You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kwara Coronavirus death: Aminu Adisa Logun ti d'olóògbé lẹ́yìn tó lùgbàdì àrùn Covid-19
Olori oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Kwara, Aminu Adisa Logun ti dagbere faye lẹni ọdun mẹtalelaadọrin lẹyin to lugbadi arun Covid-19.
Akọwe ijọba ipinlẹ naa, Rafiu Ajakaye lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣowọ si BBC Yoruba.
Atẹjade naa ni "Logun jẹ ipe Eledumare lalẹ ọjọ Iṣẹgun lẹyin wakati diẹ ti esi ayẹwo fi han pe o ti ni arun Covid-19."
O tẹsiwaju pe ijọba atawọn eeyan ipinlẹ Kwara ti padanu ẹni iyi to sin ijọba ipinlẹ ọhun pẹlu gbogbo ọkan rẹ ki ọlọjọ to de.
Iṣelẹ yii ti mu ki gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq kede ọfọ ọjọ meje lati fi ṣedaro oloogbe ọhun.
Lẹyin naa lo ni gomina ọhun ba ẹbi olori oṣiṣẹ ijọba tẹlẹri naa ati gbogbo awọn olugbe ilu Ilorin kẹdun iku rẹ.
Akọwe ijọba pari atẹjade naa pe awọn ẹbi oloogbe naa atri ijọba yoo kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ laipẹ.