You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Hushpuppi: Ìròyìn sọ pé ó ṣiṣẹ́ olórin rí, ta àlòkù àṣọ àti Kọ̀ńpútà
Hushpuppi lorukọ ti ọpọ mọ si ti o si jẹ pe isọwọ fi ọla rẹ han sọ di ilumọọka loju opo ayelujara.
Ṣugbọn ta ni arakunrin ti awọn ọlọpaa ilẹ Dubai ati ọtẹlẹmuyẹ Amẹrika gbe, fun ẹsun gbajuẹ olowo iyebiye yii?
Nibo ni wọn ti bi? Ta lawọn obi rẹ ati pe bawo lo ti se di ọlọrọ ti awọn eeyan kan n fi ọla rẹ tọrọ, pe ki awọn naa ri bi tiẹ?
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Diẹ ree ninu nkan ti a ri ko jọ nipa Hushpuppi
Ilu Eko ni wọn bi si
Ni pato ọjọ ti wọn bi Hushpuppi ti orukọ rẹ gangan n jẹ Ramoni ''Raymond'' Igbalode ko ye wa ṣugbọn bi a ba fi awọn nkan to sọ nipa ara rẹ wo ọrọ yii, ko le ti to ogoji ọdun.
Eyi to sunmọ ootọ ninu ọrọ aye rẹ ni pe nilu Eko lo dagba si, ki o to kuro lorilẹede Naijiria.
Ninu awọn aworan rẹ nigba to wa ni kekere, a ri ibi to ti duro lara ọkọ nilu Eko ati awọn omiran to tọka si pe o ti gbe Naijiria daada, ki o to lọ si ilu okere.
Loju opo rẹ ni Instagram, o tun sọ nipa ọjọ ori rẹ pe, oun ti gun oke agba bọ diẹ diẹ wọ ọmọ ọgbọn ọdun.
Loṣu Kẹwa ọdun 2019 lo fi ọrọ yii sita, eyi to jẹ ki a lero pe oṣu Kẹwa ni wọn bi.
Ṣe lootọ ni pe o ta bọsikọrọ l'Eko?
O ti ṣe awọn isẹ ọwọ kan ki o to kuro ni Naijiria ṣugbọn a ko ri aridaju lati fidi ọrọ mulẹ iru iṣẹ to jẹ.
Lẹyin ti awọn ọlọpaa Dubai mu tan la bẹrẹ si ni ri aworan orisirisi, to se afihan iru iṣẹ to kọkọ bẹrẹ si ni ṣe ki o to kuro ni Naijiria.
Ọkan ninu iṣẹ ti wọn lo ṣe ni pe, o jẹ olootu orin ti a mọ si Music Producer, ti o si ba awọn olorin Naijiria kọọkan ṣiṣẹ pọ.
Gẹgẹ bi awọn kan ti se sọ, wọn tun ni Ramoni ti ta aṣọ bọsikọrọ nigba to wa l'Eko, koda wọn tun sọ wi pe o kọ isẹ foonu ati kọmputa tita ni Computer Village nilu Eko kan naa.
Pẹlu gbogbo nkan ti a ka kalẹ yi, eleyi ti ohun gangan kii ye sọ nipa rẹ ni pe, awọn obi rẹ kii se olowo ati pe, ohun t'apata dide ni ki ẹlẹda to wa kọdi ọla si ọdọ ohun.
Awọn mọlẹbi rẹ ko foju han lẹyin ti ọwọ tẹ
Wọn ni ọwọ epo lọmọ araye n ba ni la, wọn kii ba ni la ọwọ ẹjẹ.
Ṣaaju ki ọwọ to tẹ Hushpuppi, kii saba sọrọ nipa awọn mọlẹbi rẹ to bẹẹ loju opo ayelujara.
Yatọ si aworan to fi sita nipa ọmọ iya rẹ obinrin to bimọ lọdun 2019, awọn eeyan ko le tọ ka si pe lagbaja tabi tamẹdun ni ọmọ iya Hushpuppi.
Layajọ iya tabi Baba ti a mọ si Father's Day ati Mother's Day, Hushpuppi kii kọ nkankan nipa awọn obi rẹ debi ti awọn eeyan yoo fi le sọ pe, bi awọn obi rẹ ti se ri ree tabi nibi ni wọn n gbe.
Loju opo ẹni to pe ni ọmọ iya rẹ obinrin@ rawflesh_may_9, ko si nkankan nibẹ lori Instagram, lati le fi tọkasi ẹni to n jẹ bẹẹ.
Bi a ba sọ pe Hushpuppi nikan lo ri ara rẹ lasiko yii ati pe awọn mọlẹbi ko foju han pe, eeyan awọn nii ṣe, a ko kuna rara lati sọ bẹẹ.
Ẹsin wo ni Hushpuppi n ṣe?
Idahun si ibeere yii pin si ọna meji.
Akọkọ ni pe ti a ba fi orukọ abinibi rẹ wo, tii se Ramoni, idile musulumi lo ṣeese ki o ti jade.
Ninu awọn ọrọ kan to fi sioju opo Instagram rẹ, o sọ pe oore ti Allah ṣe fun ohun to ga ju lọ ni pe, oun jẹ musulumi.
Lọdun 2012 lo fi ọrọ yi sita, ti a ko si le sọ boya o ṣi n ṣe ẹsin Islam titi di igba ti wọn fi mu bii afurasi onijibiti.
Bi a ba tibi orukọ rẹ to yi pada si Raymond wo, o ti le fi ẹsin Islam silẹ ṣugbọn o le jẹ inagijẹ lasan ni Raymond, ki o ma se wi pe o pa ẹsin da.
Bakan naa ninu fọnran fidio kan to fi si oju opo Instagram to ti n wẹ ninu omi iluwẹ igbalode, orin iyin ẹsin Kristẹni ni o n kọ ninu rẹ.
Yatọ si eyi, pupọ awọn nnkan to ma n kọ soju opo ayelujara, a ma fi adura to jọ ti Kristẹni sinu rẹ.
Gbogbo awọn kan wọn yii ni ko jẹ ki a le sọ boya Kristẹni ni Hushpuppi tabi Musulumi.
Eyi to daju ni pe, ati ẹlẹsin Kristẹni ati ẹlẹsin musulumi lo wa ninu awọn eeyan to le ni miliọnu meji to n tẹle loju opo Instagram.
Wo bí ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dubai ṣe tẹ Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
Ramoni Igbalode ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi to fi orilẹ-ede Dubai ṣe ibujoko lasiko yii ni ọwọ awọn agbofinro ilẹ Dubai ti tẹ.
Ninu fọnran fidio 'Fox Hunt 2' ni wọn ti ṣafihan rẹ.
Lọjọbọ ni ileeṣẹ agbofinro dubai fi fidio bi wọn ṣe mu gbajugbaja ori ayelujara Instagram naa sita.
Ọpọlọpọ owo bii owo to wa fun itọju Covid 19 ni Amẹrika ati awọn owo to le ni biliọnu dọla mẹrinlelogun ni wọn ti fi gbajuẹ gba.
Ọlọpaa Dubai ṣalaye bi wọn ṣe mu Hushpuppi ninu atẹjade ti wọn fi sita ti BBC ri.
Wọn ni awọn ti n fura sii ti pe pe o n ṣe awọn 'ọmọ Yahoo'ti wọn n gba awọn eeyan lori ayelujara.
Nibẹ ni wọn ti fi si ori ikanni naa nipa Ramoni Igbalode ati Olalekan Jacb Ponle ti wọn n pe ni 'Woodberry'ati awọn ọmọ ilẹ Adulawọ miran.
- .Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Ìpínlẹ̀ Oyo sọ àsìá Nàìjíríà kalẹ̀ láti dárò Abiola Ajimobi
- Kọmíṣọ́nà mẹ́ta lùgbàdì àrùn Coronavirus l'Ọyọ
- Tinubu, oju ti ẹ, o ta ilẹ Yoruba fun ọta rẹ nitori adanikanjẹ- Femi Fani-Kayode
- Wo odò tí wọ́n ti rí Aishat tí àgbárá òjò gbé lọ ní Eko
Iṣẹ akanṣẹ lati mu awọn ọmọ Yahoo ori ayelujara yii ni awọn agbofinro Dubai pe ni: 'Operation Fox Hunt 2'
Awọn ẹṣẹ bii jiji owo ko lati asuwọn kan si ikeji, jiji owo lori ayelujara, wiwọ akata ayelujara ati eto inawo ẹlomiran lọna aitọ, ṣiṣẹ gbajuẹ fun awọn eeyan ni awujọ ati fun awọn banki ni wọn mu wọn fun.
Ogagun Abdulla Khalifa Al Marri to n tukọ ileeṣẹ ọlọpaa gboriyin fun awọn ọlọpaa Dubai fun iṣẹ takuntakun ti wọn ti fi mu awọn mẹwaa naa.
O ni eyi yoo tun din ole ori ayelujara ati gbajuẹ pẹlu ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa ku diẹ lagbaye lasiko yii.
Invictus Obi, Hushpuppi, àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà méjì tí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ wà lọ́rùn wọn
Ajọ to n koju iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC ti ni Ramoni Igbalode, alias Ray hushpuppy ni ẹjọ lati jẹ ni ọdọ wọn.
EFCC to fi eyi lede loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni Hushpuppy is ẹni to gajulọ lorilẹede Naijiria ti wọn n wa bayii fun ẹsun iwa ọdaran lori ẹrọ ayelujara.
Ọjọ kẹ̀wá, Osù Kẹfa ní wọn fí panpẹ́ ọba mú Hushpuppi ní United Arab Emirates lórí ẹ̀sùn lilọ gbajuẹ pẹlu ẹrọ ventilator to le ni $35million.
Ajọ naa ni awọn mọ nipa jibiti owo ati 419 to ṣe ni Niajiria, ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ si ti wa ni panpẹ awọn bayii lorilẹede Naijiria.
EFCC fikun wi pe awọn n ṣiṣẹ pẹlu Ajọ Otẹlẹmuyẹ ilẹ Amerika, FBI titi ọwọ palaba rẹ fi segi.
A ti wi pe gbogbo awọn ti wọn j n ṣiṣẹ ni awọn n wa bayii lati ri wi pe ọwọ tẹ wọn ni kiakia.
Bakan naa ni iroyin gbe e pe Obinanne Okeke, to jẹ ilumọọka onisowọ ti wọn mu fun ẹsun lilo ẹrọ ayelujara lati ṣe magomago, ti jẹwọ pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun naa.
Ọkeke to jẹ ọmọ ọdun mejilelọgbọn ni awọn ajọ ọtẹlẹmuye mu pe, o wuwa ibajẹ lori ẹrọ ayelujara ni ọdun 2015 si ọdun 2019.
O ṣeeṣe ki Okeke lọ to ogun ọdun ni ọgba ẹwọn fun ẹsun wiwu iwa ọdaran lori ẹrọ ayelujara.
Ọjọ kejilelogun, Osu Kẹwa ọdun yii ni wọn yoo ma a se idajọ rẹ.
Àwòrán rèé nípa àwọn gbajúmọ̀ tó ti bá Hushpuppi ṣe
Lati igba ti awọn ọlọpaa ti mu gbajumọ ori ayelujara Instagram, Ramoni Abbas Igbalode, a.k.a Hushpuppi, lori ẹsun pe o lu jibiti lori ayelujara, ni awọn ọmọ Naijiria kan ti n tọka si awọn gbajumọ ti aworan wọn ti jọ han lori ayelujara ri.
Ọpọ lo bu ẹnu atẹ lu awọn ilumọọka naa, ati awọn oloṣelu, to ba Hushpuppi ya fọto ri, pe o ṣeese ki wọn o mọ pe "iṣẹ jibiti" ti wọn fi ẹsun rẹ kan an, lo n ṣe.
Diẹ lara awọn aworan naa ni a ṣe akojọpọ rẹ yii.
Davido:
Gbajugbaja akọrin Naijiria, David Adeleke da bi ẹni pe ibaṣepọ wa laarin oun ati Hushpuppi.
Koda, Hush lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo ẹgbọn Davido, Adewale, to waye nilu Dubai nibẹrẹ ọdun 2020.
Aworan si fihan pe Davido ati Chioma iya ọmọ rẹ, ti ba Hushpuppi ni alejo ri.
Lasisi Elenu:
Gbajugbaja adẹẹrinpoṣonu ori ayelujara, Lasisi Elenu, naa jẹ ọkan lara awọn gbajumọ to ti ni ibaṣepọ pẹlu Hushpuppi.
Awọn iroyin kan ti ẹ sọ pe, Elenu ma n sọrọ iwuri nipa rẹ si afurasi gbajuẹ naa.
Ifedayo Olarinde a.k.a Daddy Freeze:
Laipẹ yii ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to ṣafihan agbohunsafẹfẹ, Daddy Freeze, ati ọrẹbinrin rẹ, nibi ti wọn ti kopa nibi ayẹyẹ ọjọ ibi Hushpuppi, nilu Dubai.
Fidio naa ṣafihan wọn ti wọn jẹ, ti wọn mu, koda, Freeze sọ ninu fidio naa pe ki "awọn ọdọ to n sọrọ Hushpuppi laida lori ayelujara o bẹ Hushpuppi lati gba baba wọn siṣẹ awakọ rẹ."
O sọ eyi nitori pe Hush ni N700,00 ni awakọ oun n gba l'oṣu.
Sugbọn Freeze yi ohun pada lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ Hushpuppi laipẹ yii.
O sọ ninu fidio kan pe oun o mọ pe gbajuẹ ni Hush n ṣe.
Wiskid:
Ilumọọka olorin, Wiskid naa ti ṣe faaji pẹlu Hushpuppi ri, koda awọn mejeeji ti jọ ṣe faaji lori omi ri nilu Dubai.
Dino Melaye:
Ọmọ ile aṣofin agba Naijiria nigba kan, Dino Melaye, naa wa lara awọn ti Hush ba ya fọto ri.
O ṣeeṣe ki ibaṣepọ wọn o tayọ fọto yiya, nitori pe Hushpuppi naa lọ sibi ayẹyẹ ọjọ ibi ti Melaye ṣe nilu Dubai lọdun 2019.
Ṣugbọn o, Melaye naa ti sọ pe oun ati ẹ kii ṣe ọrẹ, lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ Hush.
Mompha:
Ọrẹ timọtimọ ni awọn eeyan maa n pe awọn mejeeji yii. Koda, awọn ololufẹ wọn maa n ṣe afiwe ẹni to lowo lọwọ julọ laarin wọn.
Laipẹ yii naa si ni Mompha koju iru ẹsun lilu jibiti ti wọn fi kan Hushpuppi, lasiko ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, mu.