Kí ló tún fàá tí ìtàkùn iná mọ̀nàmọ́ná àpapọ̀ tún da'ṣẹ́ sílẹ̀ ní Nàìjíríà?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ojú opo ina mọnamọna apapọ lorilẹede Naijiria ti kọṣẹ silẹ lọjọ Ẹti. Eyi si ni yoo jẹ igba akọkọ ti eyii yoo waye lọdun 2026 lẹyin ti irufẹ iṣẹlẹ ikọṣẹsilẹ ina mọnamọna naa waye ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2025.

Gẹgẹbi ohun tawọn alaṣẹ ileeṣẹ to n pin ina lorilẹede Naijiria sọ̀, agbara ina to wa ninu aka ipinna mọnamọna ja lati ẹgbẹrun mẹrin abọ mẹgawaati bọ si mẹgawaati mẹrinlelogun ni nnkan bii agogo kan abọ ọsan.

Iroyin sọ pe gbogbo awọn ileeṣẹ apinna to so rọ mọ itakun ina naa ni wọn ṣiwọ iṣẹ.

Latari eyii ileeṣẹ apinna ọba (DISCOs) mọkanla ni ko ri ina ti wọn le pin fun araalu.

Ko tii si ẹni to le sọ ni pato ohun to ṣokunfa rẹ, bi o tilẹ jẹwi pe ọpọ igba lawọn onimọ ti di ẹbi irufẹ iṣẹlẹ bayii latẹyinwa ru aisi atunṣe to peye lori awọn ina ọba, ati aisi agba ina to kun oju iwọn to

Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, awọn alaṣẹ ipese ina mọnamọna ni igbesẹ ti n waye lati da ina pada si oju opo awọn ileeṣẹ apinna kọọkan lati le pese ina fun awọn onibara wọn jakejado Naijiria.