You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dangerous Animal: Ẹ wo àwọn ajá mẹ́wà tó máa ń hùwà ipá tí ẹ kò gbọdọ̀ sìn nílé
Aja yẹ ko jẹ ọrẹ fun awọn to fẹran rẹ, amọ awọn aja kan wa to le se ipalara fun awọn eniyan to ba n sin wọn.
Awọn aja miran wa ti wọn ma n hu iwa ipa , ti wọn si le e bu eniyan jẹ nigbakuugba to ba wu wọn eyi to jẹ ewu nla.
O pọn dandan ki eniyan mọ iru ẹya aja ti a lee sin ninu ile lati le daabo bo awọn to wa ni agbegbe naa.
Ẹ wọ orukọ awọn aja ti ẹ gbọdọ yẹra fun:
Aja Bullmastiff:
O jẹ ẹya aja ti yoo le eniyan lere nitori bi o se tobi to, ẹrujẹjẹ ni, to si le pa eniyan.
German Shepherd:
Aja yii ma n pa awọn aja kekeke to ba sun mọ. O ma n wuwa ipa, o si ma n tobi, awọn ọlọpaa ma n lọ wọn fun isẹ wọn.
Rotweilers:
Ẹya aja yii naa jẹ eyi to wọpọ laarin awọn eniyan, amọ to loro lara pupọ ju. Ẹnikẹni ti ko ba kọ aja yii daadaa, o le e lugbadi ipalara lati ọwọ aja yii.
Aja Pitbulls:
Pitbulls lo buru ju ninu gbogbo aja ti eniyan ko gbọdọ gbe sile, ti o si ti pa ọpọlọpọ eniyan kaakiri agbaye. nitori naa ni won se gbegile rira aja yii lai gba asẹ ijọba.
Aja Bully Kutta tabi Mastiff:
Irufẹ aja yii jẹ aja to le lati kọ lẹkọ, ti o si ma n wuwa ipa, nitori naa wọn ma n lo lọpọ igba fun aja ti wọn ma fi n ja ni.
Aja Akita:
Eyi jẹ aja ti ko buru pupọ, amọ o jẹ aja to gboju, ti eniyan gbọdọ kọ ni ẹkọ.
Aja Boxer:
Ohun naa jẹ aja ti kii ja kikankikan, amọ ọpọlọ rẹ pe, nitori naa wọn ki n tete tẹle ohun ti olowo wọn ba sọ fun wọn.
Great Danes:
O jẹ aja to tobi to si ma n jẹ ibẹru fun awọn eniyan, ti wọn ko ba kọ aja naa daadaa, o le se ipalara fun wọn.
Wolf Hybrid:
Gẹgẹ bi a se mọ wi pe awọn aja wa lati ara ikooko, amọ awọn eniyan kan si n gbe aja gun ẹya ikooko, eleyii ti o mu won buru si.
Orilẹede Amerika tilẹ ti fofin de e ki enikeni ma sin iru aja bẹẹ nitori o ti pa, o kere tan, eniyan merindinlogun lorileede naa.
Chow Chows:
O jẹ ẹya aja to fẹ̀ran olowo wọn, ti o si ma n kọju ija si ẹnikẹni to ba gbẹna woju olowo rẹ.