Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà ṣèpàdé lórí ètò àbò, ohun tí Amẹ́ríkà sọ nípa ìkọlù míràn lórí àwọn agbébọn àtàwọn kókó tó jẹyọ níbẹ̀ nìyí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà ti ṣe ìpàdé àkọ́kọ́ lórí ètò ààbò èyí tí Ààrẹ Amẹ́ríkà kéde nínú ọdún tó kọjá pé ó jẹ́ ohun ìkọnilóminú.

Ní ìlú Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ìpàdé àkọ́kọ́ náà ti wáyé lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026.

Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025 ni Trump kéde pé Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tí òun fi ojú sí lára pẹ̀lú ẹ̀sùn pé wọ́n ń pa àwọn ọmọlẹ́yìn pẹ̀lú èròńgbà láti pawọ́n run àmọ́ ìjọba Nàìjíríà ti jiyàn ẹ̀sùn náà.

Lẹ́yìn náà ni Trump dúnkokò láti ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà, tó sì ṣèkọlù sáwọn agbéṣùmọ̀mí nínú igbó Bauni ní ìjọba ìbílẹ̀ Tangaza, ìpínlẹ̀ Sokoto.

Láti ìgbà náà sì ni ìjọba Nàìjíríà ti kéde láti jírorò pẹ̀lú ìjọba Amẹ́ríkà lórí àwọn ẹ̀sùn náà.

Kókó ìpàdé náà

Níbi ìpàdé tó wáyé lọ́jọ́bọ̀ ní ìjọba Nàìjíríà ti wá kéde pé àjọṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì ni àlékún ti bá báyìí lójúnà àti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà, Mínísítà fẹ́tò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ ní Nàìjíríà, Mohammed Idris sọ pé ìpàdé náà wáyé láti lè jẹ́ kí àlááfíà jọba káàkiri gbogbo ibi tí wàhálà àti ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ń wáyé ní Nàìjíríà.

Idris sọ pé ìgbésẹ̀ náà ṣàfihàn akitiyan ìjọba láti mú àlékún bá ìbáṣepọ̀ lórí ètò ààbò láàárín àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì.

Ìpàdé náà tó jẹ́ àjọṣepọ̀ Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà Joint Working Group ni olùbádámọ̀ràn ààrẹ Tinubu, Nuhu Ribadu àti akọ̀wé ìjọba Amẹ́ríkà lórí ètò ìṣèlú, Allison Hooker darí rẹ̀.

Idris ní àjọṣepọ̀ láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì ti so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso rere.

"Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ wọn ní Amẹ́ríkà láti fi ìmọ̀kúnmọ̀ tó fi mọ́ àwọn ológun tó ń ṣiṣẹ́ ní Operation Hadin Kai àti Operation Fasan ní ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà.

Ó fi kun pé ìfarajìn náà ló jẹ́ kí Amẹ́ríkà jẹ́jẹ̀ẹ́ láti láti máa pèsè ohun èlò ìjagun fún Nàìjíríà fún ọdún márùn-ún báyìí tó fi mọ́ ìpèsè àwọn ohun èlò ojú òfurufú.

"Mo fẹ́ kí àwọn mọ̀ Nàìjíríà mọ̀ pé ìbáṣepọ̀ láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì ń so èso rere, tó sì máa tẹ̀síwájú láti máa rí bẹ́ẹ̀."

Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀

Nínú àtẹ̀jáde iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà ní Nàìjíríà fi sójú òpó ayélujára wọn sọ pé àfojúsùn àjọṣepọ̀ tó ń wáyé náà ni láti mú àdínkù bá ìkọlù sáwọn ikọ̀ tí kò lẹ́ni tí yóò jà fún wọn pàápàá àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi.

Àtẹ̀jáde náà ní àwọn fẹ́ pèsè ààyè fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti lè ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n láì sí ìbẹ̀rù ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí, agbébọn tàbí àwọn ọ̀daràn míì.

Amẹ́ríkà ní àwọn ní gba ìlànà tí Nàìjíríà fẹ́ lò láti àtúnṣe bá ètò ààbò wọlé pàápàá ní ẹkùn ààrin gbùgbùn àríwá Nàìjíríà.

Wọ́n ní ibi ìpàdé náà ni wọ́n ti fénukò pé ìpàdé míì tí yóò bá wáyé máa jẹ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà lẹ́yìn tí ikọ̀ méjéèjì bá ti fẹnukò.