You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lateef Adedimeji: Nkan tí a mọ̀ nìyíì nípa ìgbéyàwó tí Lateef àti Adebimpe Oyebade
Bẹẹni, bẹẹkọ lariwo to gba ori ayelujara lopin ọsẹ to kọja lori gbajugbaja oṣere tiata, Lateef Adedimeji pe o ti ṣe igbeyawo.
Eyi ko ṣẹyin bi fọto 'igbeyawo' oun ati arẹwa oṣerebinrin, Adebimpe Oyebade, ṣe jade sori ayelujara.
Eyi lo mu ki awọn ololufẹ wọn o maa beere pe, ṣe o ṣeeṣe ko jẹ pe wọn ti ṣe igbeyawo ni tootọ?
Eyi waye nitori kii ṣe igba akọkọ niyii ti wọn fi iru fọto bẹẹ sita.
Awuyewuye ti waye lori awọn mejeeji ri pe, wọn n fẹ ara wọn.
Fọto imurasilẹ fun igbeyawo, 'pre-wedding shoot' awọn mejeeji jade sori ayelujara lọdun to kọja.
Ṣugbọn, awọn mejeeji pada sọ pe, sinima kan ni wọn ya aworan naa fun.
Lẹyin ti eruku ẹjọ lọ ọ lẹ lori fọto naa, ni Adebimpe sọ nigba naa pe, Lateef kii ṣe iru ọkunrin ti oun le fẹ.
O ni ọrẹ timọtimọ ni awọn.
Kii ṣe Adebimpe nikan ni iroyin jade pe oun ati Lateef n fẹra.
Iroyin ti jade laimọye igba pe, Lateef ati oṣerebinrin miran, Bukunmi Oluwashina, n fẹ ara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí Hushpuppi ṣe tiraka rèé l‘Eko, kí ọlà ‘òjijì’ tó dé
- Akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà, ìjọba Oyo kò pèsè ìbòmú lòdì sí ìlérí rẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
- Kàkà k‘éwé àgbọn dẹ̀ lágbo òṣèlú l‘Ondo, akọ̀wé ìjọba tún kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
Lọtẹ yii, o dabi ẹni pe ọrọ ẹnu Bimpe yatọ si awọn aworan tuntun yii.
O kọ sabẹ awọn aworan naa to fi sita lori ayelujara Instagram rẹ pe "Adedimeji Lateef, mi o nilo alujanna, nitori pe mo ṣawari rẹ.
Eyi si ti fa ariyanjiyan laarin awọn ololufẹ wọn.
Awọn kan tilẹ sọ pe, o sẹeṣe ko jẹ pe ileeṣẹ to n da awọn aṣọ igbeyawo naa ni wọn n ba polowo ọja.
Akiyesi BBCnipa aworan igbeyawo Lateef ati Adebimpe:
- Lateef kii lo yẹti tẹlẹ, nitori pe musulumi ododo ni. Ṣugbọn ninu aworan yii, o lo yẹti, eyi to jẹ ọkan lara awọn idi ti o fi ṣoro lati gbagbọ pe fọto igbeyawo gidi ni
- A tun ṣakiyesi pe, ko si ẹnikẹni ninu awọn akẹẹgbẹ wọn ninu isẹ tiata, to ki wọn ku oriire ayẹyẹ igbeyawo
- Eyi jẹ nkan to ṣe ajeji lagbo Yollywood. Arire ba ni se ni wọn, wọn kii si fi bo
- Lara akiyesi wa tun ni pe, ko si oruka igbeyawo lọwọ Adebimpe tabi Lateef ninu fọto tuntun naa. Kayeefi nla miran tun ni eyi jẹ
- Bakan na ni ko si aworan awọn ẹbi wọn, eyi ti a gbagbọ pe ko ṣeeṣe ki wọn o se igbeyawo lai si pe awọn ẹbi wọn kopa nibẹ
- Irun ori Lateef naa tun tọka si pe, o ṣeeṣe ko jẹ pe sinima kan ni wọn ya awọn fọto naa fun.
- Irun ori rẹ dabi ti Dada, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni rough curls. Lateef kii ge iru irun yii loju aye
- Ara awọn nkan mirian tun ni ọrọ ti awọn akẹẹgbẹ wọn bi Bimbo Oshin, ati Debo, a.k.a, Mr. Macaroni sọ lori awọn fọto naa ti Lateef si sita.
Diẹ lara awón to ti ki wọn:
Bimbo Oshin sọ pe "Ẹ ku oriire o, ṣugbọn bawo ni mi o se gbọ nipa igbeyawo naa?
Mr Macaroni sọ pe "Ẹ mura si..."
Ju gbogbo rẹ lọ, to ba jẹ pe igbeyawo tootọ ni, tabi ayederu, ọrọ yoo to fi oju han.