo Kiladejo, Jilo III gba ọpa aṣẹ ni ọdun 2006.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ọ, o ayẹyẹ ọdun mẹwaa lori oye ninu oṣu kọkanla ọdun 2016.