You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Witches Conference: Àjọ PFN kéde àdúrà ọjọ́ méjì láti tako àpérò àwọn àjẹ́
Ajọ awọn kristẹni, PFN ti tako apero agbarijọpọ awọn ajẹ ti yoo waye lọsẹ yii ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Nsukka nipinlẹ Enugu.
Ajọ PFN sọ pe ewu nla wa nibẹ ti awọn ajẹ ba ṣe bẹẹ ṣe apero wọn gẹgẹ bi wọn ṣe n gbero.
''A ko le fọwọ leran ki a jẹki ohun ti ko f'ogo fun Ọlọrun, to si tun le ṣakoba fun ọjọ iwaju ṣẹlẹ nipinlẹ Enugu,'' alaga ajọ PFN Bisọbu Godwin Madu, lo woye bẹẹ.
- Àmúwá Ọlọ́run lásán ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Iba-Eburu Iba Oba Okunoye
- Ó gbẹnután! Ìyá dú ọmọ rẹ̀, o yíi láta, ó sì tún jòkó jẹ ẹ́
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Pasuma kìí ṣe ọkọ mi o! Lanre Kuti ni mo fẹ́ - Jaiye Kuti
- Oúnjẹ márùn-ún tó lè ṣekú pa'ni kíákíá
- Ẹ yé parọ́ kiri! Mi ò gbèrò láti lọ fún sáà kẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ààrẹ - Buhari
- Ọmọ Nàìjíríà yarí lórí àbá láti mójútó ayélujára, ilé aṣòfin láwọn ń tẹ̀síwájú lórí ẹ̀
Alaga ajọ PFN rọ alakoso fasiti ti wọn ti fẹ ṣe apero naa, Ọjọgbọn Charles Igwe wi pe ko ma ṣe gba wọn laye, bi ko ba fẹ ri ibinu Ọlọrun.
Biṣọbu Godwin ṣalaye pe ajọ PFN ti kede ọjọ meji bayii fun akanṣe adura lati rii pe apero naa ko waye.
O fikun ọrọ rẹ pe oriṣiiriṣii iṣẹlẹ ti ko fi ogo Ọlọrun han lo ti n ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria tẹlẹ, nitorinaa awọn onigbagbọ gbọdọ gbadura lati tako apero ọhun.
Alaga PFN sọ pe ''ọwọ Ọlọrun ni ipinlẹ Enugu wa, nitorinaa a ko ni gba ko di ipinlẹ tawọn ajẹ yoo jẹ gaba le lori.''
Biṣọbu Godwin ni gbogbo awọn onigbagbọ gbọdọ ke pe Ọlọrun ninu adura bayii pe ko wa ja ni Naijiria nitori orukọ rẹ.