You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yollywood: Odunlade fẹ́ j'ọba, Bolanle Ninalowo fun ìyàwó rẹ̀ ni ẹ̀bun kanka, Pá Kasumu rebi àgbà ree
Ninu awọn iroyin to migboro titi lagbo oṣere tiata Yoruba bawọn kan ṣe n pawọpọ fi gbe ere sita ni idile awọn oṣere miran n bawọn daawọ idunnu ayọ ọjọ ibi.
Ki a ma deena pẹnu rara, diẹ re lara awọn iṣẹlẹ to jẹyọ nigbesi aye awọn oṣere tiata Yoruba ni Naijiria rèé.
Oya, jẹ ka ma mu wọn lọọkọọkan.
Odunlade fẹ jẹ ọba ni ilu rẹ?
Bi ere bi ere ni iroyin yi ṣe bẹrẹ ṣugbọn ka to diju ka to ya, o ti di nkan tawọn eeyan n ṣalabapin rẹ kaakiri ayelujara.
Ilumọọka arẹwa oṣerẹ ọkunrin nii Odunlade Adekola jẹ ọmọ bibi ilu Ọtun Ekiti ti a si gbọ pe ile ọba lo ti wa, ọmọ oye si ni pẹ̀lú.
Ni nkan bi ọjọ meloo kan sẹyin lawọn kan ni awọn afọbajẹ ti kan sipe ko wa jẹ ọba ilu rẹ ṣugbọn oṣere naa ko ti sọ nipa rẹ.
Amọ ṣa ninu ifọrọwerọ kan ti BBC ṣe pẹlu aarẹ oṣere tiata labẹ asia TAMPAN Bolaji Amusan Mr Latin, ni Odunlade fi ọrọ naa lọ ohun lootọ ṣugbọn o ni ohun ko ti mọ boya ki ohun jẹ oba tabi ko ma jẹ.
Ekunrẹrẹ fidio ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Mr Latin wa nibi yi.
Bolanle Ninalowo fi ile ta iyawo rẹ lọrẹ
Loju opo Instagram Bolanle Ninalowo ni ofi ikede ẹbun ile to fi ta iyawo rẹ lọrẹ si.
Ile naa eleyi to ni oun fun Bunmi Ninalowo jẹ eleyi tiileeṣẹ kan fun un.
Lọdun 2018 ni Bolanle Ninalowo ati iyawo rẹ ti wọn yara wọn lati nkan bi ọdun mejila pada gẹgẹ bi tọkọtaya.
Orileede Amẹrika ni iyawo rẹ n gbe ni gbogbo igba ti wọn tuka.
Pa Kasunmu faye lẹ
Gbajugbaja oṣere tiata Kayode Odumosu ti gbogbo eeyan mọ si Pa Kasumu lọsẹ yi dagbere faye.
Lọjọ Aiku ni aarẹ awọn oṣere tiata Yoruba Naijiria, Bolaji Amusan Mr Latin fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC Yoruba.
O ti to ọjọ mẹta ti aisan ti n ba Pa Kasunmu finra.
Ọpọ awọn oṣere lo fi ọrọ ibanikẹdun si oju opo wọn lati fi ṣe iranti agba ọjẹ adẹrinposonu yii.
Wọn sun ọjọ ti sinima Fate of Alakada yoo jade
Awọn ololufẹ Toyin Abraham ati Broda Shagi to ti n foju sọna sinima Fate of Alakada yoo ni lati ṣe suuru diẹ.
Idi ni pe wọn ti sun ọjọ ti sinima naa yoo jade siwaju .
Toyin Abraham fi ikede yi sojuopo Instagram rẹ to si ni ki awọn ololufẹ ohun ma foya nitori pe ọjọ naa de tan loju ẹlẹmi.
Tẹbi tọrẹ ki KWAM 1 fayẹyẹ ọjọ ibi
Ọdun 1957 ni wọn bi gbaju-gbaja akọrin Fuji, Olasunkanmi Wasiu Ishola Anifowoshe, ti ọpọ eeyan mọ ọ si Wasiu Ayinde.
Ọdọ oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ni Wasiu Ayinde ti bẹrẹ isẹ gẹgẹ bi ẹni to maa n ba ẹgbẹ akọrin rẹ ko irinṣẹ.
O ṣiṣẹ pẹlu ẹgbẹ akọrin Barrister, Supreme Fuji Commander, laarin ọdun 1975 si 1978.
Ọjọ kẹta oṣu Kẹta ọdun 2020 ni o pe ẹni ọdun kẹtalelọgọta.