You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Jaiye Kuti lu àwọn aláṣìmọ̀ lọ́gọ ẹnu lórí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Pasuma
Lootọ kii ṣe ajoji ki ibaṣepọ maa wa laarin oṣere meji lagbo awọn oṣere ṣugbọn ni Jaiyeola Kuti, o ni ohun ti wọn n ro si oun ko jọ ọ rara.
Iwoye awọn ololufẹ ere ori itage eyi to si ti tan kanlẹ gidi gan ni pe Pasuma ati Jaiye n fẹ ara wọn, eyi si tilẹ ti di igbagbọ ọpọlọpọ.
Awọn kan ni bi wọn ba ti tẹ ẹ sori ẹrọ aṣewadii google lati mọ ẹni to jẹ ọkọ rẹ, aworan olorin Pasuma lo ma n jade sita pupọ.
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Toyin Abraham ní 'gbogbo wa loníbárà', Ijebu ta sí Odunlade
- Ọ̀nà kan ò wọjà fáwọn òṣèré tíátà, bí wọn ṣe ń ta ìpara ìbóra ni wọ́n ń ta aṣọ ẹbí
- Funke Akindele, oníròyìn, agbẹjọrò àti òṣèré; ohun tí ẹ kò lérò nípa rẹ̀
Ẹwẹ, bi Jaiye ṣe wa fi sita gbangba gbangba bayii pe Lanre Kuti lorukọ ọkọ toun o kii ṣe Pasuma fun ọpọlọpọ eeyan ni ifọkanbalẹ lori ohun to ti n ja nilẹ kiri tẹlẹ yii.
Jaiye ṣalaye pe lati igba ti oun ti ṣe agbejade ere ti akọle rẹ jẹ "Jaiye Monje" to si ni ọpọlpọ aworan igbeyawo laarin oun ati Pasuma ninu ere naa ni ọpọlọpọ ro pe aworan igbeyawo rẹ ni lootọ.
"Fiimu lásán ni o. Idile Kuti ni mo ti lọ́kọ̀ latinu ọgbọnjọ, oṣu ikẹjọ ọdun 2000. Emi ko fẹ Pasuma o.
Ṣe lori ọrọ yii abomii?
Nibi ti awọn ololufẹ ffimu Yoruba ati awọn ololufẹ Jaiye Kuti gan funra rẹ fẹ mọ ohun to wa nidi ọrọ yii de, ṣe ni gbogbo wọn bẹrẹ si ni tẹnu bọ ọrọ ọpẹ.
Kete ti Jaiye fi ọrọ aridaju pe oun ati Pasuma ko fẹ ara wọn sita lawọn eeyan n fesi loju opo rẹ pe awọ́n dupẹ pupọ pe o ẹkunrẹrẹ alaye ọrọ naa sita.
Awọn kan ni ọkan awọn ti balẹ bayii, ẹnikan ti igbeyawo rẹ pẹlu Lanre Kuti naa sọ tẹnu rẹ bẹ́ẹ̀ si ni
Bakan naa ni awọn mii ni ṣe ni ko pa ọrọ awọn eeyan ti pe bi kii ba ṣe ẹni to wa lati ile ire to si gba ẹkọ lo fi n ṣalaye ọrọ tori naa ko pa wọn ti pe ko jẹ wọn ni alaye kankan.