You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Public Anger: Irú ọ̀rọ̀ wò láwọn olóṣèlú Nàìjíríà márùn ùn yí sọ tó mú ìbínú ará ìlú wa?
Awọn iṣẹlẹ inu ọdun 2020 yi jẹ eyi to n mu haa hun un wa lọdọ awọn ọmọ Naijiria.
Bi a ko ba maa ṣe wawu lori ikọlu awọn oluwọde, awọn ara ilu a si maa ṣeemọ lori ọrọ tabi iṣesi awọn oloṣelu ni idahun sawọn iṣẹlẹ to n waye.
- Ẹ gbọ́ ohun tí Desmond Elliot sọ lórí ayélujára tó bí àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú
- Bọ́ọ̀sì ìrìnà 106 tuntun yóò máa ná Ibadan sí Eko àtàwọn ìpínlẹ̀ míì - Seyi Makinde
- Kìí ṣe ebi, ìyà tàbí ìṣẹ́ ló mú kí wọ́n yabo àwọn ilé ìkẹ́rùsí - Femi Adeshina
- Wo bí o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ láti gbà nínú N75b tí ìjọba fẹ́ ẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ láti dá iṣẹ́ sílẹ̀
Pẹlu bi awọn oloṣelu ati araalu ṣe n takurọsọ lẹnu lọọlọ yi, a ṣe akojọpọ awọn oloṣelu marun un ti ọrọ ẹnu wọn tabi ihuwasi wọn ti mu ki ara ilu gbena woju wọn ni Naijiria.
Diẹ ree ninu wọn:
Minisita Amaechi ati ọrọ pe Naijiria fẹ jọwọ ominira fun China
Nigba ti Minisita feto irina ni Naijiria Rotimi Amaechi n ṣalaye idi ti owooya lọwọ China ṣe ṣepataki si ọrọ kan lu ago leti awọn ọmọ Naijiria.
Ọrọ naa to sọ niwaju igbimọ ile aṣofin jọ bi igba pe o ni ko si aburu ki Naijiria jọwọ ominira rẹ fun China.
Ọpọ ko dunnnu si Amaechi ti o si ni lati ṣalaye daada itumọ nkan ti o gba lero lori ọrọ naa.
Ati alatako ati awọn ọmọ Naijiria mii, niṣe lawọn eeyan ṣigun bo oju opo Twitter ti wọn si ni ohun to sọ yi ku diẹ kaato.
Họnọrebu Agunbiadeto ni oun fẹ pin Paliatiifu lasiko ọjọ ibi
Ọmọ ile aṣojuṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Ikorodu nile igbimọ aṣojuṣofin ipinlẹ Eko kan ni Họnọrebu SOB Agunbiade.
O fẹnukọ lọdọ awọn ọmọ Naijiria nigba to ni awọn janduku ji paliatifu ti oun fẹ pin fun awọn araalu lọjọ ibi rẹ eyi to jẹ ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwa ọdun 2020.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ SOB Agunbiade ni ohun tawọn eeyan n pin kaakiri gẹgẹ bi iroyin yii jẹ amọọmọṣe awọn kan lati gbẹ oun lẹsẹ gẹgẹ bi oloṣelu ni.
Lai Mohammed ati ọrọfifi ofin de ọrọ kobakungbe ori ayelujara
Ninu awọn Minisista aarẹ Buhari, Lai Mohammed j eleyi ti ọpọ ọmọ Naijiria ko fẹ ri imi rẹ laatan.
Ohun to si fa gẹgẹ bi awọn kan ti ṣe sọ ni pe kii saba sọ odod ọrọ fara ilu.
Minisita naa mọ pe awọn ọmọ Naijira paapa awọn ọdọ ko gba toun.Amọ ṣa ko tori r ma ṣe iṣẹ rẹ gẹgẹ bi Minisita eto iroyin.
Pataki ninu ọrọ rẹ ti kii ṣalai ma mu ikunsinu wa ni eyi to niṣe pẹlu fifi ofin de ọrọ kobakungbe lori ayelujara ta mọ si 'hate-speech.'
Laipẹ yi ti Minisita sọ fara ilu pe o di dandan lati fofin de itankalẹ iroyin ofege ni Naijira niṣe lawọn eeyan tako.
Koda nigba to ni Naijiria ko ni bojuwẹyin lori abadofin iṣakoso ẹrọ ayelujara, ibinu lawọn ọmọ Naijira fi da lohun.
"Detective Fashola" ati Kamẹra iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan Lekki
Ọrọ ti Minisita to n ri si ọrọ iṣẹ ode ati ileegbe Naijiria Babatunde Fashola ba sọ, a maa saba mu iriwisi wa lati ọdọ awọn ọmọ Naijira.
Bi a ko ba gbagbe o sọ nigba kan pe ere oritage Nolywood n mu ki oogun owo ati ijinigbe gbilẹ si ni Naijiria.
Ninu eleyi to ṣe laipẹ yi, ko tiẹ sọrọ rara.Iwa to hu lo mu ki awọn eeyan mọrọ rẹ bẹnu loju opo ayelujara.
Ohun to ṣe ni pe o kawọ pọnyin lasiko to ṣe abẹwo si Lekki nibi ti iṣẹlẹ ipaniyan ti waye nitori iwọde ENDSARS.
Yatọ si pe o rin kaakiri ibi iṣẹlẹ yi, o tun nawọ gan kamẹra kan nibẹ ti eleyi si mu kawọn eeyan maa fi ṣe yẹyẹ pe o n ṣebi ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ.
Igbagbọ awọn eeyan dopin ninu Desmond Elliot nitori ọrọ to sọ
Jẹjẹ lawọn eeyan joko si oju opo ayelujara ki Desmond Elliot aṣoju ile aṣofin ipinlẹ Eko to fa okete niru.
Ki si ni gbajugbaja elere sinima to wa di oloṣelu yi sọ?
Desmond Elliot ko sọ ju pe ki awọn gbajumọ lawujọ ati awọn oloṣere ye sọrọ kobakungbe lori ayelujara mọ-o tun pe awọn oluwọde ni ''ọmọde''
Hmm. Ọrọ yi mu ibinu wa lọdọ awọn ọmọ Naijira.Nigba ti ariwo pọ lori ayelujara, Elliot tọrọ aforijin ni kiakia