You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Air Peace: 'Rárá o, kó bá 'má jẹ́ Onyema, èyí àtàwọn ọ̀rọ̀ míì tó ń yọjú
Bi inu ile tabi gbọngan ti ero ko ti gba ẹsẹ loju opo Twitter, Facebook, instagram atawọn ẹrọ alatagba mii kun fọ́fọ́ lori iroyin pe ilẹ Amẹrika fi ẹsun jibiti kan ọga agba ileeṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace, Allen Onyema.
Oniruuru ọna lawọn eeyan ti n gba da si ọrọ naa ti wọn si n ke si ijọba lori igbesẹ to yẹ ki wọn gbe.
Ṣaaju, gbajugbaja oloṣelu ati minisita f'eto ofurufu tẹlẹri ni Naijiria, Femi fani Kayode fi si oju opo Twitter rẹ pe bi wọn ba fi ẹsun kan eeyan, ko tii tumọ si pe o daju. "Ẹsun ni ẹsun n jẹ niwọn igba ti ile ẹjọ ko ba tii fi aridaju han. Allen Onyema kii ṣe adigunjale tabi ọlọsa. Eeyan ire gbaa ni to si jẹ olufọkansin ilu. Mi o mikan pe yoo jare yoo si bori ninu ẹjọ yii".
Gbajugbaja ọdọ olorin Davido ni "Mo duro pẹlu Allen Onyema.
Ni ti gbajugbaja ori ayelujara fun irufẹ awọn iroyin to ma n gbe sita ati ọna to n gba kọ́ iroyin rẹ, Kemi Olunloyo, o ni "gbogbo yín lẹ ni iwa jẹgudujẹra lọwọ gẹgẹ bi olori Naira Marley ṣe kọ ọ."
"Bi mo ba sọrọ daadaa nipa eeyan kan tabi kọ iroyin mi lai lẹja mbakan ninu, ẹ o ni wọn ti san owo fun mi". O fi apẹrẹ orukọ awọn to sọrọ nipa wọn sita.
Ọpọ ọmọ Naijiria ko lee pa ẹnu mọ lori ọrọ̀ yii o. Niṣe lori ẹrọ ayelujara n du to to to leti eeyan ni gbogbo iṣẹju fun bi awọn eeyan ṣe n da si ọrọ̀ naa.
Mo duro pẹlu Allen, ayafi to ba tẹnu ile ẹjọ jade pe o jẹbi.
Ọgbẹni yii ni tirẹ ti sare ro o to si mu ni ranti ore banta banta ti Ọga ileeṣẹ ọkọ baalu Air Peace ṣe fun Naijiria to fi ko awọn ọmọ Naijiria pada wa sile lọwọ pipa ti wọn n pa wọn lorilẹede South Africa.
Ṣugbọn o ni ṣe ko wa ti ya ju lati yaa fopin si ayẹsi, ayẹyẹ ati ajọyọ ta n ṣe lori ẹmi awọn to fi ọkọ baalu rẹ gbe wale laaye.
Ẹwẹ, ọrọ naa ti wa ni ile ẹjọ lọwọ lọwọ ti eeyan ko si lẹtọ lati dede sọ ohunkohun pato nipa rẹ bo ṣe n lọ afi bi ile ẹjọ ba to fọhun lori rẹ.