Yoruba Films: Femi Adebayo sọ ẹran àgbò rẹ̀ lórúkọ tuntun, Bukky Wright ṣ'ọjọ ìbí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajakalẹ aarun coronavirus le wa nita ni tootọọ, amọ aarun naa ko ni kawọn oṣere tiata Yoruba ma ṣe ti wọn.

Wọnyii ni awọn ohun to ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere tiata Yoruba, Yollywood lọsẹ yii.Bi awọn kan ṣe n yọ ayọ ọjọ ibi, lawọn kan n palẹmọ fun ti wọn naa, bakan naa lawọn oṣere kan ko sai mẹnu ba ọrọ coronavirus gan an.

1. Bukky Wright

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni gbajugbaja oṣere, Bukky Wright ṣe ayẹyẹ ọ̀jọ ibi rẹ.Bukky dupẹ lọwọ Eleduwa to jẹ ko ri ọdun miiran laye. Arẹwa oṣere naa ki ara rẹ ku ọjọ ibi loju opo Instagram rẹ.

2. Lizzy Anjorin

"Owo, ọmọ, alaafia ati ẹmi gigun ni mo beere."Orin ti Lizzy Anjorin fi bọnu niyii loju opo Instagram rẹ.Lizzy gbe ọrọ coronavirus si ẹgbẹ kan papaa julọ bi o ti n palẹmọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

3. Mercy Aigbe

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni Mercy Aigbe gboṣuba rabandẹ fun ni tiẹ.Mercy rọ gbogbo eeyan lati lo asiko yii ki wọn fi gboriyin fawọn oṣiṣẹ eleto ilera to n tọju awọn to lugbadi aarun corona virus.O ni oun mọ riri iṣẹ ribiribi ti wọn n ṣe lasiko yii.

4. Femi Adebayo

Femi Adebayo ni tiẹ sọ pe jijoko sile lasiko coronavirus yii ti su oun.Koda awọn ẹran agbo rẹ lo n ba ṣere nile ti o si fi fidio rẹ sori oju opo Instagram rẹ.Femi Adebayo ni oun tiẹ ti fun awọn ẹran agbo oun lorukọ tittun