Coronavirus and sport: Paul Onuachu ni agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó lùgbàdì Covid 19

Ẹlẹsẹ ayo, ọmọ Naijiria to n gbabọọbu jẹun fun ìkọ Genk lorilẹ-ede Belgium, Paul Onuachu ti ko aarun coronavirus.

Ni Ọjọru ni ayẹwo fihan pe Onuachu nikan lo ni arun covid-19 ninu gbogbo awon agbabọọlu Genk ti wọn ṣe ayẹwo coronavirus.

Amọ, ayẹwo naa tun fihan pe awọn akẹgbẹ rẹ ọmọ Naijiria ti wọn jọ wa ni Genk, Stephen Odey ati Cyrul Dessers ko ni arun ọhun.

Nigba ti Ẹgbẹ agbabọọlu Genk pinnu lati ṣe ayẹwo fun gbogbo agbabọọlu wọn ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọọrẹẹ kan ni ayẹwo naa ti fihan pe Onuachu ti farakasa.

Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun un ni Onuachu rinrin ajo lati Belgium lọ si Naijiria.

Ọjọ kejidinlọgbon, oṣu kẹfa lo lanfaani lati pada si Belgium lẹyin ti o ha si ilu Eko fun ọsẹ kan ti ko ri baalu wọ nitori ajakalẹ arun coronavirus.