Jose Mourinho: 3-2 ni Tottenham fi se àgbà fún West Ham

Ọpọ eniyan lo gboriyin fun akọnimọọgba tuntun Tottenham, Jose Mourinho pẹlu bi ikọ rẹ se na West Ham pẹlu ami ayo mẹta si meji.

Son Heung-min lo kkọ fi bọọlu sinu awọn, lẹyin ti Dele Alli gba bọọlu fun un, ti o si wọ inu awọn.

Ni se ni Jose n tọ soke sodo, ti inu re si n dun de di.

Lucas Moura lo gba bọọlu keji wọnu awọn, nigbati Harry Kane si ran Serge Aurier lọwọ lati gba bọọlu naa wọ inu.

Michail Antonio ti ikọ West Ham ati Angelo ogbonna lo gba bọọlu wọle fun ikọ naa ti ayo fi pari si 3-2.

Igba akọkọ ni yii ti akọnimọọgba naa yoo ma a tukọ ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham lẹyin ti wọn le ni ikọ Chelsea ati Manchester United.