Arsenal vs Liverpool: Arsenal fìyà bẹ̀rẹ̀ sáà bọ́ọ̀lù tuntun fún Liverpool pẹ̀lú Community Shield

Aṣe igi ti a ba foju rena, lo maa n gun ni loju ni tootọọ. Ẹfọn ja baalu lulẹ ni Wembley lẹyin ti Arsenal fi iya bẹrẹ saa bọọlu tuntun fun Liverpool.Ami ayo marun si mẹrin ni Arsenal fi gbẹyẹ lọwọ Liverpool eyi to mu wọn gba ife ẹyẹ Community Shield.Pierre-Emerick Aubameyang lo kọkọ gbayo wọle Liverpool fun Arsenal ki Takumi Minimano to dayo naa pada.

Ọmi alayo kọọkan ní ifẹsẹwọnsẹ naa pari si ki wọn to fi pẹnariti yanju ẹ.Ife ẹ̀yẹ keji ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal yoo gba ree labẹ akọnimọọgba tuntun, Mikel Arteta lẹyin ti wọn ti kọkọ gba ife ẹyẹ FA CUP.

Igba keji ree ti Liverpool yoo fidi rẹmi nibi ifẹsẹwọnsẹ pẹnariti lọdun 2020 yii lẹyin ti Manchester City ti kọkọ lu wọn pẹlu pẹnariti.

Mẹsan an mẹwaa ni akọnimọọgba Arsenal, Mikel Arteta n ki ẹlẹsẹ ayo, Aubameyang fun ipa ribiribi to ko ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield.

Arteta ni o da oun loju pe balogun Arsenal yoo buwọlu iwe adehun tuntun lati wa pẹlu ikọ agbabọọlu naa siwaju sii.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Aubameyang lo gba pẹnariti ẹlẹẹkarun un to kẹyin wọle fun Arsenal lẹyin to ti kọkọ mi awọn titi ninu ere bọọlu naa ni papa iṣere Wembley.

Oun kan naa lo gba goolu meji sawọn eyi to mu ki Arsenal gba ife ẹyẹ FA Cup loṣu yii ni Wembley lo ti ṣẹlẹ.

Arteta ko ṣai gboriyin fawọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal yoku, o ni gbogbo wọn patapata lo ṣe gudugudu meje yaya mẹfa bi wọn ti fẹyin Liverpool gbalẹ.

Ohun mẹ́fà tí ọ̀pọ̀ kò mọ̀ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Arsenal àti Machester City

Oke ti alagbara gun to mi hẹlẹhẹlẹ ni ikọ Manchester City jẹ fun ọpọlọpọ ẹgbẹ agbabọọlu ni idije premier league, FA Cup lorilẹede Gẹẹsi tabi idije miran kaakiri agbaye.

Eyi si yipada nigba ti ikọ naa koju Arsenal ni alẹ ọjọ Abamẹta.

Ṣaaju ni ọpọlọpọ ti fi ọkan sii pe ṣokoto yoo ṣo idi Mikel Arteta atawọn agbabọọlu rẹ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Amọṣa, ibi aye fojusi ọna ko gba ibẹ lọrọ ja si fun awọn agbabọọlu Arsenal atawọn ololufẹ ikọ naa.

Lẹyin ti alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa fun feere pe ere gbogbo pari, ami ayo meji si odo ni Arsenal fi gbẹyẹ mọ Manchester City lọwọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele to kangun si a'sekagba idije FA Cup ti ọdun yii ni orilẹ-ede Gẹẹsi.

Goolu meji ti atamatase ati Balogun ikọ naa, Pierre-Emerick Aubameyang gba wọ àwọ̀n Manchester City nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejidinlogun ati ikọkanlelaadọrin.

Nibayii, Arsenal ti wọ ipele aṣekagba ife ẹyẹ FA cup bayii, eyi si ni igba ikọkanlelogun iru ẹ ti wọn yoo maa ṣe bẹẹ.

Arsenal yoo maa pade ikọ to ba bori ninu idije Manchester United pẹlu Chelsea

Ninu ọrọ rẹ, Mikel Arteta, olukọni ikọ Arsenal ni iya jẹ awọn pupọ ni ifẹsẹwọnsẹ naa ṣugbọn aato to gun rege ló ko awọn yọ.

Nitirẹ, Pep Guardiola ṣalaye pe nnkan ko ṣẹnure fun awọn agbabọọlu rẹ nitootọ.

Bi nnkan ṣe duro niyi:

  • Arsenal ti de ipele aṣekagba idije ife ẹyẹ FA cup lorilẹ-ede Gẹẹsi fun igba mọkalelogun
  • Igba mẹtala ọtọọtọ ni Arsenal ti gba ife ẹyẹ naa.
  • Lati oṣu keji, ọdun 2018, eyi ni igba akọkọ ti wọn yoo maa yọ ọwọ Manchester City kuro ni ifẹsẹwọnsẹ idije bọọlu abẹle (League cup ati FA cup)
  • Igba mẹfa ọtọọtọ sẹyin ni Arsenal ti di igbaju olooyi ru awọn ikọ to gbe ife ẹyẹ naa dani ni ọdun to ba tẹle aṣeyọri wọn.
  • Bọọlu kan ṣoṣo ni Manchetser City ri gba soju ile Arsenal lati ibẹẹrẹ titi de opin ifẹsẹwọnsẹ naa, eleyi to kere ju fun wọn lati oṣu kẹrin, ọdun 2018.
  • Pierre-Emerick Aubameyang ni agbabọọlu kẹrin ni inu itan Arsenal ti yoo jẹ goolu meji ninu ifẹsẹwọnsẹ kan naa ni papa iṣire Wembley lẹyin Reg Lewis (aṣekagba FA Cup lọdun 1950), Charlie Nicholas (aṣekagba League Cup lọdu 1987) pẹlu Alexis Sanchez ni idije FA Cup lọdun 2015.