Àjọ NBC fi ẹgba ìbáwí rẹ̀ na AIT, Arise TV àti Channels nítorí ìwọ́de ENDSARS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ to n mojuto eto igbohunsafẹfẹ lori redio ati tẹlifisan ni Naijiria, NBC, ti na ẹgba ibawi rẹ si ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ mẹta, AIT, Arise TV, ati Channels.

Ajọ naa fi ẹsun kan wọn pe wọn tapa si ofin to de igbohunsafẹfẹ, nipa ṣiṣe afihan awọn fidio ti wọn ko ṣe iwadii rẹ.

Adele Ọga Agba ajọ NBC, Ọjọgbọn Armstrong Adachaba, kede eyi nibi ipade oniroyin kan to waye nilu Abuja lọjọ Aje.

Ajọ NBC sọ pe awọn ileeṣẹ amohunmaworan mẹtẹẹta yii fi awọn fidio nipa ibọn yinyin to waye ni Lekki sita, lai wadii boya otitọ ni wọn tabi ayederu.

Gẹgẹ bi ikede ti ajọ naa fi sita, owo itanran ti wọn yoo san wa laarin miliọnu meji si miliọnu mẹta Naira.

Ọsẹ to lọ ni ajọ naa ti kọkọ fi atẹjade sita, lati fun awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ni ilana ti wọn yoo tẹlẹ lori iwọde naa.

Wo ìròyìn, àwòrán àti fídíò èké nípa ìwọ́de EndSARS

Owe Yoruba kan lo ni ọrọ okeere, bi ko ba lekan, yoo dinkan ni.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu awọn iroyin gbogbo tawọn eeyan maa n ju sori ayelujara, to fi mọ awọn aworan abi fidio nipa isẹlẹ kan.

Bi eeyan ko ba si se iwadi bo se yẹ, tabi ko ka ojulowo iroyin lati awọn ileesẹ iroyin bii BBC Yoruba, to maa n tọpinpin iroyin bo se yẹ, afaimọ ki eeyan ma sẹ dẹsẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, isẹlẹ ikọlu bo waye laipẹ yii nibi iwọde EndSARS lẹnu bode Lekki, ti bi oniruuru nnkan miran laarin ilu nitori iroyin eke tawọn eeyan kan n pin kiri nipa isẹlẹ naa.

Koda, awọn iroyin, aworan ati fidio to jinna sootọ nipa isẹlẹ Lekki lo lu ori ayelujara kan, eyi to mu ko fẹ lọwọ iwa ẹlẹyamẹya ninu bayii.

Awọn iroyin, aworan ati fidio eke ti wọn pin kiri lori isẹlẹ Lekki:

Aadọrin oluwọde EndSARS ni ologun yinbọn pa ni Lekki:

Ni kete ti isẹlẹ ikọlu Lekki waye ni ọjọ Isẹgun, ogunjọ kẹwaa, ni iroyin kan ti gba ori ayelujara pe awọn ologun ti yinbọn pa awọn ọdọ to le ni aadọrin.

Awọn miran tilẹ se onkaa tiwọn lati ogun si mẹẹdọgbọn, eyi to mu ki ori ọpọ ọmọ Naijiria gbona.

Sugbọn lẹyin igba ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu se abẹwo yika awọn ile iwosan ilu Eko loru mọju ọjọ ti isẹlẹ naa waye, o fidi rẹ mulẹ pe ẹmi kan soso lo ku nile iwosan ti wọn gbe awọn oluwọde to fara gbọgbẹ lọ.

Bakan naa ni wọn ri oku ẹlomiran nile igbokusi to wa ni Yaba, ti ọgbẹ ọta ibọn si wa lara rẹ, amọ ko sẹni to le sọ boya asiko iwọde EndSARS ni oloogbe naa ti jade laye.

Ibọn pa agunbanirọ kan ni Eko:

Aworan miran to tun n fọ ni lori ni ti oku agunbanirọ kan ti wọn n pin kiri pe wọn yinbọn pa nilu Eko.

Sugbọn nibẹ naa ni wọn ti n tako ẹni to pin aworan naa lori ayelujara pe irọ ni.

Wọn ni wọn ya aworan naa ninu ere sinima kan, kii si se otitọ ni ọrọ naa.

Eniola Badmus fara gbọgbẹ ọta ibọn lọwọ ologun ni Lekki, o wa lẹsẹkan aye, ẹsẹ kan ọrun:

Bakan naa ni ẹnikan gbe soju opo Twitter rẹ pe gbajumọ osere tiata kan, Eniola Badmus ti fara gba ọta ibọn latọwọ awọn ologun ni Lekki.

Iroyin naa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni Eniola wa, ti wọn si du ẹmi rẹ lọwọ nile iwosan.

Amọ alẹ ọjọ naa ni Eniola kede loju opo Twitter ati Instagram rẹ pe ko si ohun to se ohun, saka ni ara oun da.

Ijọba pasẹ fun ileesẹ to n pin ina ọba ni Eko, EKEDC, lati pa ina ladugbo Lekki:

Ori ayelujara gbona pẹlu iroyin tawọn eeyan kan n pin kiri pe ijsba Eko lo pasẹ pe ki ileesẹ amunawa mase fun adugbo Lekki ni ina ọba.

Wọn ni eyi lo fun awọn ologun ni anfaani lati fi okunkun boju, sisẹ ibi lọjọ Isẹgun naa.

Amọ iwadi fihan pe eyi ko ri bẹẹ nitori ina tawọn ara adugbo Lekki nlo ni wọn n pese funra wọn.

Bakan naa si ni ajọ EKEDC ti fi iroyin sita pe ebu lasan ni iroyin naa.

Asita ibọn ọlọpaa lo pa Oke ninu ile rẹ ni Mafoluku:

Iroyin miran lo ni asita ibọn tawọn ọlọpaa yin lo ba ọkunrin kan lọjọru, lasiko taọn janduku fẹ jo agọ ọlọpaa Makinde to wa ni Mafoluku.

Sugbọn ẹnikan to pe ara rẹ ni aburo oloogbe, Daniel, jade sita pe awọn janduku lo wọle gun ẹgbọn ohun lọrun pa, kii si se asita ibọn ọlọpaa lo baa.

Ugwu Blessing Ugochukwu padanu ẹmi rẹ:

Lara ẹbu iroyin to gba ori ayelujara nipa isẹlẹ Lekki ni pe obinrin kan Ugwu Blessing Ugochukwu padanu ẹmi rẹ lasiko to jo, to si mu asia Naijiria lọwọ.

Amọ iwadii wa fihan pe irọ gbaa ni , ti agbẹnusọ obinrin naa si ni lootọ ni SARS gbe Ugochukwu lọdun 2018 amọ ko si ohun to se.

Gbigbe asia Naijiria lọwọ ko le gba ọ lọwọ ologun:

Iroyin yii gba ori ayelujara kan pe tawọn oluwọde ba ti mu asia orilẹede Naijiria lọwọ, awọn ologun ko ni kọju ibọn si wọn.

Sugbọn ninu ifọrọwerọ BBC pẹlu agbẹjọro kan, Onyekachi Umah, o ni lootọ ni ọwọ nla wa fun asia ilẹ wa amọ eyi ko tumọ si pe ologun ko lee gbe igbesẹ lori rẹ.

Awọn alufa Katoliki rin lọwọọwọ lati se atilẹyin fun iwọde EndSARS:

Ẹbu iroyin miran to tun gba ori ayelujara ni aworan ati iroyin kan to safihan awọn alufa ijọ aguda, ti wọn n rin lọwọ.

Akọle to wa labẹ aworan naa lo ni wọn n se iwọde lati se atilẹyin fun iwọde EndSARS ni.

Sugbọn kia ni ijọ Katoliki kede loju opo Twitter rẹ pe iroyin naa ki se otitọ nitori ọjọ pẹ ti awsn ti ya aworan naa.