Aiyedatiwa jáwọ́ nínú ẹjọ́ tó pé ilé aṣòfin Ondo lórí ìyọ́ní nípò rẹ̀, ìdí réè

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo , Lucky Aiyedatiwa, ti jawọ ninu ẹjọ to pe ile aṣofin ipinlẹ naa eyi to gbe lọ siwaju ile ẹjọ giga Abuja.

Lọjọ Aje lo gbe igbesẹ lati jawọ ninu ẹjọ eleyi to pe ṣaaju ni itako iyọni nipọ rẹ ti ile aṣofin ipinlẹ Ondo bẹrẹ igbesẹ le lori.

Yatọ si ile aṣofin to pe lẹjọ yi ti nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/1294/2023,

Gomina,Olori ile Adajọ agba,Kọmiṣana Ọlọpaa Ondo ati adari ajọ Ọtẹlẹmuyẹ DSS naa pẹlu awọn to jijọ pe lẹjọ.

Nibi igbẹjọ to waye lọjọ Aje agbẹjọro Aiyedatiwa Ọgbẹni Ebun-olu Adegboruwa (SAN), sọ fun ile ẹjọ pe o wu lati yọwọ ninu ẹjọ yi lẹyin ti awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress,APC da si aawọ to n waye laarin ohun ati Gomina.

Agbẹjọro agba yi sọ pe alaga ẹgbẹ APC Abdullahi Ganduje ti ṣe agbekalẹ igbimọ ti yoo yanju aawọ laarin awọn to pe lẹjọ yi lọjọ Kẹfa oṣu Kẹwaa

Adegboruwa sọ pe titẹsiwaju pẹlu igbẹjọ yi yoo ṣe akoba fun ipẹtusaawọ ti awọn olori ẹgbẹ n gbe igbesẹ rẹ.

Bẹẹ naa lo tọka si pe ile aṣfin ipinlẹ Ondo kọ iwe ẹhonu si igbimọ to n ṣe akoso awọn adajọ ni Naijiria lọjọ Kẹta oṣu Kẹwaa ni itako si adajọ Emeka Nwite to n gbẹjọ ọhun.

O rọ ile ẹjọ lati ṣe suuru de esi iwe ẹhonu yi ki wọn to tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ to wa nilẹ.

Rara,igbẹjọ gbọdọ tẹsiwaju-agbẹjọro Akeredolu fariga

Ninu atako si ohun ti agbẹjọro Aiyedatiwa sọ, agbẹjọro ti Gomina ipinlẹ Ondo Kazeem Gbadamosi (SAN), ati ti adajọ agba ipinlẹ Ondo, Mutalib Ojo (SAN), sọ fun ile ẹjọ pe awọn ko faramọ nkan ti o sọ ati pe awọn rọ ile ẹjọ lati tẹsiwaju igbẹjọ naa.

Agbẹjọro ile aṣofin Femi Emodarimo sọ pe ile aṣofin ipinlẹ Ondo ti ṣaaju kọ iwe ẹhonu kotẹmilọrun ni itako adajọ to n gbẹjọ yi.

Ninu idajọ to gbe kalẹ, adajọ Nwite sunjọ itẹsiwaju igbẹjọ naa di ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa.

Koko ẹjọ ti Aiyedatiwa pe ni pe oun fẹ ki ile ẹjọ paṣẹ ki Akeredolu ati awọn to n ṣiṣẹ fun jawọ nidi idunkoko mọ ohun tabi tita abuku oun lasiko toun ba n ṣe iṣẹ rẹ gẹgẹ bi igbakeji Gomina.

Ile ẹjọ ti buwọlu lu ibeere rẹ to gbe wa siwaju adajọ ti o si sun igbẹjọ di ọjọ Aje to n bọ lati le gbọ awọn koko to wa ninu ọrọ naa.