You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo Crisis: Aṣòfin Iroju Ogundeji, Favour Tomowewo àti Williams Adewale ń lọ rọọkún nílé
Sinima orita awoowotan ni ọrọ adari ile igbimọ aṣofin ati awọn ọmọ ile igbimọ n di lasiko yii ni ipinlẹ Ondo.
Awọn ile igbimo ti dibo wọn si ti ni ki awọn Họnọrebu mẹta o ko kangara ẹru wọn pada si ile.
Awọn aṣofin méta ti wọn ni ki wọn lọ rọọkun nile ni Họnorebu Irọju Ogundeji to jẹ igbakeji adari ile, Họnọrebu Adewale Williams ati Họnọrebu Favour Tomomewo.
- Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara, Adisa Logun ti dágbére fáyé lẹ́yìn tó lùgbàdì àrùn Covid-19
- Fọwọ́ kan obìnrin lọ́nà àìtọ́, kí o rẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá he- Àwọn aṣòfin yarí
- Bí àwọn adarí ìjọba ṣe ń kó Coronavirus, ń kọ wá lóminú - Ìjọba àpapọ̀
- Àkójọ́pọ̀ àwòrán rèé lórí bí ìwọlé akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lọ sí ní Oyo
Ẹsun ti wọn fi kan awọn aṣofin mẹtẹẹta yii ni pe wọn n tapa si ofin ile igbimọ aṣofin.
Bẹẹ, ọrọ lo ko moko-moro wa ni ọrọ ohun to n ṣẹlẹ nile igbimọ aṣofin ati ninu eto oṣelu ipinlẹ Ondo lati bii ọjọ mẹta sẹyin.
Diẹ lara ẹsun ti wọn tun fi kan awọn mẹtẹẹta ni pe:
Wọn ko wa si ipade to igba to yẹ, Gbigba riba tabi ẹbun lọna aitọ lori iṣẹ tabi igbesẹ ile.
Ọmọ ile gbọdọ figba gbogbo maa ṣe ohun to yẹ nigboro ki awọn ara ilu le tubọ nigbagbọ ninu igbimọ ile aṣofin sii.
Aifi ara mọ aba ati awọn ilana ti awọn ọmọ ẹgbẹ fi ẹnu ko le lori.
Aṣòfin Iroju Ogundeji lo jẹ igbakeji adari ile, oun naa lo n ṣoju ẹkun idibo Odigbo 1; nigba ti Favour Semiloore Tomowewo n ṣoju ẹkun idibo Ilajẹ keji; àti Williams Adewale to n ṣoju Ondo West keji.
Igbakeji awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to pọju lọ, Aṣofin Oladiji Adesanmi lo buwọlu lẹta gbe ile rẹ naa pẹlu ifọwọsi abẹnugan ile.
Wọn ti ni ki awọn Họnọrebu mẹtẹẹta yii má rin ni sakani ile igbimọ aṣofin Ondo mọ ni Akurẹ.
Ati pe ki wọn ko awọn ohun to jẹ ti ilu ati tile igbimọ aṣofin gbogbo to ba wa lọwọ wọn sile.
- Kò ní sí ayẹyẹ ọdún Ojúde Oba lọ́dún yìí- Awujale ilẹ̀ Ijebu
- Wọ̀nyí ni àwọn ẹjọ́ tó làmìlaaka ti EFCC ṣe lásìkò Ibrahim Magu
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade ṣe ìgbéyàwó?
- Wo ìgbẹ́sẹ̀ méjọ tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé láti yọ igbákejì gómìnà
- Wo ìgbẹ́sẹ̀ méjọ tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé láti yọ igbákejì gómìnà
Awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to ku ti wọn fọwọ si aṣẹ lọ rọọkun nile awọn akẹgbẹ wọn ni orukọ ati ibuwọlu wọn hande loke yii.
Kini awọn ẹsun to kọkọ ṣaaju ni ipinlẹ Ondo:
Akeredolu, aya àti ẹbí rẹ̀ ló ń ṣèjọba ni mo ṣe fipò sílẹ̀ - Akọ̀wé ìjọba tẹ́lẹ̀ l'Ondo
Akọ̀wé ìjọba tẹ́lẹ̀ ní irọ́ ni, òun kò sọ pé èrú ìbò ló gbé Akeredolu wọlé
Ọjọ Aje ni awọn ileesẹ iroyin kan gbe iroyin sita pe, akọwe ijọba nipinlẹ Ondo to kọwe fipo silẹ naa, Ifedayo Abegunde, ti kede pe, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu kọ lo wọle ibo gomina to gbe depo.
O ni awọn ba Akeredolu se magomago ibo, lati jẹ ko moke ninu idibo naa ni.
Eyi si lo mu gomina Akeredolu kesi awọn agbofinro lati gbe akọwe ijọba ana naa, ki wọn lee fi ọrọ wa lẹnu wo lati seranwọ ninu iwadi ẹsun mago mago naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń bèèrè owó lọ́wọ́ àwọn Alfa lórí ìsìnkú ẹni tó pokùnso
- Hushpuppi di gbajúmọ̀ ẹlẹ́wọ̀n tó ní nọ́ńbà l‘Amẹrika, orúkọ̀ rẹ̀ wà lórí ayélujára
- Nǹkan tí ojú rí rè é bí pápákọ̀ òfurufú ṣe di ṣíṣí padà ní Nàìjíríà
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade ṣe ìgbéyàwó?
- Kòṣẹlẹ̀rí ni Hajj ọdún 2020, wo ìyàtọ̀ tó wà nínú rẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀
Idi si ree ti BBC Yoruba fi kan si akọwe ijọba tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Ifedayo Abegunde, lati wadi okodoro ọrọ nipa isẹlẹ naa.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Abegunde ni irọ gedegbe ni ọrọ naa, oun ko si fi igba kankan kede pe magomago abi ayederu ni ibo to gbe gomina Akeredolu wọle lọdun 2016.
"Mo fẹ sọ pe nkan ti awọn oniroyin gbe naa nipa mi kii se otitọ.
Ohun ti mo sọ ni pe ẹgbẹ APC to jawe olubori ninu ibo taa di lọdun 2016 nipinlẹ Ondo pegede, debi pe awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to jẹ alatako gan ko lee lọ sile ẹjọ."
" Mo ni Akeredolu nikan kọ lo bori eto idibo naa, mo ni awa taa jẹ akọni oselu, awọn asoju ẹgbẹ ati araalu la dijọ sisẹ taa fi bori ibo naa.
Kii si se gomina nikan lo da bori ibo yii, idi si niyi ti ko fi yẹ ki oun, iyawo ati awọn ọmọ rẹ maa danikan maa se ijọba, bikose gbogbo awa taa sisẹ to fi moke, lo jẹ ka dijọ se ohun to wa nilẹ yii."
Lori igbesẹ gomina Akeredolu pe ki awọn agbofinro gbe sahamọ lori ẹsun sise magomago ibo to fi kan oun, Abegunde ni ẹni to ba jẹ gbi, ni yoo ku gbi.
O ni ẹẹmeji ni oun ti lọ soju ipinlẹ Ondo nile asoju-sofin nilu Abuja, ti oun ko si ko owo jẹ, ipo ti Akeredolu si fi oun si, oun ko ri owo kankan nibẹ debi pe oun yoo ko owo jẹ nibẹ, ki wa ni agbofinro fẹ gbẹ oun si?
Akọwe ijọba tẹlẹ nipinlẹ Ondo naa ni, oun kọwe fi ipo naa silẹ nitori oun ko fẹ ba gomina Akeredolu sisẹ mọ ni.
Amọ o ni oun si wa digbi ninu ẹgbẹ oselu APC nitori ẹgbẹ gbogbo awọn ni, ẹgbẹ ti oun nifẹ si ni, kii si se ẹgbẹ Akeredolu nikan.
Nigba to n salaye boya otitọ wa ninu ọrọ kan to n ja rainrain nilẹ pe, oun naa fẹ fi ẹgbẹ oselu APC silẹ lati lọ dije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oselu miran.
Abegunde ni oun ko dije fun ipo kankan rara nitori awọn to n dije ninu ẹgbẹ APC gan pọ.
"Oluwarotimi Akerdolu ko tọju ẹgbẹ ati awọn ọmọ ẹgbẹ daadaa, o si wu mi pe ki wọn gbe ẹlomiran sita lati rọpo rẹ, ti yoo se daada ju bi Akeredolu ti se lọ.
- Bí Hushpuppi ṣe tiraka rèé l‘Eko, kí ọlà ‘òjijì’ tó dé
- Akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà, ìjọba Oyo kò pèsè ìbòmú lòdì sí ìlérí rẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
- Kàkà k‘éwé àgbọn dẹ̀ lágbo òṣèlú l‘Ondo, akọ̀wé ìjọba tún kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
Ti temi ni pe ki n duro sinu ẹgbẹ APC, ki n si maa tọpinpin awọn ti yoo dije ninu awọn oludije ẹgbẹ wa.
Ti wọn ba si fa ẹlomiran silẹ ko dije ninu ẹgbẹ wa, yatọ si Akeredolu, a jọ maa se e daadaa ti yoo fi wọle, ti yoo si se daadaa ju bi Akeredolu ti se bayii lọ."
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti jajabọ lọwọ arun Coronavirus.
Akeredolu lo fi ọrọ naa lede nigba to n jabọ ibi iṣẹ de duro lori bi ipinlẹ naa ṣe n gbogun ti ajakalẹ arun ọhun lọjọ Aje.
O ni "Gẹgẹ bi gbogbo yin ṣe mọ, emi naa jẹ ọkan lara awọn eeyan to ni arun Covid-19, ti mi o si ṣafihan apẹrẹ arun naa."
"Lẹyin ti mo lo ọjọ diẹ ni idanikanwa ni mo ṣe ayẹwo miran gẹgẹ bi agbekalẹ ajọ NCDC, iṣẹju diẹ sẹyin ni mo gba esi ayẹwo naa, to si fi han pe mi o ni arun ọhun mọ."
Akeredolu sọ pe ọjọ diẹ ti oun lo ni igbele fun oun laye lati ro arojinlẹ lori awọn ipenija ti Covid-19 mu ba ipinlẹ Ondo.
Lọwọ yii, irinwo le mẹrindinlọgọta eeyan lo ti ni arun naa ni ipinlẹ Ondo.
Ọgbọn ọjọ oṣu Kẹfa ọdun 2020 ni gomina ọhun kede pe oun ti ti lugbadi arun naa, lẹyin ọjọ diẹ si ni kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ ọhun, Wahab Adegbenro dagbere faye.
Ifedayo Abegunde kọ̀wé fipò sílẹ̀ bíi akọ̀wé ìjọba
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti kede pe akowe ijọba ipinlẹ Ondo, Ifedayo Abegunde ti kọwe fi ipo rẹ silẹ.
Abegunde fi eyi lede ninu atẹjade kan to fi si oju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.
Abegunde ni ikọwe fi ipo silẹ ọhun yoo bẹrẹ ni Ọjọ Kẹfa, Oṣu Keje, ọdun ti a wa yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa lo dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu to fun oun ni ore ọfẹ ati ṣiṣẹ fun ipinlẹ naa.
Abegunde wa gbadura pe ilera pipe yoo jẹ ti gomina ipinlẹ Ondo naa.
Bẹẹ ba gbagbe, o to ọsẹ meji ti igbakeji gomina nipinlẹ Ondo yii kan naa, Agboola Ajayi, kuro ninu ẹgbẹ oselu APC to n se ijọba lọwọ nibẹ, lọ sinu ẹgbẹ alatako PDP.
Bi o tilẹ jẹ pe Agboola si di ipo rẹ mu bii igbakeji gomina, sibẹ iroyin fi ye ni pe, awọn ọgọọrọ oloselu kan ti n ya lọ ba ninu ẹgbẹ oselu alatako naa.