Unai Emery: Àwọn olólùfẹ́ Arsenal ní Emery gbọdọ̀ fipò rẹ̀ sílẹ̀ dandan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ina ti jo dori koko bayii fun akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Unai Emery.

Ọgọrọ awọn ololufẹ Arsenal ni wọn yabo oju opo ayelujara papaajulọ Twitter, nibi ti wọn ti sọ pe ki Emery kọwọ fipo rẹ silẹ tabi ki Arsenal juwe ile fun un.

Agidi ni Arsenal fi gba ọmọ alayo meji si meji pẹlu ikọ agbabọọlu Southampton lopin ọsẹ to kọja ninu idije Premier League.

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa lawọn ẹgbẹ alatilẹyin Arsenal kan sọ fun awọn alaṣẹ ikọ Arsenal pe ki wọm fọwọ osi juwe ile fun Emery.

Ipo kẹjọ ni Arsenal wa bayii lori tabili idije Premier League eleyi to jẹ ki ọpọ alatilẹyin Arsenal maa kọminu.

Ẹgbẹ naa ṣalaye pe awọn eeyan bi ọgọrun un mẹfa lo ti kọwọ bọwe pe ki Emery dagbere fun Arsenal.

Bakan naa lọpọ eeyan loju opo Twitter n sọ pe o ti to asiko fun Emery lati fipo rẹ silẹ.

Ọpọ lo n sọ pe kawọn alaṣẹ Arsenal gba Massimiliano Allegri tabi Mauricio Pochettino lati rọpo Emery gẹgẹ bi akọnimọọgba Arsenal.