Hushpuppi: Kíni àwọn nkán tí kò hàn s'awọn èèyàn nípa arákùnrin tí ọlọ̀pàá Dubai fí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ kàn?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Hushpuppi lorukọ ti ọpọ mọ si ti o si jẹ pe isọwọ fi ọla rẹ han sọ di ilumọọka loju opo ayelujara.

Ṣugbọn ta ni arakunrin ti awọn ọlọpaa ilẹ Dubai ati ọtẹlẹmuyẹ Amẹrika gbe fun ẹsun gbajuẹ olowo iyebiyẹ yi?

Nibo ni wọn ti bi,ta lawọn obi rẹ ati pe bawo lo ti se di ọlọrọ ti awọn eeyan kan n fi ọla rẹ tọrọ ki awọn naa ri bi tiẹ?

Diẹ ree ninu nkan ti a ri ko jọ nipa Hushpuppi

Ilu Eko ni wọn bi si

Ni pato ọjọ ti wọn bi Hushpuppi ti orukọ rẹ gangan n jẹ Ramoni ''Raymond'' Igbalode ko ye wa ṣugbọn bi a ba fi awọn nkan to sọ nipa ara rẹ wo ọrọ yi, ko le ti to ogoji ọdun.

Eyi to sunmọ ootọ ni pe nilu Eko lo dagba si ki o to kuro lorileede Naijiria.

Ninu awọn aworan rẹ nigba to wa ni kekere, a ri ibi to ti duro lara ọkọ nilu Eko ati awọn omiran to tọka si pe o ti gbe Naijiria daada ki o to lọ si ilu okere.

Loju opo rẹ ni Instagram, o tun sọ nipa ọjọ ori rẹ pe oun ti gun oke agba bọ diẹ diẹ wọ ọmọ ọgbọn ọdun.

Loṣu Kẹwa ọdun 2019 lo fi ọrọ yi sita eyi to jẹ ki a lero pe oṣu Kẹwa ni wọn bi.

Ṣe lootọ ni pe o ta bọsikọrọ l'Eko?

O ti ṣe awọn isẹ ọwọ kan ki o to kuro ni Naijiria ṣugbọn a ko ri aridaju lati fidi ọrọ mulẹ iru iṣẹ to jẹ.

Lẹyin ti awọn ọlọpaa Dubai mu tan la bẹrẹ si ni ri aworan orisirisi to se afihan iru iṣẹ to kọkọ bẹrẹ si ni ṣe ki o to kuro ni Naijiria.

Ọkan ninu iṣẹ ti wọn lo ṣe ni pe o jẹ olootu orin ti a mọ si Music Producer ti o si ba awọn olorin Naijiria kọọkan ṣiṣẹ pọ.

Gẹgẹ bi awọn kan ti se sọ, wọn tun ni Ramoni ti ta aṣọ bọsikọrọ nigba to wa l'Eko koda wọn tun sọ wi pe o kọ isẹ foonu ati kọmputa tita ni Computer Village nilu Eko kan naa.

Pẹlu gbogbo nkan ti a ka kalẹ yi, eleyi ti ohun gangan kii ye sọ nipa rẹ ni pe awọn obi rẹ kii se olowo ati pe ohun t'apata dide ni ki ẹlẹda to wa kọdi ọla si ọdọ ohun.

Awọn mọlẹbi rẹ ko foju han lẹyin ti ọwọ tẹ

Wọn ni ọwọ epo lọmọ araye n ba ni la, wọn kii ba ni la ọwọ ẹjẹ.

Ṣaaju ki ọwọ to tẹ Hushpuppi, kii saba sọrọ nipa awọn mọlẹbi rẹ to bẹ loju opo ayelujara.

Yatọ si aworan ko to fi sita nipa ọmọ iya rẹ obinrin to bimọ lọdun 2019 awọn eeyan ko le tọ ka si pe lagbaja tabi tamẹdun ni ọmọ iya Hushpuppi.

Layajọ iya tabi Baba ti a ma si Father's Day ati Mother's Day, Hushpuppi kii kọ nkankannipa awọn obi rẹ debi ti awọn eeyan yoo fi le sọ pe bi awọn obi rẹ ti se ri ree tabi nibi ni wọn n gbe.

Loju opo ẹni to pe ni ọmọ iya rẹ obinrin@ rawflesh_may_9 ko si nkankan nibẹ ni Instagram lati le fi tọka ẹni to n jẹ bẹ.

Bi a ba sọ pe Hushpuppi nikan lo ri ara rẹ lasiko yi ati pe awọn mọlẹbi ko foju han pe eeyan awọn nii ṣe, a ko kuna rara lati sọ bẹ.

Ẹsin wo ni Hushpuppi n ṣe?

Idahun si ibeere yi pin si ọna meji.

Akọkọ ni pe ti a ba fi orukọ abinibi rẹ wo, tii se Ramoni, idile musulumi lo ṣeese ki o ti jade.

Ninu awọn ọrọ kan to fi sioju opo Instagram rẹ, o sọ pe oore ti Allah ṣe fun ohun to ga ju lọ ni pe oun jẹ musulumi.

Lọdun 2012 lo fi ọrọ yi sita ti a ko si le sọ boya o ṣi n ṣe ẹsin Islam titi di igba ti wọn fi mu.

Bi a ba tibi orukọ rẹ to yi pada si Raymond wo, o ti le fi ẹsin Islam silẹ ṣugbọn o le jẹ inagijẹ lasan ni Raymond ki o ma se wi pe o pa ẹsin da.

Bakan naa ninu fọnran fidio kan to fi si oju opo Instagram to ti n wẹ ninu omi iluwẹ igbalode, orin iyin ẹsin Kristẹni ni o n kọ ninu rẹ.

Yatọ si eyi, pupọ awọn nkan to ma n kọ soju opo ayelujara, a ma fi adura to jọ ti Kristẹni sinu rẹ. Gbogbo awọn kan wọn yi ni ko jẹ ki a le sọ boya Kristẹni ni Hushpuppi tabi Musulumi.

Eyi to daju ni pe ati ẹlẹsin Kristẹni ati ẹlẹsin musulumi lo wa ninu awọn eeyan to le ni miliọnu meji to n tẹle loju opo Instagram

Wo bí ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dubai ṣe tẹ Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi

Ramoni Igbalode ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi to fi orilẹ-ede Dubai ṣe ibujoko lasiko yii ni ọwọ awọn agbofinro ilẹ Dubai ti tẹ.

Ninu fọnran fidio 'Fox Hunt 2' ni wọn ti ṣafihan rẹ.

Lọjọbọ ni ileeṣẹ agbofinro dubai fi fidio bi wọn ṣe mu gbajugbaja ori ayelujara Instagram naa sita.

Ọpọlọpọ owo bii owo to wa fun itọju Covid 19 ni Amẹrika ati awọn owo to le ni biliọnu dọla mẹrinlelogun ni wọn ti fi gbajuẹ gba.

Ọlọpaa Dubai ṣalaye bi wọn ṣe mu Hushpuppi ninu atẹjade ti wọn fi sita ti BBC ri.

Wọn ni awọn ti n fura sii ti pe pe o n ṣe awọn 'ọmọ Yahoo'ti wọn n gba awọn eeyan lori ayelujara.

Nibẹ ni wọn ti fi si ori ikanni naa nipa Ramoni Igbalode ati Olalekan Jacb Ponle ti wọn n pe ni 'Woodberry'ati awọn ọmọ ilẹ Adulawọ miran.

Iṣẹ akanṣẹ lati mu awọn ọmọ Yahoo ori ayelujara yii ni awọn agbofinro Dubai pe ni: 'Operation Fox Hunt 2'

Awọn ẹṣẹ bii jiji owo ko lati asuwọn kan si ikeji, jiji owo lori ayelujara, wiwọ akata ayelujara ati eto inawo ẹlomiran lọna aitọ, ṣiṣẹ gbajuẹ fun awọn eeyan ni awujọ ati fun awọn banki ni wọn mu wọn fun.

Ogagun Abdulla Khalifa Al Marri to n tukọ ileeṣẹ ọlọpaa gboriyin fun awọn ọlọpaa Dubai fun iṣẹ takuntakun ti wọn ti fi mu awọn mẹwaa naa.

O ni eyi yoo tun din ole ori ayelujara ati gbajuẹ pẹlu ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa ku diẹ lagbaye lasiko yii.

Ki ni o ti kọkọ ṣẹlẹ lori mimu awọn Invictus àti Hushpuppi

Invictus Obi, Hushpuppi, àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà méjì tí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ wà lọ́rùn wọn

Ajọ to n koju iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC ti ni Ramoni Igbalode, alias Ray hushpuppy ni ẹjọ lati jẹ ni ọdọ wọn.

EFCC to fi eyi lede loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni Hushpuppy is ẹni to gajulọ lorilẹede Naijiria ti wọn n wa bayii fun ẹsun iwa ọdaran lori ẹrọ ayelujara.

Ọjọ kẹ̀wá, Osù Kẹfa ní wọn fí panpẹ́ ọba mú Hushpuppi ní United Arab Emirates lórí ẹ̀sùn lilọ gbajuẹ pẹlu ẹrọ ventilator to le ni $35million.

Ajọ naa ni awọn mọ nipa jibiti owo ati 419 to ṣe ni Niajiria, ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ si ti wa ni panpẹ awọn bayii lorilẹede Naijiria.

EFCC fikun wi pe awọn n ṣiṣẹ pẹlu Ajọ Otẹlẹmuyẹ ilẹ Amerika, FBI titi ọwọ palaba rẹ fi segi.