Daura varsity: Amaechi ní ọ̀fẹ́ ni China yóò kọ́ fásítì $50M ètò ìrìnnà sí Daura ìlú Ààrẹ Buhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Minisita eto irinna ọkọ ni Naijiria, Rotimi Amaechi, ti sọ pe ọfẹ ni ijọba orilẹ-ede China yoo kọ fasiti eto irinna ọkọ ti yoo gberasọ niluu Daura, ipinlẹ Katsina loṣu kẹsan an, ọdun 2021.

Aadọta miliọnu owo dọla ni owo ti yoo kọ fasiti naa tan gẹgẹ akọsilẹ ẹka ijọba to n ri si eto irinna ni Naijiria.

Minisita eto irinna to sọrọ yii nigba to lọ ṣe ayẹwo ibi iṣẹ de duro ni fasiti naa ṣalaye pe ọfẹ ni ileeṣẹ onimọ ẹrọ (Technics Engineering Architectural Marketing (TEAM) naa yoo ṣiṣẹ ni fasiti ọhun.

Amaechi ṣalaye ṣiwaju sii pe ni fasiti naa ni wọn yoo ti maa kọ bi wọn yopo ṣe maa ṣe amojuto ọna reluwe ti ileeṣẹ kan lati China n ṣe lọwọ bayii ni Naijiria.

Bakan naa ni minisita sọ fawọn agbaṣẹṣe nibẹ lati kọ ileewe alakọbẹrẹ ati girama si fasiti ọhun.

O ni eyi ni yoo fawọn ọmọ awọn to yoo maa ṣiṣẹ nibẹ lanfaani lati fi ọmọ wọn sile iwe.

Ilu Daura ni ipinlẹ Katsina jẹ ilu abinibi Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari.