You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Killer Mum: Kí ló lè mú kí ìyá pa ọmọ rẹ̀ sè jẹ?
Awọn alaṣẹ lorileede Tanzania ti ni ki awọn oṣiṣẹ ijọba agba tẹ ọkọ leti ni kiakia, lati lọ foju ri oun to n ṣẹlẹ labule kan lẹyin ti iroyin kan pe obinrin kan pa ọmọ rẹ jẹ.
Gẹgẹ bi ohun ti akọroyin BBC jabọ, wọn ni labule Mavanga ni obinrin naa ti fi ọbẹ du ọmọ rẹ, to si se e, ki o to wa bẹrẹ si ni jẹ.
Awọn agbofinro ti mu obinrin naa ati ọkọ rẹ, lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.
Emmanule Ngalikakwa to jẹ kansilọ agbegbe naa ṣalaye fun akọroyin BBC ohun ti obinrin naa sọ fawọn aṣaaju abule.
O ni nigba ti wọn kọkọ beere ọrọ lọwọ obinrin naa, o ni oun ju oku ọmọ naa si inu ṣalanga ni lẹyin toun pa.
Ni igba ti wọn tẹ ninu daada, o yi ọrọ pada to si sọ pe, okuta nla loun fi fọ ọmọ naa lori, ki ohun to gbe oku rẹ lọ si inu igbo.
Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, nigba to de inu igbo to sọ, obinrin naa sọ fun wọn pe, oun du ọmọ naa, ki oun to ge wẹlẹwẹlẹ ti oun si se jẹ.
Ko ti daju boya arun ọpọlọ n damu arabinrin naa ṣugbọn awọn ọlọpaa ni o yẹ ki iwaadi awọn sọ ohun to mu ki obinrin ọhun hu iru iwa bẹẹ.